Awọn eeyan ọmọ ile ọba niluu Osogbo ti pariwo síta pe ki araalu o gba wọn lọwọ Ọba Jimoh Olanipekun Ataoja ilu Osogbo, lori ẹsun pe o n fi awọn ti kii ṣe ọmọ ilu naa jẹ oye. Eyi jẹyọ nibi eto ìwọ́de ifehonuhan kan ti awọn eniyan naa ṣe …
Ka si »Trailer ọkọ̀ nlá akẹ́rù sekúpa Bàbá ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin 84 lójú ọ̀nà Ògbómọ̀sọ́.
Baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin 84 se kongẹ ọlọjọ nipasẹ ikọlu ti ọkọ nla Trailer kan se si lasiko to n gbiyanju a ti rena sọda sodi keji lopopona Ọyọ s’Ogbomọsọ ladugbo Owolakẹ agbegbe Agric Ogbomọsọ. Gẹgẹ bi ẹni ti isẹlẹ naa soju rẹ se wi, Baba Oloye Joseph Ọkẹowo ti …
Ka si »Eyi ni ohun tó ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà krìstẹ́nì Korede Are ‘Baba Gbenro
Ọpọ àwọn oloolufẹ lo ti wọn fẹ gbajumọ osere naa lo ti n ṣedaro Dokita Moses Korede Arẹ ẹni ti ọpọ èèyàn mọ si Baba Gbenro to doloogbe lana Ọjọbọ Thursday, ọjọ kẹrinla oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii. Iyalẹnu nla ni iku gbajumọ osere kristiẹni ọhun Baba Gbenro jẹ fun …
Ka si »Aunty Ramota bèèrè fún ìrànwọ́ owo lọ́wọ́ àwọn èèyàn ọmọ orileede Nàìjíria nótorí ìlera rẹ̀
O ma se o, Fọnran fídíò kan to jade loju opo itakun ayelujara Instagram lo ti ṣafihan bi gbajumọ oṣerebinrin onitiata nní, Ramota Adetu, ti ọpọ èèyàn mọ si Aunty Ramota ṣe n pe fun iranlọwọ àwọn eeyan ọmọ Naijiria pe oun ko ni ile lori mọ. Ninu fọnran fídíò …
Ka si »Ẹ gbọ́ kí ni Portable ṣe tí àwọn ẹ̀gbọ́n àdúgbò kan fi fi ìbọn wá a lọ sí ọ́fíìsì rẹ̀
Gbajugbaja were olorin takasufe nni, Habib Okikiola, ti ọpọ eeyan mọ si Portable ni ori ti ko yọ lọwọ awọn eeyan kan ti wọn furasi pe wọn fẹ gba ẹmi lẹnu rẹ. Ninu fọnran fidio kan to lu sita lori ayelujara laipẹ yi ni ọkunrin kan ti ọwọ tẹ pẹlu sisaapa …
Ka si »Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó sọ ìgbà ati àkókò tí ìgbẹ́jọ́ ikú Mohbad yóò bẹ̀rẹ̀
Kọmiṣọna feto idajọ nipinlẹ Eko, Lawal Pedro, SAN, ti ṣeleri rẹ pe igbẹjọ iku gbajugbaja olorin takasufe nni Ilerioluwa Alọba ti ọpọ mọ si ‘Mohbad’ yoo bẹrẹ laipẹ lati fi oju gbogbo awọn to lọwọ ninu iku rẹ lede. Pedro lo sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ …
Ka si »Irọ́ ikú ni wọn npa o, Lagbaja ò kú, ó lọ fún ìsinmi lẹ́nu ìṣẹ̀ ni-Iléeṣẹ ológun kede bẹ
Ileeṣẹ ologun nilẹwa Naijiria ti wọgile iroyin ẹlẹjẹ kan to ni Ọga agba ologun lorilẹede Naijiria, Taoreed Lagbaja ti jade laye. Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Onyema Nwachukwu fi ohun naa lede taki iroyin ẹlẹjẹ ti awọn kan ngbe kiri pe ọgagun naa ku, o ni Lagbaja lọ fun isinmi lẹyin iṣẹ, …
Ka si »Àràbà kan tún wo láwùjọ àwọn gbajúmọ̀ òsèré Bọbọ B jáde láyé
Araba miran tun ti wo lawujọ awọn osere tiata Yoruba nilẹwa Naijiria Alhaji Ayọbami Mudasir Olabiyi ti gbogbo aye mọ si Bobo B ti jade laye. Ti a ba n sọ nipa awujọ awọn gbajumọ osere tiata eekan ni Alhaji Mudasir Olabiyi Bobo B. Iroyin iku gbajumọ osere naa lo …
Ka si »Akọni Ọmọ ni ọmọbìnrin mi tó d’ologbe, ikú rẹ bàmí lọ́kàn jẹ́ púpọ̀, Saidi Balogun sọ̀rọ̀ lórí ikú Zeenat Balógun ọmọ rẹ̀.
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Saidi Balogun, ti ṣapejuwe ọmọbinrin rẹ, Zeenat Balogun to ku laipẹ yii gẹgẹ bii akọni eeyan. Balogun sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku Sunday. Ni owurọ ọjọ Ẹti Friday, ọjọ karun un, oṣu Kẹwaa yii ni ilumọọka oṣere …
Ka si »Sunday Igboho kọ̀wé sí Olóòtú Ìjọba gẹẹsi nilẹ Ọba UK, fun ìdásílẹ̀ Yoruba Nation.
Gbajugbaja Ajijagbara to n ja fun idasilẹ ati òmìnira orileede Yoruba ìyẹn Yoruba Nation Agitator Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ eeyan mọ si Igboho ooṣa, ni ìròyìn rẹ kan ti káàkiri pe o ti kọwe si Olootu ijọba ilẹ Gẹeṣi (United Kingdom) lati da si ọrọ idasilẹ orilẹede Yoruba Nation. …
Ka si »