Niise l’Àwọn ojise Ọlọrun, awon imaamu ke pajare sita si Ijọba àpapọ ilẹwa Nàìjíríà lori isoro-ipenija owongogo ounjẹ to n dojuko awon Araalu. L’Ọjọbọ tọside ọsẹ yii ni agbarijọpọ ẹgbẹ awọn omo-lehin-Kristi ati ti Musulumi lorileede Naijiria fohun sọkan rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati wa ojutu, ọna abayọ si …
Ka si »Ó dójú ẹ o, Àjọ EFCC kéde ìyàwó Emefiele ati àwọn mẹ́ta mìíràn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá
Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu-isowo ilu basubasu nílewa Nàìjíríà, Ajọ EFCC ti kéde ìyàwó gómìnà àná fún banki Apapọ ilewa CBN l’Orileede Nàìjíríà, Godwin Emefiele, Margaret Dumbiri Emefiele ni wọn ti kede rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá. Margaret Emefiele àti àwọn mẹ́ta mìíràn, òṣìṣẹ́ banki Apapọ …
Ka si »Oluwo tilu Iwo kọ Lẹ́tà sí Ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò Nàìjíríà tó mẹ́hẹ
Oluwo t’ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi ti kesi aarẹ Orileede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu lati foju oro han awọn ajinigbe nipa agbekalẹ ofin ti yoo faaye gba sisekupa awọn ti ọwọ sinkun ofin ba tẹ to n ji eeyan gbe-gbowo tabi sekupaniyan. Ori-Ade ọrun-ileke naa nilẹ Yoruba sọrọ yi di …
Ka si »Ó ti dójú ẹ bayi Àwọn Oníṣòwò ‘Bureau de change’ dáwọ iṣẹ́ dúró ní Abuja latari Ọ̀wọ́ngógó owo Dọ́là l’Orileede Naijiria
Ẹka awọn to n ṣowo paṣiparọ owo t’awon eeyan mọ si Bureau de Change nilẹwa Naijiria awọn onisowo naa to wa nilu Abuja, olu ilu ilẹwa l’Orileede Naijiria ti kede pe awọn yoo dawọ iṣẹ duro. Idi ti wọn lawọn fẹ tori rẹ ṣe bẹẹ ni nitori ọwọngogo dọla to …
Ka si »Gani Adams léríléka, o ni láàrin osù mẹ́fà péré oun o yanju Ìṣòro ìpènijà ètò aàbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá.
Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba Iba Gani Adams ti ṣeleri lati mu opin ba ipenija aabo to n koju ilẹ Yoruba laarin oṣu mẹfa pere. O fidi ọrọ naa mulẹ lasiko ajọdun Oodua Festival eleyi ti Olokun Festival Foundation ṣe agbatẹru rẹ. Nibi ayẹyẹ ọhun ni Ooni Ife Oba Adeyeye …
Ka si »Ọwọ́ tẹ àwọn ọ̀daràn fulani mẹta ti wọn ṣekúpa Pásítọ̀ nínú oko rẹ̀ l’Ogbomoso
Pasitọ ijọ aladani kan, Adegboyega to tun n ṣiṣẹ agbẹ ni a gbọ pe awọn afurasi Fulani darandaran kan ṣekupa ninu oko rẹ ni agbegbe Gẹgẹ to wa ni opopona Ogbomoso si ilu Iseyin ni ipinlẹ Oyo. Awọn afurasi ọdanran darandaran naa ni a gbọ pe wọn da ẹran jẹ …
Ka si »Èèyàn méta pàdánù èmí wọn nipasẹ Rògbòdìyàn to bẹ bẹ silẹ̀ laarin àwọn èèyàn ìlú Ilobu àti Ifon nípinlẹ Ọ̀sun
Ènìyàn mẹ́ta r’ọrun alakeji, wọn pade ọlọjọ wọn lasiko wàhálà-on-rogbodiyan to waye láàárín awọn eeyan ìlu Ifon àti Ilobu ní ìpínlẹ̀ Osun. Gẹgẹ bi Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé kan se gbe jade, won ni àwọn ìlú méjéèjì naa ló pàdánù àwọn ènìyàn wọn sínú rogbodiyan ìkọlù náà ti wọn se …
Ka si »Nípinle Èkìtì Àwon Ajínigbé Agbébon jí akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà, olùkọ́ mẹ́ta gbé salọ lásìkò tí wọ́n ń dari padà lọ sílé wọn
Àwọn agbébọn jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà àti olùkọ́ mẹ́ta ilé ẹ̀kọ́ kan gbé salọ ní ìjọba ìbílẹ̀ Emure, ni ìpínlẹ̀ Ekiti. Lọjọ́ Ajé Monday ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní ọdún 2024 yi ni isẹlẹ akọlu ìjínigbé náà wáyé nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ náà ń dari padà lọ sílé wọn. …
Ka si »Èèwọ ni oo, Òfin Oríléèdè Nàìjíríà kò Fàyè gba ìgbéyàwó akọ s’ákọ àti abo s’ábo
Ileeṣẹ ọlọpaa l’Orileede Naijiria ti se ikilọ fun awọn araalu pe ofin orilẹede Naijiria ko faye gba igbeyawo laarin akọ si akọ ati abo si abo, ko da, ofin ilẹwa ko Faye gba ibalopọ pẹlu eranko pẹlu. Ikilọ naa waye lẹyin tawọn eeyan kan sọ ninu fọnran fidio kan to …
Ka si »Nipinlẹ Ondo, Ọkùnrin kan gba ibi tó gbà wáyé padà lọ s’ọ̀run lẹ́yìn to ba ọ̀rẹ́bìnrin rẹ lòpọ̀ tan l’Hoteli.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti kede rẹ pe ọwọ ti tẹ eeyan meji lori iku ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Abiodun Akintomowo niluu Ondo. Arakunrin naa lo padanu ẹmi rẹ lẹyin to ni ibalopọ pẹlu obinrin kan tiise ọrẹbinrin rẹ ti wọn n jọ nse wọlewọde, ni ile …
Ka si »