Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"transform":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fòntẹ̀ lù ìdájọ́ ikú oloye Ramon Adedoyin latari po lọwọ nínú ikú tó pa Akẹkọọ OAU Timothy Adegoke.

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fòntẹ̀ lù ìdájọ́ ikú oloye Ramon Adedoyin latari po lọwọ nínú ikú tó pa Akẹkọọ OAU Timothy Adegoke.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti o fi di kalẹ niluu Akurẹ ti buwọ́lù idajọ iku fun oludasilẹ Hotẹẹli Hilton ti o wa nilu Ile Ife nipinlẹ Osun, Dokita Ramọn Adedoyin, lori ọrọ iṣekupa akẹkọọ ileewe gíga fasiti OAU, Timothy Adegoke to ku si hotẹẹli rẹ nijọ kinni ana.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ọhun to fìdí kalẹ siluu Akure l’ọjọbọ tọside lo buwọ́lù idajọ iku eyi ti ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Osun ti da tẹlẹ fun oloye Adedoyin atawọn osisẹ rẹ kan.

Lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2024 to kọja lọ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti ṣe agbekalẹ idajọ naa ki o to ka a jade lonii Ọjọbọ Tọside ọjọ kẹtalelogun oṣu Kinni ọdun 2025 yii.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Akure sọ pe ”awọn duro lori idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun lori ọrọ naa.

Fun idi eyi, ile ẹjọ kotẹmilọrun ti yi ẹjọ ti Adedoyin pe danu bi omi isanwọ ti o si fidi ẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan.

Se ẹni ba ti bi ida pani ka tibi ida pa ni ofin sọ.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe ko si aṣiṣe ninu idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to dajọ iku fun ilumọnka oniṣowo naa Adedoyin.

Ile ẹjọ ni idajọ iku ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun da tẹlẹ fun Adedoyin tọna labẹ ofin pẹlu nnkan to ṣe.

Amọ, ile ẹjọ kotẹmilọrun fagile idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to gbẹsẹ le ile itura Hilton Hotel to jẹ ti Adedoyin.

Bakan naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tun fagile idajọ ile ẹjọ giga to paṣẹ pe ki Ọgbẹni Adedoyin maa sanwo ile ẹkọ awọn ọmọ oloogbe Timothy Adegoke.

Ti a o ba gbagbe, a o rántí pé inu oṣu Kọkanla ọdun 2021 ni iroyin iku akẹkọọ Timothy Adegoke lugboro kan lẹyin ti wọn ri oku rẹ nile itura Hilton hotel niluu Ile Ife.

Lẹyin idajọ ile ẹjọ giga ti o da pe ki wọn lọ yẹgi fun oludasilẹ ile itura Hilton naa latari iwadi ti o fi han pe o lọwọ ninu iku ologbe Timothy ti o ku s’otẹli rẹ.

Nse ni adari ile itura Hilton ọhun, Dokita Ramọn Adedoyin gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ lẹyin ti adajọ da ẹjọ iku fun lori iṣekupani akẹkọọ ileewe gíga fasiti OAU, Timothy Adegoke.

Ileẹjọ giga nipinlẹ Osun lo da ẹjọ pe ki wọn yegi fun nitori o lọwọ ninu iku arakunrin naa to sun si ile itura rẹ.

A o ranti ninu idajọ ile ẹjọ giga ilu Osogbo naa ni, adajọ Adepele Ojo ti dajọ naa pe ki wọn lọ yẹgi fun Adedoyin ati oṣiṣẹ rẹ meji ti wọn gbe oku Timothy kuro ni ile itura, Adeniyi Aderogba ati Oyetunde Kazeem.

Bakan naa ni adajọ ni ki ijọba gbẹsẹle ile itura rẹ, pe ki o di ti ijọba.

Adajọ tun ni ohun ini Adedoyin ni wọn yoo fi ran awọn ọmọ Adegoke lọ si ileẹkọ titi wọn yoo fi jade ileewe gíga fasiti.

Amọ adajọ naa fi awọn oṣiṣẹ mẹta silẹ, Magdalene Chiefuna, Oluwole Lawrence ati Adebayo Kunle ki wọn maa lọ ni alaafia, ti akọwe to wa ni ibi isẹ naa si gba idajọ ẹwọn ọdun meji.

Lẹyin idajọ ile ẹjọ giga naa ni Ramon Adedoyin ni oun ko faramọ idajọ iku, to sì gba ileẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun lọ.

Ọkan ninu awọn adajọ Adedoyin, Adajọ agba Kunle Adegoke lo fi idi ọrọ naa mulẹ f’awọn Akọroyin nigba naa.

Amọ a abalọ ababọ rẹ bayi ile ẹjọ kotẹmilọrun naa da ẹjọ kotẹmilọrun ti Adedoyin pe danu ti o si fidi idajọ iku ti ile ẹjọ giga ti kọ kọ da fun mulẹ pe o jẹbi iku ni tootọ

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Lateef Adedimeji: Àgàn lọ̀pọ̀ n pe Mo-Bimpe aya mi, àmọ́ nse ni mo kọtí ikún.

Lateef Adedimeji: Àgàn lọ̀pọ̀ n pe Mo-Bimpe aya mi, àmọ́ nse ni mo kọtí ikún. …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *