Iroyin pajawiri

Ìròyìn Yàjó Yàjó

Owá Obòkun Ilẹ̀ Ijẹsha, Ọba Gabriel Adekunle Arọ́mọlaran II wàjà lẹni ọdún mérìndínlaadọrun

Erin wo, ajanaku sun bi oke, Owa Obokun ti Ile Ijesha, Ọba Gabriel Adekunle Aromolaran ll niroyin fidiẹ mulẹ pe o ti waja lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun un. Ìròyìn iku eekan ọba nilẹ Yoruba nipinlẹ Ọsun naa Ọwá Obòkun ti ilẹ Ijesha lo mi igboro titi l’ọjọbọ Toside, ti awọn ọmọ …

Ka si »

Àjọ NCC tun ti kéde gbèdéke tuntun fún àwọn eeyan tí kò tíì so nọ́mbà fóònú wọn pọ̀ mọ́ nọmba ìdánimọ̀ NIN

Ajọ NCC, ajọ to n ṣakoso awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilẹwa Naijiria ti tun kede gbedeke ọjọ ti wọn yoo fofin de awọn ti wọn ko i ti so Sim wọn pọ mọ NIN wọn. Ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an to n bọ yi ni ajọ naa kede gẹgẹ bi gbedeke …

Ka si »

Ayẹyẹ ọdún Ìsẹ̀se wáyé káàkiri àwọn ìlú nílẹ̀ Yorùbá.

Ayẹyẹ ọdun iṣẹṣẹ wa kaakiri ilẹ Yoruba, Paapajulọ lawọn ipinlẹ bii Ọyọ, Eko, Ọṣun, Ogun to fi mọ ipinlẹ Kwara. Gbogbo ogunjọ oṣu kẹjọ ọdọọdun ni ayajọ ọdun iṣẹṣẹ ni ilẹ Yoruba. Kaakiri awọn ilu isẹmbaye, nilẹ Yoruba ni awọn ipinlẹ ti o wa lẹkun gusu orileede Naijiria ni ajọdun …

Ka si »

Àdùkẹ́ Gold, Irú ikú wo lo pa gbajúmọ̀ Akọrin ẹ̀mí yi, Àdùkẹ́ Gold.

Adukẹ Ajayi ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Adukẹ Gold ni oju rẹ ti ri ọpọ adojukọ ninu aye latari awọn ipenija adojukọ ọhun lo mu kọrin nitori ogo ti o sọ digbajumọ lawujọ awọn akọrin ẹmi lorileede Naijiria. Ohun ti o jẹ ibanujẹ ọkan nipa iku gbajumọ akọrin …

Ka si »

NCC ti pàsẹ́ fún Iléesẹ́ MTN láti sí àwọn Simu tí wọ́n tí padà

Ojú òpó ìbára ẹni sọ̀rọ̀ Nomba Simu yin gbọdọ̀ ti maa sisẹ́ padà látàri àsẹ tí àjọ NCC pa fún àjọ MTN Àjọ tó ń mójútó àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ lorileede Nàìjíríà, àjọ NCC ti darí àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ láti ṣí ojú òpó àwọn oníbàárà wọn tí wọ́n ti wọn dena …

Ka si »

Òsì Balógun tilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Lateef Gbadamọsi Adebimpe ti wàjà o.

Oloogbe naa Osi Balogun tilẹ Ibadan, Ọba Lateef Gbadamọsi Adebimpe j’Ọlọhun nipe ni ọjọru Wednesday, ọjọ kẹrinlelogun lẹyin aisan ranpẹ ti wọn lo n se e. Gẹgẹ bi iroyin naa ti ileesẹ iwe iroyin Naijiria Tribune gbe jade, ologbe naa lo soju Ọba Olubadan tuntun Ọba Owolabi Ọlakulẹyin lasiko sisi …

Ka si »

Ọ̀ọ̀ni Ilè Ifẹ̀ f’òfin de àwọn lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́ àt’àwọn tó n ta ọ̀wọ́n gógó Ata láwọn ọjà gbogbo tó wà nilu Ilé Ifẹ̀.

Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ọjaja ll lo ti fòfin dè awọn Ẹlẹgbẹjẹgbẹ-Ọlọja ni gbogbo ọja nilu ile-Ifẹ patapata poo. O ni ka fẹgbẹ mu ni, ka fofin deni ko si n to jọ bẹ mọ laarin áwọn ọja gbogbo nilu ile-Ifẹ. Igbesẹ yi lo waye lẹyìn tí …

Ka si »