Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":false,"containsFTESticker":false}

Wàhálà, Ija tun bẹ silẹ laarin Ifọn àti Ilobu, ìjọba ipinlẹ Osun kéde kónílé o gbélé lawọn ilu mejeeji

Wàhálà, Ija tun bẹ silẹ laarin Ifọn àti Ilobu, ìjọba ipinlẹ Osun kéde kónílé o gbélé lawọn ilu mejeeji

Aawọ gbonmisi-omi-o-to tun bẹ silẹ laarin ilu Ilobu ati Ifọn-Orolu, tii se ilu meji ti wọn dijọ paala pẹlu ara wọn.

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọbibi ilu Ifon-Orolu lo ke gbajare sita pe awọn agbebọn kan sekọlu sí awọn ni’lobu, ti wọn si dana ibọn bolẹ ni adugbo Apinroro nilu naa.

Isẹlẹ ọhun lo da ibẹru bojo silẹ sọkan awọn olugbe ilu naa, ti wọn si n sa asala fun ẹmi wọn.

Ẹni ori yọ, o dile, koju ma ribi gbogbo ara loogun rẹ ni wọn koowa fi ọrọ naa se.

Nse lawọn eeyan ilu Ifon-Orolu ati Ilobu n naka ija sira wọn lori ọrọ naa ti aawọ oun gbọnmisiomioto si bẹ silẹ laarin ilu mejeeji ọhun.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, Alaga ẹgbẹ to wa ni ilọsiwaju ilu Ifon, Jide Akinyooye fidi isẹlẹ ọhun mulẹ eyi to ni o bẹrẹ ni aarọ ọjọ Isẹgun Tuesday.

O ni ọpọ eeyan lo ti fi ile wọn silẹ nilu Ifon lati sa asala fun ẹmi wọn.

Amọ nigba to n ba awọn Akọroyin sọrọ, Otun Jagun tilu Ilobu, Oloye Goke Ogunsola salaye pe awọn agbebọn ilu Ifon lo kọkọ kọju ija sawọn eeyan to wa ni agbegbe kan nilu Ilobu.

O ni oun gba ipe lọdọ awọn eeyan awon to wa lẹba aala ilẹ pẹlu ilu Ilobu, ti wọn si figbe bọnu pe awọn agbebọn kan lati ilu Ifon ti sekọlu s’awọn.

O ni awọn eeyan awọn to n gbe ni agbegbe Ganga ati Apinroro lawọn agbebọn naa dena de awọn, o si di dandan ki awọn naa gbe ara awọn nija lọna kan tabi omiran.

Wọn wa pe ipade alaafia lọjọ Aje Mọnde, nibi ipade naa si ni Olufọn ti n dunkooko- dun mọhuru.

O wa parọwa fun ijọba ipinlẹ Osun lati gbe igbesẹ to yẹ lati daabo bo awọn nitori ololufẹ alaafia ni awọn, awọn eeyan ilu Ifon si lo n kọlu awọn ni wọn n tọ awọn nija.

Wayi o, lọwọ bayi iijọba ipinlẹ Osun ti kede konile-ogbele ni ilu mejeeji naa, ti wọn si ni esinsin ko gbọdọ ta firi laarin awọn ilu mejeeji naa.

Nigba to n gbe asẹ kalẹ, ninu Atẹjade kan ti Kọmisana feto iroyin, Kolapo Alimi, fi sita lọjọbọ Tọside l’aago meje aarọ si aago meje alẹ ni isẹlẹ naa yoo fi maa waye.

O ni “Gbogbo awọn ti isẹlẹ yii gberu láwọn ti gba niyanju lati fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba ki isẹlẹ ọhun le di afiẹyin ti eegun fi asọ.

O ni Awọn ti da ikọ awọn agbofinro eleto-ààbò sawọn ilu mejeeji ninu eyi ti awọn osisẹ ologun, ọlọpaa ati ikọ ẹsọ ara ẹni laabo ilu wa, lojuna ati da alaafia pada sawọn agbegbe naa.

Ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n da omi alaafia ru lawọn agbegbe naa yoo fimu ko kulubusu-ata ofin eyi ni ikilọ ti ijọba se

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Olùkọ tó n fi’gbaju, Igbamu kọ akẹ́kọ̀ọ́, ọmọ ọdún mẹta ti dero Ọgbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orileede Naijiria ti tari olukọ ileewe alakọbẹrẹ kan, Stella Nwadigo, ẹni to ko …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *