Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"transform":2,"effects":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Pasitọ Adeboye, Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo, Alufa Kumuyi, at’awọn ìránsẹ́ Ọlọrun mii ti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún tuntun 2025 yoo se ri.

Ni ọdọọdun Ọpọ Àwọn èèyàn tó ní afojusun at’awọn iransẹ Ọlọrun lo ma n woye, sọ awọn orisirisi asọtẹlẹ tó nikimi, bẹrẹ lati aisun ọdún tuntun.

Pasitọ Adeboye, Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo, Alufa Kumuyi, at’awọn ìránsẹ́ Ọlọrun mii ti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún tuntun 2025 yoo se ri.

Gbogbo awọn èèyàn yi lo sí má n fi ọrọ ayé àti ìrìnàjò wọn lè Oluwa lọwọ lọdun tuntun, wọn yóò wa ọna lati gbadura, ki ọdun tuntun dun – ko loyin, ko si dara fun wọn, tabi ṣe alakalẹ afojusun awọn nnkan ti wọn fẹ ko sẹlẹ si wọn lọdun tuntun.

Bẹẹ sí ni, Eyi ko yọ awọn ọmọlẹyin Kristi silẹ, paapaa ni ilẹ adulawọ Africa, pẹlu bi wọn ṣe ma n fojusọna fun awọn asọtẹlẹ nipa ọdun tuntun lati ẹnu awọn olori ẹsin ati pasitọ wọn.

Awọn asọtẹlẹ yii lo ma n jade ni aṣalẹ ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, lasiko ti iṣọ-oru irekọja si ọjọ kini ọdun tuntun ba n waye.

Bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ti kilọ pe pẹlẹ-pẹlẹ ni ki awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa maa fi sọ awọn asọtẹlẹ wọn, sibẹ wọn ko danu sisọ rẹ duro.

Awọn asọtẹlẹ nipa ọdun 2025 to ti jade, paapaa lati ẹnu awọn gbajúgbaja ojiṣẹ Ọlọrun wọnyi.

Alufa Agba ijọ irapada, Redeemed Christian Church of God, RCCG, sọ ni olu ijọ rẹ to wa ni ipinlẹ Ogun lasiko isin opin ọdun pe, ọdun ti yoo ni apẹrẹ ni ọdun 2025 y jẹ, eyi ti ẹnikẹni ko ni le gbagbe rẹ.

O ni ọjọ Ẹti ni oun yoo to sọ awọn asọtẹlẹ nipa awujọ agbaye, ati pe oun yoo ṣọra ṣe nipa sisọ asọtẹlẹ nipa orileede Naijiria.

O ni ninu awọn asọtẹlẹ ti oun ba sọ nipa agbaye ni orileede Naijiria yoo ti mu tiẹ.”

Oludasilẹ ile ijọsin Living Faith Church, ti ọpọ tun mọ si Winners Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo, naa sọ asọtẹlẹ fun awọn ọmọ ijọ rẹ ni orumọju ọdun tuntun.

Nile ijọsin rẹ to wa ni Ota, nipinlẹ Ogun, ni Oyedepo ti sọ pe ọdun “ibẹrẹ ọtun, ati ọdun ti awọn eeyan yoo ṣe amuka nnkan ọtun laye wọn”, ni ọdun 2025 yi jẹ.

O ni kosi Wooli kankan to ni agbara lati mu ki nnkan ti Ọlọrun sọ, ko wa si imuṣẹ, “Igbagbọ onikaluku ni yoo sọ boya yoo ṣẹ tabi bẹẹ kọ.”

Pasitọ Daniel Olukọya, to jẹ oludasilẹ ati alamojuto agba fun ijọ Mountain of Fire and Miracle, sọ lasiko iṣọ-oru irekọja sinu ọdun tuntun pe, ọdun iṣẹgun ti ko ṣe e gbe pamọ ni ọdún 2025 yi yoo jẹ.

Ọdun idasi, imupadabọsipo, itusilẹ ti ko ni onka, ati igbedide awọn adari ti yoo mu ayipada wa, ni ọdun 2025.

Ọdun ti o lewu pẹlu ailegbadura pupọ ni, to si tun jẹ ọdun ti a nilo adura lati fi koju iji eto ọrọ aje ati wahala l’agbo eto oṣelu nilẹwa Nàìjíríà.

O ni “Lọdun yii, a nilo adura lati gbogun ti awọn iṣẹlẹ bii omiyale-agbarayasọbu ati awọn ajalu loriṣiriṣi, to fi mọ awọn aisan tuntun ti o le farahan.

Alufa ijọ Deeper Christian Life Ministry, Pasitọ William Kumuyi, naa ko sai sọ asọtẹlẹ nipa ọdun tuntun fun awọn ọmọ ijọ rẹ.

O ni, “ọdun aluyọ, ọdun to kun fun ire ni ọdun 2025 yi jẹ, ninu eyi ti ọta ko nii le sọ bi irinajo aye rẹ yoo ṣe ri.

Pasitọ agba fun ileeṣẹ iranṣẹ Streams of Joy, Jerry Eze, naa sọ tẹlẹ sinu aye awọn ọmọ ijọ rẹ pe, gbogbo oun to n pa wọn lẹkun ni yoo di ajọyọ lọdun 2025.

Ọdun iyanu ojoojumọ, ati eyi ti awọn eeyan naa yoo gba imisi, igbega lawujọ agbaye, ni ọdun tuntun yi 2025 yoo jẹ.”

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ìdí ẹ re t’áwọn ọmọ ìsọta fi lọ s’èyà f’Ọ́ba alayé kan nipinlẹ Ọsun.

Ẹni ba foju d’Ọba, awo a awo, ni wọn ma n sọ, laye atijọ amọ, …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *