Iroyin pajawiri
Ẹ̀yin Abiamọ o, ẹ má jẹ ki wọ́n pa Naomi o, olúọmọ ló jẹ́ fún mi. - Ìyá t'obi Olorì Naomi lo rawọ́-ẹ̀bẹ̀ bẹ t'omijé-lójú.

Ẹ̀yin Abiamọ o, ẹ má jẹ ki wọ́n pa Naomi o, olúọmọ ló jẹ́ fún mi. – Ìyá t’obi Olorì Naomi lo rawọ́-ẹ̀bẹ̀ bẹ t’omijé-lójú.

Ẹ̀yin Abiamọ o, ẹ má jẹ ki wọ́n pa Naomi o, olúọmọ ló jẹ́ fún mi. – Ìyá t’obi Olorì Naomi lo rawọ́-ẹ̀bẹ̀ bẹ t’omijé-lójú.

Pasitọ Olufunmilayo Ogunseyi, iyẹn mama to bi Olori tẹlẹ fun Ọọni ifẹ, Naomi Silekunola, ti fi omije bẹbẹ nipa ọmọ rẹ, ti o wa lọgba ẹwọn o ni ki gbogbo abiamọ aye ma jẹ ki wọn pa Naomi oun lọmọ tori pe olu ọmọ oun lo jẹ.

Ninu fọnran fidio kan to wa loju opo itakun ayelujara Instagramu olori Naomi ni mama naa ti n sunkun ṣalaye nipa apeje to ran ọmọde marundinlogoji lọ sọrun lọjọ kejidinlogun, oṣu kejila ọdun 2024 yii.

A o rántí pé, Olori Naomi lo ṣagbatẹru àpèjẹ- ifunni-lounjẹ ọfẹ to ti ni oun fẹ ran ẹgbẹrun marun-un awọn ọmọde lọwọ, ti Oriyomi Hamzat si ba a kede rẹ lori redio-ileesẹ igbohunsafẹfẹ rẹ.

Iṣẹlẹ naa lo gbe Naomi de agọ Ileesẹ ọlọpaa, ileẹjọ ati ọgba ẹwọn, nibi ti adajọ ti ni ki wọn fi i si titi di oṣu kin-in-ni ọdun 2025 ti igbẹjọ yoo tun waye.

Iya naa wa ni, ki wọn dakun-dabọ ṣaanu oun, ki wọn ma jẹ ki wọn ba aye oun jẹ, ọmọ oun o mọ nnkankan, aago mẹwaa ni wọn fi eto si, aago mẹrin aabọ idaji ni wọn ti n tẹra wọn pa nigba ti eto naa yo fi bẹrẹ.

O rawọ-ẹbẹ, O ni ki wọn ma jẹ ki wọn pa Naomi toripe, oluọmọ oun lo jẹ Iya rẹ ni, Ọdun kẹwaa re to ti n se iru eto yii fun awọn ọmọde, arugbo ati awọn alaboyun.

Eto naa lo gbe wa s’Ibadan lati mu idẹrun ba awọn èèyàn papajulọ awọn ọmọde.

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ, Pasitọ Ogunseyi sọ pe funra Naomi lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to wọn leti ni àgọ Ileesẹ ọlọpaa Iyaganku, n’Ibadan, tiise Oluilu ipinlẹ Ọyọ.

O ni awọn jọ lọ si àgọ Ileesẹ Ọlọpa naa ni, wọn si da a duro latigba naa ni wọn ti fi i s’ahamọ, wọn bẹrẹ si i fọrọ wa a lẹnu wo.

Iya rẹ naa ni ”Ojiji ni wọn gbe e lọ si ileẹjọ, iya naa ni ọun kabamọ pe oun o rẹni sọ fun oun pe bo ṣe maa ri fun oun ni osu Kejìlá, ọdún 2024 yi oun i ba ti dira koun fun’ja.

Iya Naomi ni, ”oun o mọ eeyan kankan o, ki awọn èèyàn saanu oun.

O wa sọ siwaju pe oun ba awọn mọlebi ti wọn padanu awọn ọmọ wọn nibi iṣẹlẹ naa kẹdun, tori ibanujẹ nla ni fun Obi lati padanu ọmọ rẹ laipẹ ọjọ, o wa gba ladura fun wọn pe iru iṣẹlẹ bẹ koni sẹlẹ si wọn mọ wọn o tun tan naa wo saare ọmọ wọn mọ.

Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila ọdun 2024 yi ni wọn gbe Naomi Silekunola lọ sile ẹjọ Majisireeti kan to wa ni Iyaganku, niIu ibadan.

Nibẹ ni Adajọ Olabisi Ogunkanmi ti paṣẹ pe ki wọn fi olori tẹlẹ naa pẹlu Oriyomi Hamzat to ni ileeṣẹ redio ti wọn ti kede eto naa si ahamọ ọgba ẹwọn.

Bakan naa ni adajọ paṣẹ pe ki wọn fi olori ile ẹkọ Islamic High School, Bashorun, Ibadan, ti eto naa ti waye iyẹn Ọgbẹni Fasasi Abdulhahi Babatunde si ẹwọn.

Ọgba ẹwọn Agodi ni Adajọ Ogunkanmi sọ pe ki wọn fi wọn pamọ si titi di igba ti igbẹjọ yoo tun fi waye lọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Wọn fẹsun kan” Naomi Silekunola, Oriyomi Hamzat, Fasasi Abdullahi Babatunde ati awon yooku ti wọn ti sa lọ bayii, pe wọn gbimọ pọ lati huwa to le fa iku kiakia, lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024 nipasẹ eto apejẹ ti wọn gbe kalẹ.

Fun idi eyi, wọn ni wọn huwa tako abala 324 ofin iwa ọdaran ipinlẹ Oyo, ti wọn se lọdun 2000.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ọpẹ oo, Ilé ẹjọ́ gba béèlì Oriyomi, Naomi ati Ọga agba ile-ẹkọ gírámà Abdullahi, pẹlu ìkìlọ̀ ńlá fún Oriyomi

Ile ẹjọ giga to wa nilu Ibadan ti gba beeli gbajumọ agbohunsafẹfẹ nni, Oriyomi Hamzart …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *