Iroyin pajawiri

l’Ogbomọsọ, Kọntena (Container) ẹ̀yìn ọkọ̀ nla kan rélu kẹ̀kẹ́ Maruwa t’oun t’àwọn èrò inú rẹ lorita Takie, Ògbómọ̀sọ́.

Iṣẹlẹ ìjàmbá ọkọ nla ọhun lo waye lorita Takie, nilu Ogbomọsọ ni nkan bi owurọ ọjọ Isẹgun Tuesday, ọjọ keje, oṣù kínní, ọdun 2025.

l’Ogbomọsọ, Kọntena (Container) ẹ̀yìn ọkọ̀ nla kan rélu kẹ̀kẹ́ Maruwa t’oun t’àwọn èrò inú rẹ lorita Takie, Ògbómọ̀sọ́.

Nse ni ọkọ tirela ẹlẹyin Kọntana naa sọ bireki-ijanu rẹ nù, to sì lọ kọlu awọn èèyàn, debi ti kọntena ẹyin rẹ wolu kẹkẹ maruwa ẹlẹsẹ mẹta t’oun tawọn ero ti o wa ninu rẹ mọlẹ.

Awọn eeyan to wa ninu kẹkẹ naa padanu ẹmi wọn ti wọn sì gbé awọn Olufarakasa mii digbadigba lọ ọgbà ileewosan.

Se ohun ta o jẹ la n wa k’Ọlọhun ma jẹ a pade ohun ti o jẹwa

L’owurọ ọjọ isegun Tuesday lasiko tonikaluku n wa ounjẹ oojọ rẹ, láwọn eeyan naa se kongẹ ìjàmbá laburu ọhun.

Gẹgẹ bí osojumikoro kan se wí lakoko ti n ba awọn Akọroyin sọrọ, o jẹ ki o di mimọ pe nse ni Kontena ẹyin ọkọ nla tirela naa wolu kẹkẹ maruwa ẹlẹsẹ mẹta mọlẹ̵ tawọn èèyàn tó wà nínú rẹ si padanu ẹmi wọn lakoko ti Awakẹkẹ maruwa ọhun fẹ duro gb’ero.

Se lootọ ẹnu Kinihun lowo wa, k’Ọlọrun ọba o ma fi jẹ wa sibi to nira.

Loju ẹsẹ ti iṣẹlẹ ìjàmbá naa sẹlẹ ni awọn ìkọ ẹṣọ eleto aabo, Agbofinro Ọlọpa, ìkọ Àjọ Ẹṣọ oju popo FRSC, Awọn oṣiṣẹ Alabojuto lilọ bibọ ọkọ loju popo, awọn ìkọ ẹṣọ ara ẹni laabo-ilu Civil Defence, at’awọn àjọ eleto-ààbò mii tofi mọ awọn araalu ni wọn jumọ fọwọsowọpọ gbiyanju sa ipa wọn lati doola ẹmi olufarakasa naa.

Nigbati awọn ikọ agbofinro ọlọpaa at’awọn ẹṣọ oju popo sí n dari lilọ-bibọ ọkọ lopopona ti iṣẹlẹ ìjàmbá ọun ti waye.

Awọn Àjọ Ẹṣọ oju popo ati awọn alabojuto lilọ-bibọ ọkọ ti wọ ọkọ nla tirela naa lọ àgọ Ileesẹ Ọlọpa, nigba ti kọntena ẹrú to já ọhun sí wa loju ona Takie titi di akoko ti a n ko ìròyìn yi jọ lọwọ.

Ẹni toun naa ba awọn Akọroyin sọrọ nibi iṣẹlẹ ìjàmbá naa, Pasitọ Oyelami, ti o jẹ ọmọ bíbí ìlú Ogbomoso, fi aidunnu rẹ hàn latari iṣẹlẹ ìjàmbá ọhun to waye, gẹgẹ bi o se wi, o ni, iṣẹlẹ ìjàmbá orita layipo, Takie roundabout yi ti di lemọlemọ, eyi to sì n da ọpọ ẹmi l’egbodo, Ọpọ ẹmi lo n sofo loju ọna naa.

O wa parọwa f’awọn Ijọba lati tete wa ojutu-ona abayọ sí ojú ònà márosè Takie paapaa julọ orita layipo Takie Roundabout to lọ s’ilu Ilorin lati dẹkùn iṣẹlẹ ìjàmbá to n fojoojumo waye níbẹ.

Bakan naa ko sai satẹmọ rẹ pe, ibẹ gan lọpọ emi awọn eeyan ti sọnu ju lọdun to kọja, o ni oju ọna ọhun ni tirela kan ti da ẹmi iya at’awọn ọmọ rẹ meji kan l’egbodo lọdun ti o kọja.

O fikun ọrọ rẹ pe, ti ijọba ba kọ ti wọn kò gbe igbesẹ kankan lori ọrọ yi, oun gan loun o lewaju iwọde-ifẹhonuhan, nitoripe Oju ọna ọhun ti n sekupa awọn eeyan ọmọ Ògbómọ̀ṣọ́ ati alejo pupọ.

O ni, iṣẹlẹ ìjàmbá oju popo yi toogẹ, Ki ijọba tete wa ojutu-ona abayọ si ni kiamọsa.

Pasitọ naa ko sai ba mọlẹbi àwọn èèyàn to farakasa naa kẹdun to si gba ladura fun wọn pe Ọlọrun yoo tu wọn ninu.

Alaga alabojuto ibudokọ awọn ọkọ nla l’Ogbomọsọ (iyẹn Park Management), Adegoke Adeniyi, naa sọ wipe iṣẹlẹ ìjàmbá naa waye latari ọkọ nla kọntena ti o sọ bireki-ijanu rẹ nù, to sì tún gba ọna ọlọna (One-Way) eyi ti o mu relu kẹkẹ Maruwa to n lọ jẹjẹ rẹ mọlẹ

O wa rọ awọn Ijọba Ipinlẹ ati ìjọba àpapọ̀ lati tete wa ojutu-ona abayọ sí ojú ọnà naa.

Bakan naa ko sai rọ àwọn aláṣẹ ìjọba pe ki wọn pàṣẹ fún gbogbo àwọn ẹgbẹ ọlọkọ ero, awọn onikẹkẹ maruwa, at’awọn Ọlọkada ki wọn yé gbero loju popo mọ, ki wọn pèsè aye ibudokọ síbi kan níbi tí wọn yóò ti ma pe ero sinu ọkọ, ki wọn yé fi ẹmi awọn eeyan wewu.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ó di dandan k’áwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú àwọn ọmọdé ni’badan Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, Seyi Makinde lo sọ bẹ

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti jẹ ko di mimọ pe ko si …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *