Ọrọ to n lọ laarin ilu nipa awọ ohun rogbodiyan tonise nipa Imam Agba ilẹ Ogbomọsọ ni awọn eeyan kan ti bẹrẹ sini sigbọ, fi oju ọtọ wo bayi o.
Ọpọ eeyan lo n fi ọrọ naa kọ Sọun tilẹ Ogbomọsọ, Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye lọrun pe Kabiesi fẹ yọ Imam Agba naa nipo, niise lọpọ eeyan n beere laarin ilu pe kilode, kilo kan Ọba ilu, ẹni ti o tun jẹ olori ẹsin Igbagbọ lati maa dasi ọrọ ti o nise nipa ẹsin Musulumi.
Yatọ si pe ọrọ naa jẹ ọrọ ilu niise lawọn eeyan kan tun fẹ maa gbe ọrọ ẹsin wọọ.
Ohun ti o kan Sọun ninu ọrọ naa gan lo jẹ ohun ti ko fi bẹ ye ọpọ awọn eeyan, amọ ohun ti a gbọ ni pe Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye ni ohun ti o pọ niwaju lati gbori itẹ se, Ọba naa ni awọn alakalẹ iran ati afojusun lasiko yi ju a ti maa dasi ọrọ ẹsin tabi gbiyanju ati sọ pe oun fẹ yọ Imam agba naa nipo.
Ti a o ba gbagbe a o ranti pe ọrọ yiyọ Imam Agba ilẹ Ogbomọsọ ọhun nipo ko sẹsẹ bẹrẹ, ọrọ naa ti n ja raninrain saaju ki Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye Sọun tilẹ Ogbomọsọ yi o to jẹ.
Ti a o ba gbagbe, a o ranti awọn eeyan idile Ayilara ti ọrọ ipo jijẹ Imam Agba ilẹ Ogbomọsọ naa kan ni wọn kọwe ẹhonu wọn si awọn adari ẹsin nilu pe ẹni ti wọn fi jẹ Imam Agba ilẹ Ogbomọsọ ti i se Sheikh Taliat Yunus Ayilara ki i se ọmọ ile awọn, ki i se ọmọ inu ile Ayilara ti o wa ni adugbo Oke Agbẹdẹ nilu Ogbomọsọ.
Nigba ti awọn adari ẹsin naa o ri ọrọ ọhun yanju ni wọn gbe ọrọ naa tọ awọn igbimọ oloye Sọun tilẹ Ogbomọsọ wa, ti awọn igbimọ naa si yan awọn igbimọ eyi ti wọn fi eekan asaju ẹsin takoko rẹ ti awọn elegbe lẹyin Sheikh Taliat Yunus Ayilara si n fẹ ki awọn igbimọ ọhun o se idajọ ti yoo segbe lẹyin awọn.
Ọrọ naa fẹrẹ tabuku Aarẹ Ago ẹni ti i se olori igbimọ oloye Sọun ti o tun jẹ ẹlẹsin Kristiẹni lasiko igba naa, ohun ti awọn eeyan naa sọ nipe bawo ni Aarẹ Ago ẹlẹsin Kristiẹni yoo se maa se dajọ dasi ọrọ ẹsin Islam.
Ọrọ naa di yanpọn yanrin da ipinya silẹ laarin pupọ awọn ẹlẹsin Musulumi nilu Ogbomọsọ debi lasiko irun Jimọh awọn ikọ ẹsọ alabo lo maa n duro layika lati dẹkun awọn igun ti inu nbi ti wọn a maa dun koko pe Imam Agba naa koni le waju irun Jimọh fun awọn.
Wahala naa ni wọn si n fa di asiko yii ti Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye fi dori oye gẹgẹ bi Sọun tilẹ Ogbomọsọ.
Tiwọn si tun gbe ọrọ naa wa siwaju Ọba Ghandi ti Kabiesi si yan igbimọ eyi ti o fi agba Oye Yusuf Kasali, Abẹsẹ ilu Ogbomọsọ se olori wọn lati ri si ọrọ awọ naa.
Igbimọ ọhun lo ransẹ pe iya ti o bi Sheikh Taliat Yunus Ayilara Imam Agba fun ra rẹ lati fi ọrọ wa Obinrin ọhun lẹnu wo, gbogbo igbesẹ naa ni awọn ti o fi ẹsun kan Imam Agba naa ri gẹgẹ bi eyi ti wọn o fẹ ohun ti wọn n fẹ ti wọn duro le lori ni yiyọ Imam Agba naa nipo.
Saaju ni Aarẹ Basọrun, asoju musulumi nilẹ Ogbomọsọ ati awọn Imam Imam awọn alufa bi o le diẹ logoji pẹlu ẹgbẹ Musulumi bi mẹwa ni wọn pawọpọ kọ si Ọba Ghandi Afọlabi lati yọ Imam Agba naa nipo tabi ki o yẹba kuro fun gba diẹ amọ ti Ọba Ghandi nfẹ asọyepọ, t o si kọ lati se ohun ti awọn eeyan naa nbeere fun
Niise lawọn tinu n bi ninu idile naa tun kọwe ẹsun wọn ransẹ si ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti awọn yẹn si pe igun mejeeji lati wa sọ ti ẹ̵nu wọn, asiko naa ni Imam Agba naa gba ile ẹjọ lọ pe ki ile ẹjọ o fun oun ni iyọnda lati tẹsiwaju gẹgẹ bi Imam Agba tilẹ Ogbomọsọ ti o si tun pe Sọun lẹjọ lati ma le ni anfaani kankan fun iyọnipo rẹ.
Ti iroyin si gbe lasiko naa pe Imam Agba tilẹ Ogbomọsọ pe Sọun tilẹ Ogbomọsọ lẹjọ.
Eyi lo mu ki awọn eeyan o maa gbe kiri pe Sọun lo fẹ yọ Imam Agba naa iyẹn Sheikh Taliat Yunus Ayilara nipo laimọ pe Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye ko ni nkan se lori iyọnipo Imam Agba naa.
Dipo ki awọn eeyan o maa fọn rere orukọ awọn tinu nbi ninu idile Ayilara ti wọn kọwe ẹsun pe Sheikh Taliat Yunus Ayilara ki i se ọmọ ile wọn, orukọ Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye Sọun tilẹ Ogbomọsọ ni wọn pa kiri.
Kabiesi ninu ọrọ rẹ eyi ti ọkan ninu awọn agbẹnusọ rẹ Peter Ọlalẹyẹ sọ fun awọn oniroyin jẹki o di mimọ pe Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye ko si nidi a n yọ Imam Agba nipo bẹẹ sini ko tilẹ raye a n da sọrọ iyọ nipo ẹnikẹni bayi.
Ọlalẹyẹ gẹgẹ bi o se wi o ni ohun ti o wa niwaju Kabiesi lasiko yi ni bi ilu Ogbomọsọ yoo se ni ilọsiwaju ti alafia yoo si wa nilu.
O ni ki gbogbo awọn to n gbe ọrọ naa kiri pe Ọba Ghandi fẹ yọ Imam Agba nipo o sinmi a ti maa ba Ọba lorukọ jẹ, o ni biba Ọba lorukọ jẹ kọ lọna abayọ eyi keyi ti o ba mọ idi ọrọ ko lọ beere lọwọ awọn ti wọn mọ ki wọn o ye sọ ohun ti oju wọn ko to.