Pasitọ Olufunmilayo Ogunseyi, iyẹn mama to bi Olori tẹlẹ fun Ọọni ifẹ, Naomi Silekunola, ti fi omije bẹbẹ nipa ọmọ rẹ, ti o wa lọgba ẹwọn o ni ki gbogbo abiamọ aye ma jẹ ki wọn pa Naomi oun lọmọ tori pe olu ọmọ oun lo jẹ. Ninu fọnran fidio …
Ka si »Ọmọ tó ń tọ́jú mi ni wọ́n ti d’ẹmi rẹ l’egbodo yi o Ìyá ọkùnrin tó kú s’àgọ́ ọlọ́pàá nilu Ilorin lo kọminú bẹ.
Alhaja Morenike Olatunji, to jẹ iya fun oloogbe, Abdukadir Olatunji Jimoh, to ku satimọle ọlọpaa niluu Ilorin ti sọ pe, oloogbe naa ni o n tọju oun ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo. Alhaja Morenike sọ ọrọ yi lasiko to n ba awọn Akọroyin sọrọ nile rẹ to wa …
Ka si »Òrìṣà bi Èṣù ni Jesu Kristi ati Ànọ́bì Muhammad, òjísẹ́ Elédùmárè kan naa ni wọn, Ifáyemí Elebuibon ló sàlàyé ọ̀rọ̀ bẹ.
Araba Awo ti ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibọn ti ṣalaye ohun ti Jesu, Mohammadu ati Esu jẹ. Ifayẹmi ninu ọrọ rẹ, o ni Eṣu jẹ oriṣa ati Ojisẹ Olodumare bi Jesu Kristi ati Annabi Muhammad ṣe jẹ oriṣa ati Ojisẹ fun Olodumare. Baba Ifeyemi tun tẹsiwaju pe, aṣiṣe ni alufaa Samueli …
Ka si »Ipò t’Oriyomi Hamzat níleewòsàn lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó sokùnfa ikú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé nibi ayẹyẹ ìparí ọdún nilu Ìbàdàn
Alasẹ ati oludari Ileesẹ redio igbohunsafẹfẹ Agidigbo FM nilu Ibadan, Oriyomi Hamzat d’ero ileewosan lasiko tó dákú lẹyìn iṣẹlẹ aburu to se bẹ mú ọpọ àwọn ọmọdé lọ nigba ti awọn miiran sí tun farapa. Gẹgẹ bí ẹnìkan to ba awọn oniroyin sọrọ se wí, ipo ailera Hamzat ko sẹyìn …
Ka si »Iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo kọ lo sàgbékalẹ̀ ètò ayẹyẹ ìparí ọdún fawọn ọmọdé, níbi tí ọ̀pọ̀ ọmọ ti sọ ẹ̀mí wọn nù.
Igbimọ alaṣẹ ileeṣẹ igbohun safẹfẹ redio Agidigbo FM niluu Ibadan ti sọ pe ileeṣẹ redio naa kọ lo ṣagbekalẹ tabi sagbatẹru eto apejẹ to waye lọgba ile-ẹkọ Islamic High School, to wa ni agbegbe Bashorun, nibi ti ọpọ awọn ọmọde ti pàdánù ẹmi wọn. Ọjọru Wednesday, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila …
Ka si »Gómínà Adeleke sètò ìtúsílẹ̀ ọ̀dọ́mọ̀kùnrin tí wọ́n dájọ́ ikú fún torí pé ó jí adìyẹ gbe nipinlẹ Ọsun
Gomina ipinlẹ Osun, Sẹnitọ Ademola Adeleke ti kede pe ki wọn bẹrẹ igbesẹ lati ṣe iwadii kikun nipa ọdọmọdekunrin kan, Segun Olowookere ti wọn dajọ iku fun lọdun mẹwaa sẹyin. Adeleke ni oun yoo rii daju pe idajọ ododo waye lori ẹjọ naa, ati pe ẹsun ti wọn fi kan …
Ka si »Ha o mase o! Ọ̀dọ́kùnrin kan tó lọ sun ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ jóná mọ́lé nílu Ilorin
Arakunrin kan ẹni ọdun mọkanlelogoji, ti wọn pe orúkọ rẹ ni Abdulfatai lo se kongẹ iku ojiji nibi iṣẹlẹ ijamba ina kan to waye loru mọju ọjọ Aje Mọnde. Abdufatai yii la gbọ pe, o n gbe ni Agboole Alatẹ, Abayawo niluu Ilọrin, tiise Oluilu ipinlẹ Kwara. Gẹgẹ bí iroyin …
Ka si »Wọ̀nyí ni bí nkan se lọ níbi ètò Ìsìnkú Sheik Muhideen n’Ibadan
Ero pitimu nibi eto isinku ilumọọka alfa to tun jẹ olukọ ẹsin Islam, oniwaasi Sheikh Muyideen Ajani Bello, nile rẹ to wa lagbegbe Akobọ niluu Ibadan. Owurọ ọjọ Ẹti Friday ni iroyin gbe e jade pe Alhaji Sheik Muyideen Bello jade laye. Lati aarọ ọjọ Ẹti yii naa ni ọpọ …
Ka si »Orí kó tọkọ’taya kan yọ lọ́wọ́ ikú òjijì tí ì bá pawọ́n láìrò tì
Ọkọ ati iyawo rẹ ọhun ni irọlẹ Ọjọbọ Thursday ni ori ko yọ lọwọ iku ojiji lasiko ti Container ile alasopọ mọ ọkọ nla trailer deede subu lu ọkọ wọn ti number idanimọ rẹ jẹ Nasarawa JZ 101 ZA loju ọna Ogbomọsọ High School. Gẹgẹ bi iroyin naa ti a …
Ka si »Àlàyé ikú ti ó pa Sunday Babatunde, elégún Danafojura, l’Ogbomọṣọ.
Awọn ẹbi oloogbe naa fidi iku ẹni wọn mulẹ pe l’ọgba ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Bowen, BUTH, niluu Ogbomoso, nipinlẹ Ọyọ ni Sunday Babatunde dakẹ si. Awọn ẹbi Babatunde sọ fawọn oniroyin pe lọjọ Abamẹta Satiide to kọja yi ni oloogbe naa deedee yọ ṣubu lasiko to n wẹ lọwọ …
Ka si »