{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"transform":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Ọlọrun ò fẹ́kú ẹlẹ́sẹ̀ bìkòse ìrònúpìwàdà, àmọ́ ẹni tó sọ àwòrán mi d’Alhaji ó ti yàn láti parun Pásítọ̀ Adeboye sọ bẹ.

Oluṣọaguntan agba naa fun ijọ The Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasitọ Enoch Adeboye lo sọ asọtẹlẹ yi nipa awọn kan to gbe aworan atọwọda imọẹrọ AI eyi to ṣe afihan rẹ gẹgẹ bi arinrinajo Hajj lọdun to kọja.

Pasitọ Adeboye wa ṣalaye lasiko to n ba awọn ọmọ ìjọ rẹ sọrọ nibi eto isin oloṣooṣu Holy Ghost service to waye laẹ ọjọ Ẹti Friday mọjumọ ọjọ Abamẹta Saturday pe eyi tubọ tọka si asọtẹlẹ ti Ọlọrun fi han oun nipa ọdun 2025 pe ọpọlọpọ awọn olupẹgan yoo dide s’oun.

O ni o da oun loju pe ọpọlọpọ awọn eeyan lo ti ri aworan naa lori ayelujara bi awọn eeyan ọhun se lo imọẹrọ AI lati gbe aworan kan to fi oun han gẹgẹ bi Alhaji jade.”

Pasitọ Adeboye sọ pe ohun ti Ọlọrun sọ fun oun ni pe awọn olupẹgan yoo pọ sii lọdun 2025 ṣugbọn pupọ wọn ni ko ni la ọdun 2025 ja.

Amọṣa Adeboye ni bi o tilẹ jẹ wi pe ko dun mọ Ọlọrun ki ẹlẹsẹ ku, Ọlọrun o fẹ iku ẹlẹse bikoṣe ko ronupiwada, amọ awọn eeyan naa ko le mu ọdun 2025 jẹ nitori pe “wọn ko fẹ yipada, wọn ti yan lati parun. ”

Aworan yi bẹrẹ si f’arahan lori ayelujara nibi oṣu kejila ọdun 2024 ti o kọja.

Iwadii fihan pe eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ @Sarkideyforyou loju opo ayelujara X, iyẹn Twitter tẹlẹ lo gbe aworan naa jade eyi to ṣe afihan Pasitọ Adeboye to duro ni Kaabah ni ilu Mecca.

Eeyan to din diẹ ni miliọnu mẹrin lo ti wo aworan naa, igba ẹẹdẹgbẹjọ ni wọn si ti pin aworan ọhun ka, ti awọn bii ẹgbẹsan si ti sọ ọrọ kan tabi omiran labẹ rẹ leyi ti o ti fa onirunru awuyewuye.

Igba ti aworan ati ohun tawọn eeyan nsọ detigbo Adeboye ni Ojisẹ Ọlọrun naa se b’awọn eeyan ọmọ ijọ rẹ sọrọ ti o si gbe awọn to sisẹ naa re pe wọn o ni kolẹ ọdun yi.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Wàhálà, Ija tun bẹ silẹ laarin Ifọn àti Ilobu, ìjọba ipinlẹ Osun kéde kónílé o gbélé lawọn ilu mejeeji

Wàhálà, Ija tun bẹ silẹ laarin Ifọn àti Ilobu, ìjọba ipinlẹ Osun kéde kónílé o …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *