{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"transform":1,"effects":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Ìmáàmù Agba Ogbomoso tu ba o, o rawọ-ẹbẹ sí Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi, pe ko má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ t’oun bá ṣẹ̀

Lẹyin ọpọ awuyewuye, gbonmisi-omi-o-t o ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumọgẹgẹ Kẹta ati Imaamu agba ilu Ogbomoso, Sheikh Teliat Yunus Ayilara, ni bayi imaamu agba naa ti rawọ-ẹbẹ pe ki kabiyesi fiye denu ko dari asise atasi sọ oun gbogb ji oun.

Nigba to n sọrọ ninu fọnran fídíò kan to fi lede loju opo itakun-ayelujara oju iwe Facebook rẹ, Imaamu Ayilara ni ”awon bẹ baba pe ki wọn ma binu gbogbo ohun ti awọn ba ṣe si wọn gẹgẹ bi ọmọ.

O ni, Ọrọ ẹnu ni, irin ẹsẹ ni, ihuwasi ni, ki wọn ma binu tori ti Ọlọrun.

O ni, Baba kabiyesi Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, ẹ ma binu tori Ọlọrun, ẹyin agbalagba lo sọ pe bi ẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi, ko ni pẹ lori ikunlẹ.

O ni Awọn agbalagba naa lo tun sọ pe ti a ba fi ọwọ ọtun bọmọ wi, a o tun fi ti osi fa a mọra, o ni ki Oba Ghandi fa oun mọra.

O wa rọ Ori-ade-ọrùn ilẹkẹ naa lati ba oun wi nigbaku gba ti oun ba ṣẹ ori ade naa.

O ni ki Baba kabiyesi yọnu si oun atawọn eeyan oun ti o ba yọnu s’awọn, awọn eeyan yoo dẹkun ariwo awọn ti wọn n pa kaakiri ori itakun ayelujara lojoojumọ.”

Sheikh Teliat ni ohunkohun ti musulumi kankan ba le ṣe fun kabiyesi, pe ki Ọba Ghandi o se aforijin rẹ.

Imaamu agba Ogbomoso ọhun wa gbadura ninu fọnran fidio naa to fi lede loju opo ayelujara oju uwe Facebook rẹ pe Eledua yoo fun gbogbo eeyan niluu Ogbomoso ni isinmi.

Sheikh Ayilara sọ bi oun atawọn eeyan oun ṣe n pẹ lori ikunlẹ o ni pipẹ lori ikunlẹ naa lo jẹ ẹdun ọkan foun.

O tun sọ ninu fọnran naa pe lati igba ti kabiyesi ti rinrin ajo lọ si oke okun loun ti n bẹbẹ eyi ti oun si tun tẹsiwaju pẹlu rẹ nigba ti kabiyesi tirin-ajo de.

Imaamu ni o da oun loju pe kabiyesi yoo maa gbọ ninu aafin bi oun sẹ n rawọ-ẹbẹ lati inu mọṣalaaṣi Oja-igbo.

Shiekh Ayilara fidi rẹ mulẹ ninu fọnran fidio naa pe o ti di Jimọh meje toun ti n rawọ-ẹbẹ sipẹ si kabiyesi bayii.

O wa sọ pe o da oun loju wi pe Ọba Ghandi ti gbọ ẹbẹ oun, wọn si ti gba bakan naa.

Imaamu wa sọ pe oun atawọn musulumi mii yoo lọ si aafin laipẹ lati tọrọ aforijin lọwọ kabiyesi daadaa.

Sheikh Ayilara ni Ọba Ghandi fẹran oun gan an tẹlẹ ko to di wi pe aawọ bẹ silẹ laarin awọn, amọ, oun gbagbọ pe ko ni pẹ mọ ti aawọ naa yoo fi pari pẹlu bi oun ti n bẹ kabiyesi.

A o rántí pé Wahala oun aawọ aarin Ṣọun Ogbomọṣọ ati Immamu agba Sheikh Ayilara ọhun lo bẹrẹ nigba ti imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun Ogbomọṣọ lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.

Soun ana lo fi Ayilara jẹ oye Imaamu agba lọdun 2021 ko to waja, eyi ti Imaamu agba naa si n sọ wi pe iyansipo oun ba ilakalẹ gbogbo ilana mu ni ibamu pẹlu ẹsin Islam, ti igbimọ nipa ẹsin ni ilu Ogbomọṣọ si fọwọ si i.

Amọṣa ọrọ mii suyọ saaju iyansipo Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye sori apere Ṣọun ti ilu Ogbomọṣọ lọdun 2023 nigba ti awọn ọmọ idile Ayilara kọwe ẹsun pe Sheikh Tọliat Ayilara ki i se ojulowo ọmọ idile Ayilara

Lọrọ ba ba ibomiran yọ
lori Awuyewuye ọhun to laaarin Ọba Ghandi ati Imaamu agba pẹlu bi igbimọ awọn Alfa ati Imaamu ile Ogbomọso se da si ọrọ naa

Igbimo ẹgbẹ awọn Imaamu ati Alfa ti ilu Ogbomoso naa bu ẹnu atẹ lu ifanfa to n waye laaarin Imam agba Alhaji Toliat Yusuf Ayilara ati Oba Ghandi Olaoye Orumogege lll Sọun tilu Ogbomọsọ.

Ẹgbẹ awọn Alfa ati Imaamu Ilu Ogbomoso labẹ isakoso Aarẹ musulumi ilẹ Ogbomoso, Aarẹ AbdulGaniyu Owodunni ninu ifọrọwerọ tí ẹgbẹ naa ṣe pẹlu awọn Akọroyin ni gbọngan Recreation Club, lo ti ni, iwa ti Imaamu agba ilu Ogbomoso naa n hu ti mu ki aisọkan wa laarin awọn Musulumi ilu Ogbomoso.

Ninu ọrọ apilẹkọ ti Aarẹ musulumi ilu Ogbomoso ka lọjọ naa lo ti ran Imam Toliat Yusuf leti wí pe ṣaaju ko to gba lawani gẹgẹ bi Imam agba ilu Ogbomosho ni awọn ẹbi Ayilara ti ń fapa janu wi pe kii ṣe ọmọ ile awọn, nitori naa ipo naa ko tọ si.

Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye Orumọgẹgẹ lll, ni atẹjade to ti Aafin rẹ jade nigba naa sọ pe ko ba ẹnikẹni ja, O ni, ọrọ ìdílé ni, oun sí ni ki Ìmáàmù Agba Ogbomoso naa, Yusuf Taliat lọ yanju ọrọ  pẹlu awọn ẹbi Ayilara, pe ojúlówó ọmọ Ayilara loun n se, ko sí fi àwọn ẹrí aridajusaka hàn fún wọn amọ dipo bẹ ohun ti o jọra wọn ni Imaamu naa n gbe kiri eyi lo si mu ki ọrọ naa pẹ nilẹ di asiko yi.

Amọ ju gbogbo ẹ lọ Imaamu agba naa ti n rawọ ẹbẹ pe ki Ọba Ghandi Afọlabi o foriji oun pe eeyan ki mọ ọ gun mọ ọ tẹ ki’yan ewura o mọ lẹ mọ

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Wàhálà, Ija tun bẹ silẹ laarin Ifọn àti Ilobu, ìjọba ipinlẹ Osun kéde kónílé o gbélé lawọn ilu mejeeji

Wàhálà, Ija tun bẹ silẹ laarin Ifọn àti Ilobu, ìjọba ipinlẹ Osun kéde kónílé o …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *