Lọdún 2025 yi àdínkù yóò débá ọ̀wọ́ngógó to n koju ilẹwa Nàìjíríà – Ààrẹ Bọla Tinubu lo sọ bẹ.

Lọdún 2025 yi àdínkù yóò débá ọ̀wọ́ngógó to n koju ilẹwa Nàìjíríà – Ààrẹ Bọla Tinubu lo sọ bẹ.

Lọdún 2025 yi àdínkù yóò débá ọ̀wọ́ngógó to n koju ilẹwa Nàìjíríà – Ààrẹ Bọla Tinubu lo sọ bẹ.

Ààrẹ ilẹwa Naijiria Bola Ahmed Tinubu ti kéde láti ṣe ìdásílẹ̀ iléeṣẹ́ kan, ti o pe ni National Credit Guarantee Company lójúnà àti mójútó ìpèníjà táwọn èèyàn ọmọ Nàìjíríà ń kojú lórí ọ̀wọ́ngógó to ń bá orílẹ̀ èdè yìí.

Tinubu ní iléeṣẹ́ náà ni yóò maa mójútó iye owó oúnjẹ àti oògùn káàkiri Nàìjíríà.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ to sọ láti fi kí àwọn ọmọ orileede Nàìjíríà ku àmójubà ọdún tuntun ni Tinubu ti kéde ìgbésẹ̀ naa.

Ó sọ pé ìgbésẹ̀ náà tún máa ṣe kóríyá fún ìpèsè àwọn oògùn lábẹ́lé nínú ọdún tuntun yìí.

Gẹ́gẹ́ bi ààrẹ ṣe sọ, iléesẹ́ náà, lo ni ìrètí wà pé yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kó tó di ìparí oṣù Kẹfà ọdún 2025 yi, o ni o jẹ́ àjọṣepọ̀ àwọn iléeṣẹ́ àti àjọ ìjọba bíi Bank of Industry, Nigerian Consumer Credit Corporation, Nigerian Soverign Investment Agency, Ministry of Finance Incorporated, tó fi mọ́ àwọn ẹ̀ka aládàni.

Ààrẹ ní òun mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà ni àwọn èèyàn ọmọ Nàìjíríà kojú ní ọdún tó kọjá lọ àmọ́ òun ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà pé dídùn ni ọsàn yoo so lọ́dún 2025 yi.

Ó wòye pé owó epo bẹntiróòlù ti ń já wálẹ́ díẹ̀díẹ̀, tí àlékún sì ti ń ba okoòwò ilẹ̀ òkèrè.

Bákan náà ló ní owó ilẹ̀ òkèrè tí Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ ni o tún ti lọ sókè si, ti Náírà náà sì ti ń gbèrú, léyìí to n túmọ̀ sí pé ìgbá ọ̀tun ti ń bá orileede Nàìjírià.

Àmọ́ ó ní pẹ̀lú gbogbo èyí, ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ àti oògùn lílò jẹ́ nǹkan gbòógì tó fa ìnira fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjírià lọ́dún 2024 to kọja.

O ni, “Ní ọdun 2025 yi ìjọba oun ní àfojúsùn láti mú àdínkù bá ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ nípa pípésè oúnje lọ́pọ̀ yanturu àti ṣíṣe kóríyá fáwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe oògùn lábẹ́lé.”

Tinubu ní òun ní ìfarajìn láti ri dájú pe ọ̀wọ́ngógó tó wà ní ìdá 34.6% báyìí já lọ silẹ̀ di 15% nígbà tó bá fi máa di ìparí ọdún 2025.

Ó fi kun pé àwọn yóò túnbọ̀ máa tẹ̀síwájú láti máa pèsè ẹ̀yáwó fáwọn aladanni àtàwọn ẹ̀ka tó ṣe kókó láti ri pé ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà rú gọ́gọ́ si.

Ààrẹ Tinubu tún ṣàlàyé pé àpérò táwọn ọ̀dọ́ ń bèèrè fún, tó jẹ́ ọ̀kan lára nǹkan táwọn ń fẹ́ lásìkò tí wọ́n ṣe ìwọ́de “Ẹ fopin sí ìjọba buruku” #EndBadGovernance nínú oṣù Kẹjọ ọdun 2024, yóo gbérasọ láìpẹ́ ninu ọdun yi bakan naa.

Ó ní ko tó di ìpari osù Kẹta ọdún 2025 yìí ni àpérò náà yóò wáyé.

O ní èyí ṣàfihàn ìfarajìn ìjọba òun láti ri daju pé àwọn kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ lójú ọ̀nà láti gbé Nàìjírià dé èbúté ògo.

“Iléeṣẹ́ tó ń rí si ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ yóò kéde ìlànà tí wọn fi máa mú àwọn ọ̀dọ́ tí yóò jẹ́ aṣojú tí yóò kópa níbi àpérò náà láìpẹ́.”

Ó wá rọ àwọn èèyàn, ọmọ Nàìjíríà láti máa hùwà bíi ọmọ Nàìjíríà rere àti pé àwọn máa tó bẹ̀rẹ̀ ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìwúlò àwọn èèyàn láti nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀ èdè baba wọn.

Ààrẹ wòye pé kò sí bí ètò táwọn bá gbé kalẹ̀ bá ṣe dára tó, tí kò bá si ìfẹ́ láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí, ó ṣeéṣe kí àwọn ètò náà má so èso rere.

Bakan naa lo tún pàrọwà sáwọn gómìnà àtàwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ láti ṣàmúlò àwọn àǹfàní tó wà lẹ́ka ètò ọ̀gbìn, àtúnṣe owó orí gbígbà láti sún orileede wa Nàìjírià sọwọ íwájú .

Ó wa kan sáárá, gbosuba fáwọn gómìnà fún ṣíṣe àmúlò ètò àwọn ọkọ̀ tó ń lo afẹ́fẹ́ gáàsì àtàwọn tó ń lo iná agbara mọ̀nàmọ́ná.

Bẹ́ẹ̀ náà ló yin àwọn ọ̀dọ́ lákin fún ìfaradà wọn láti ìgbà tí ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní oṣù mọ́kàndínlógún sẹ́yìn, pé gbogbo rẹ̀ kò ní ṣègbé, o ni awọn ti wọn jẹ ọwọn gogo ni wọn yoo jẹ ọpọ rẹ

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ààrẹ Tinubu ti já awọn Ọmọ Naijiria kulẹ̀, kòsí ìyàtọ̀ làárín isejọba rẹ̀ àti Adolf Hitler

Aarẹ Ona Kakanfo tilẹ Yoruba, Iba Gani Adams sọ pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *