Gómìna ipinlẹ Ọyọ onimọ-ẹrọ Seyi Makinde, ti buwọ́lù iyansipo Ọmọọba Abimbola Ọwọade gẹgẹ bí Alaafin Ọyọ tuntun ti yóò gori apeere awọn baba nla rẹ.
Ikede ọhun lo jẹyọ jade ninu atẹjade kan to jẹ gbigbe jade sita l’ọjọ Ẹti Friday, lat’ọwọ Kọmisọna f’eto iroyin ati ilanilọyẹ, Ọmọ ọba Dotun Oyelade.
Oyelade ni Owoade ni wọn yan lẹyìn eto gbogbo to waye nibamu pẹlu eto-ilana jíjẹ oye ọba, niti asa ati iṣẹṣe yoruba, gbigbe-fa janlẹ ati bẹẹ bẹẹ latọwọ awọn afọbajẹ ilu Ọyọ.
Kọmisọna fún ọrọ ìjọba ibilẹ ati ọrọ oye jíjẹ nipinlẹ Ọyọ, Ademola Ojo, ninu ọrọ ti ẹ, O ni ikede naa máa fopin sí aawọ-ariyanjiyan láwùjọ- awọn awọn ọmọ oye ati n’ileẹjọ eyi to ti n waye lẹyìn ipapoda Alaafin Ọyọ ana, Ọba Lamidi Adeyemi lll (kẹta), ẹni tó waja l’ọjọ kejilelogun, osu Kerin, ọdún 2022.
Wọn wa rọ àwọn ọmọ ìlú Ọyọ- aráàlú ipinlẹ Ọyọ lati gbaruku ti Alaafin tuntun naa, ki wọn si rọgba-yika-satilẹyin fun, ki wọn darapọ mọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati sajọyọ igba ọtun -itan tuntun tó dé yi.
Oyelade jẹ kó di mímọ pé, igba Aláàfin tuntun naa yóò mú àlàáfíà, iṣọkan ati ise-rere ba ilu Ọyọ lapapọ.
Ti a o ba gbagbe, a o rántí pé lẹyìn ipapoda Aláàfin Ọyọ tẹlẹ, Ọba Lamidi Adeyemi lll, ni eto-iyansipo Ẹni ti yóò gori apeere Ọba Alaafin ti fa Orisirisii awuywuye-ahesọ ọrọ lati bi ọdún mẹta sẹyìn.
Laipẹ yi ni Gómìnà Makinde pàṣẹ ìlànà ètò yiyan Alaafin tuntun naa, ṣugbọn awọn Afọbajẹ marun- to jẹ awọn aworosasa laarin awọn Afọbajẹ ọun kọ jalẹ pe awọn kò gba ìlànà-ètò oye jíjẹ tí Makinde pàṣẹ- eyi to gbe kalẹ ọun l’ọjọbọ tọside.
Awọn Afọbajẹ ọun ni Basorun tilu Ọyọ, Agba Oye Yusuf Akinade; Lagunna tilu Ọyọ, Agba Oye Wakeel Akindele; Akinniku tilu Ọyọ, Agba Oye Hamzat Yusuf; ati Oloye to duro gẹgẹ bí agbelẹsẹ alatilẹyin fún Alapinni tilu Ọyọ, Oloye Gbadebo Mufutau.
Awọn oloye wọnyi ni wọn tẹnumọ, fajekọri pe, Ọmọọba Lukman Gbadegesin ni awọn yansipo gẹgẹ bí Alaafin ti yóò gori apeere Ọba, wọn tọka sí igbẹjọ to n lọ lọwọ n’ileẹjọ niti eto ilana iyansipo alafin Ọyọ.
Agbẹjọro awọn Afọbajẹ, Adekunle Sobaloju ti wa ṣàpèjúwe ìgbésẹ Gomina Makinde gẹgẹ bí èyí tí kò bá òfin mu rara, to sì parọwa pe ki wọn so eto naa rọ naa titi digba ti Ileẹjọ yóò fi yanju fa n fa to n lọ laarin awọn ọmọ oye.