Kosi ba se pẹ laye to iku naa ni o gbẹyin ẹda, ya to bi Gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal, ẹni ti ọpọ èèyàn mọ si K1 De Ultimate, Alhaja Halima Anifowoshe lo ti jade laye lẹni ọdún marunlelọgọrun.
K1 Dé Ultimate lo kede iku iya rẹ loju opo itakun ayelujara ni owurọ Ọjọ àbámẹ́ta Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu kinni ọdun 2025.
Fọnran fidio iya to di oloogbe naa pẹlu K1 ni wọn fi kede iku iya naa.
O kọ sí bẹ pe “Pẹlu ẹdun ọkan ni awọn fi kede ipapoda iku iya King Wasiu Ayinde, Ki Ọlọrun ba awọn tẹ si afẹfẹ rere.
Alhaja Shadiya Omoakeredolu Aya Anifowoshe. Sun re oo.”
Se kosi barugbo ẹni sele pẹ to bi ko ti iku rẹ ki i dun ni
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti ranṣẹ ibanikẹdun si K1 De Ultimate lori iku iya rẹ naa.
Ninu fọnran Fidio kan ti K1 gbe sita eyi to ṣafihan bi o se n ba aarẹ sọrọ lori ipapoda iya ọhun ninu ile rẹ.
Gẹgẹ bí iroyin ti a gbọ, wọn ti sin oku iya naa l’ọjọ Abamẹta Satiide ni ilana ẹsin musulumi ni ile rẹ to wa niluu Ijebu Ode nipinlẹ Ogun.
Saaju ni Wasiu Ayinde ni gbogbo ẹbun orin ti oun ni lo jẹ pe ọwọ ara iya oun loun ti gba.
O ṣapejuwe ajọsepọ to wa laarin oun pẹlu iya rẹ gẹgẹ bii eyi ti o danmọran pẹlu ọpọ ifẹ otitọ.
O ni, “Iya oun ni ẹbun orin lọpọlọpọ, o ni wọn bi oun sinu orin ni, Olorin ni iya oun ko to di pe o ṣe igbeyawo, O ni pẹlu b’ose lẹbun orin kikọ to sibẹ o tun jẹ ọmọ ọba.
Amọ wọn ko gba iya oun laaye lati kọrin nitori pe o jẹ ọmọọba, ti awọn obi rẹ si lero pe orin kikọ yoo se idaduro igbeyawo rẹ.”
Amọ orin ti iya oun o kọ loun ọmọ rẹ kọ lako lowo bayi ki Ọlọhun o tẹ iya naa si afẹfẹ ire.