Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti jẹ ko di mimọ pe ko si aniani, o ti di dandan ki awọn eeyan ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku awọn ọmọde marundinlogoji nibi iṣẹlẹ itẹra-ẹni pa to waye nibi eto apejẹ- ifunni-lounjẹ opin ọdun lọfẹ ti olori Ooni Ile-Ife tẹlẹri, Naomi Ogunwusi, ṣagbekalẹ niluu Ibadan foju ba ile ẹjọ.
Makinde sọ eyi ni ọfiisi ijọba to wa ni Ibadan, tiise olu-ilu ipinlẹ Ọyọ, lọjọ Aje Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kinni ọdun 2025.
Gomina ni ọpọ eeyan lo ti pe oun pe iru iṣẹlẹ to ṣekupa awọn ọmọde marundinlogoji nipinlẹ Ọyọ ti waye ni awọn ipinlẹ mii lorilẹede Naijiria, ti ijọba ko si ti gbe igbesẹ kankan.
Ṣugbọn o jẹ ko di mimọ pe “ipinlẹ Ọyọ yatọ si awọn ipinlẹ yooku”.
O ni, awọn o ni ri iru iṣẹlẹ yii mọ nipinlẹ Ọyọ, nigbati awọn ba f’awọn to tọwọ wọn se jofin, gomina ni awọn eeyan ti pe oun pe iru iṣẹlẹ yii waye ni ipinlẹ Anambra ati ilu Abuja tiise Oluilu ilẹwa Nàìjíríà, ti ko si ti si ẹnikẹni to lọ si ẹwọn ṣugbọn ipinlẹ Ọyọ ki i ṣe ipinlẹ Anambra tabi Abuja
O ni, ko si bi o ṣe le ni okiki to tabi mọ’yan to idajọ ododo yoo waye latọ awọn ẹka idajọ wa nipinlẹ Ọyọ.
O ni “ti wọn ba pinnu pe awọn fẹ gba beeli awọn eeyan yii ṣaaju ki idajọ to waye, o ni oun ko tako rara, ṣugbọn wọn gbọdọ foju ba ile-ẹjọ.”
Makinde ni ti gbogbo orilẹede Naijiria ba pinnu pe awọn ko ni tẹle ilana ti ofin lakalẹ, ipinlẹ Ọyọ yoo tẹle ofin.
Ti a o ba gbagbe, a o rántí pé, Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ kede rẹ pe awọn ọmọde marunlelọgbọn lo padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ itẹra-ẹni pa to waye nibi eto apejẹ -ifunnilounjẹ-ọfẹ opin ọdun ti olori Naomi Ogunwusi, gbekalẹ niluu Ibadan.
Bakan naa ni wọn gbé àwọn ọmọde mẹfa lọ sí ileewosan nitori wọn farapa kọja aala.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Osifẹsọ Adewale fi sita ni ọsan Ọjọbọ Thursday, lo gbe sita lọdun to kọja pe àwọn ti nawọ gan ẹni to ṣagbatẹru eto naa, Woolilobinrin, olori Naomi Silẹkunọla
Lara awọn ti agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe awọn fi gbooro ofin gbe naa ni Fasasi Abdulahi (Ọga agba ile-ẹkọ Islamic High School, Ibadan), Genesis Christopher, Tanimowo Moruf, Anisolaja Olabode, Idowu Ibrahim, ati Abiola Oluwatimilehin.
SP Osifeso sọ pe awọn ti gbe isẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto iwa ọdaran lọwọ fun iwadii-ifimufinle to lọọrin, ti igbẹjọ naa yóò sì bẹrẹ laipẹ.