Olorì Damilọla dákú lóbá dèro ilé ìwòsàn látàri bí Portable tún se b’ọ́nà mi yọ si

Awuyewuye wahala mii tun ti suyọ lori itakun ayelujara laarin gbajumọ akọrin takansufe nni, Habeeb Okikiola, ti ọpọ eeyan mọ si Portable ati ọrẹbinrin rẹ, Olori Damilola.

A o rántí pé, o ti to bii osu meji bayi ti awuyewuye ti n lọ laarin awọn ololufẹ mejeeji naa nigba ti Portable ke pajare sita pe Dammy ti kuro ninu ile ti oun gba fun, tawọn mejeeji si bẹrẹ si i sọ oko ọrọ sira wọn lori ayelujara, leyi t’áwọn ọrọ alufansa n tẹnu wọn jade sira wọn.

Sugbọn iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti ariwo mii tun sọ laipẹ yi ni irọlẹ ọjọbọ tọside pẹlu bi fọnran fidio kan se lù ori-itakun-ayelujara kan.

Fọnran fidio naa lo n se afihan Damilola ninu ọkọ ayọkẹlẹ kan pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji, ti wọn n pariwo pe Dammy ti daku o, ti wọn si pe orukọ rẹ ni kikan kikan

Bẹẹ láwọn orisirisii iroyin n jade pẹlu awọn ahesọ-ọrọ, Ọpọ iroyin to n lọ lori ayelujara naa lo n salaye pe Dammy gbe oogun jẹ ni nitori isẹlẹ to waye laarin ọrẹkunrin rẹ, Portable ọmọ ọlalọmi.

Gẹ́gẹ́ bí iroyin naa to tẹ wa lọwọ, Damilola ati Portable ni wọn n gbinyanju lati fẹ tẹsiwaju ninu Irinajo ìfẹ wọn lẹyin ti wọn ti ba arawọn mu-nkanlẹ lori itakun ayelujara.

Fọnran fidio akasilẹ ohun kan si ni awọn kan n pin kaakiri ori itakun ayelujara, eyi ti wọn ni Portable ka silẹ, to si jẹ itakurọsọ laarin oun ati Olori Damilola.

Ninu fọnran fídíò ohun naa ni Damilola ti n se adura lakọlakọ fun Portable pe ọla rẹ yoo maa lọ siwaju.

Akasilẹ ohun ori foonu naa fihan pe Damilola ati Portable ti n pada sọrọ bii ololufẹ, ti wọn si fẹ pari ija laarin ara wọn ni bounkẹlẹ.

Eyi ni ohun ti Portable kọkọ gbe sita lati fi di rẹ mulẹ pe Olori Damilola ti pada si ọdọ rẹ gẹgẹ bii ololufẹ.

Ninu fọnran naa ni Olori Damilola ti sọ fun pe ọrẹ kan n gbe ọrọ sita lori ayelujara nipa rẹ pe o ti ba ọkunrin mii lopọ nigba to kuro ni ile Portable.

Dami ni “Ẹni naa ni oun n fun lesi, nitori pe o ti gbọ pe oun ati portable fẹ pada, pe ẹni naa lo n gbe igbekugbe si oju opo itakun ayelujara rẹ.

Nigba ti wọn fọrọjomitoro ọrọ ni Portable bi Olori Damilola pe se o ti ba ọkunrin mii lopọ lẹyin to kuro ni ile oun lootọ.

Ti Olori Damilola si fun lesi pe, oun o se nnkankan to jọmọ bẹẹ, ti ohun si setan lati fi ohunkohun bura.

Portable tun bi leeré pe se o le lọ soju opo itakun ayelujara, ko si se fọnran fídíò lati bura pe oun ko ba ọkunrin mi sun lẹyin to kuro ni ile oun.

Niiṣe ni Dami dalohun pe, oun o le pada si oju opo ayelujara lati lọ sọ ohunkohun mọ, yoo dara pe ki o gba oun gbọ pe oun ko ba ọkunrin mii sun.

Tomije loju ni Olori Damilola se n ba Portable ololufẹ rẹ sọrọ pe ko gbagbọ ninu oun ṣugbọn Portable Ọmọ Olalomi kọ jalẹ lati gba gbogbo ohun ti Olori Damilola n sọ gbọ, to si gbe gbogbo ọrọ naa sita lori ayelujara.

Olori Damilola ni ti awọn akọroyin ba fi le gbe ohun ti Portable sọ si oju opo ayelujara, ohun ko ni pada si ile Portable mọ lailai.

Lẹyin isẹlẹ naa ni awọn ọrẹ Damilola gbe digba-digba sinu ọkọ, ti wọn n pariwo pe o ti daku, tawọn eeyan miran si ni o gbe nnkan jẹ ni.

Lẹyin gbogbo aawọ gbonmisi-omi-o-to naa ni Portable kede pe o ti tan laarin oun ati Olori Damilola.

O ni “Ti ọkunrin mii ba ba iyawo Ifa sun, o di gbere niyẹn.

Portable ni “Pada kẹ ẹ Oun kan n beere lọwọ rẹ pe se wọn tun ti ya ni abi wọn kò ti ya lẹyìn tó kúrò nílé oun. ìtumọ ọrọ “ya” ọun, Portable nikan lo ye, nse lo sa tẹnu mọ pe oun fẹ mọ boya wọn ti ya ni tabi wọn ko ti ya.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ó màse o, Oriyomi b'omijé lójú lásìkò tó n ba àwọn olólùfẹ́ rẹ sọrọ lẹ́yìn to jade kuro lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Ó màse o, Oriyomi b’omijé lójú lásìkò tó n ba àwọn olólùfẹ́ rẹ sọrọ lẹ́yìn to jade kuro lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

  Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ nni, Oriyọmi Hamzat, ti bawọn ololufẹ rẹ sọrọ lati mọ riri wọn …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *