Alhaja Morenike Olatunji, to jẹ iya fun oloogbe, Abdukadir Olatunji Jimoh, to ku satimọle ọlọpaa niluu Ilorin ti sọ pe, oloogbe naa ni o n tọju oun ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo.
Alhaja Morenike sọ ọrọ yi lasiko to n ba awọn Akọroyin sọrọ nile rẹ to wa ni Balogun Fulani, niluu Ilorin.
Obinrin naa ni kii ṣe pe oloogbe naa nikan loun bi, ṣugbọn oun pẹlu rẹ lawọn mọ ọwọ ara awọn julọ, ti awọn si jọ maa n damọran.
Alhaja Morenike ni ilu Offa ni ọmọ oun ti n ṣisẹ ṣugbọn awọn ọmọ rẹ mejeeji wa lọdọ oun, ti ọmọ naa si maa n yọju sile ni gbogbo igba.
O fi kun-un pe baba rẹ wa lori akete aisan ti awọn n jọ tọju rẹ lọwọ, laimọ pe yoo fi baba naa saye lọ lojiji, lai saisan, lai rotẹlẹ.
Awọn obi oloogbe Abduquadir Olatunji ti wa ke gbajare si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati kan-an nipa fun ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn ṣe iwadii ati idajọ ododo lori iku to pa ọmọ awọn.
Iya oloogbe naa sọrọ pẹlu omije loju wi pe ki Ọlọrun ṣedajọ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọdọkunrin naa.
O wa rawọ ẹbẹ si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ati gbogbo awọn alẹnulọrọ lawujọ ki wọn ma ṣe wo ẹbi oun niran.
O ni ki wọn dasi ọrọ yii, lati ṣewadii iku to pa ọmọ oun, ki wọn si ṣe idajọ ododo.
Gbogbo awọn ọdọ agbegbe naa lo peju si ibi ti ọfọ ti ṣẹ ọhun ti wọn si n fapa janu pe Awọn ko ni gba ṣugbọn awọn agba ile naa n fọwọ le wọn lejika.
Ẹwẹ, ọga agba ọlọpaa patapata nilẹwa Naijiria, Kayọde Adeolu Egbetokun ti ṣabẹwo si iluu Ilorin lati ki mọlẹbi oloogbe ọhun.
Ọga ọlọpaa naa ni oun waa ba awọn mọlẹbi Ọlatunji kẹdun lori ohun to ṣẹlẹ.
O ti wa paṣẹ ki iwadii-ifimufinle to lọọrin bẹrẹ lori iku ọdọkunrin naa ni kanmọkobo.