Iroyin pajawiri

Òrìṣà bi Èṣù ni Jesu Kristi ati Ànọ́bì Muhammad, òjísẹ́ Elédùmárè kan naa ni wọn, Ifáyemí Elebuibon ló sàlàyé ọ̀rọ̀ bẹ.

Araba Awo ti ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibọn ti ṣalaye ohun ti Jesu, Mohammadu ati Esu jẹ.

Ifayẹmi ninu ọrọ rẹ, o ni Eṣu jẹ oriṣa ati Ojisẹ Olodumare bi Jesu Kristi ati Annabi Muhammad ṣe jẹ oriṣa ati Ojisẹ fun Olodumare.

Baba Ifeyemi tun tẹsiwaju pe, aṣiṣe ni alufaa Samueli Ajayi Crowther, ẹni to tumọ Bibeli lede Gẹẹṣi si Yoruba ṣe latari bo ṣe pe Esu ni Satani.

O ni Satani ati Esu yatọ sira wọn, o ni Eṣu jẹ iranṣẹ fun gbogbo eeyan lati le gbe gbogbo ẹbọ ati adura wọn lọ si ọdọ Ọlọrun ọba Olodumare lati le jẹ ko ṣe itẹwọgba niwaju Olodumare.”

Ifakayode Ifaniyi babalawo yi naa tun sọrọ lori oun ti Eṣu jẹ.

Ifaniyi sọ pe Esu kii ṣe ẹni ẹkọ tabi ẹni egbe gẹgẹ bi awọn ẹlẹṣin Musulumi ṣe maa n sọ o, o ni Satani lẹni ẹkọ ẹni e gbe.

Ifakayode fi kun ọrọ rẹ pe Eṣu jẹ oriṣa to ni aanu ju gbogbo oriṣa ẹgbẹ ẹ ti Olodumare da si aye ati si ọrun.

O ni “Eṣu ki se abani wa ọ̀ràn bi a o rí da ti ọpọ eeyan ma n pe e.

“Eṣu jẹ arẹmọ ati olotitọ oriṣa, bakan naa si ni o jẹ oriṣa ti o maa n ba eeyan bẹbẹ niwaju Olodumare lọpọ igba ti eeyan ba wa ninu isoro.”

Bẹẹ náà ni Ifashola Esuleke ṣalaye fun awọn oniroyin pe bi gbogbo eeyan ba le gba wi pe, Eṣu kii ṣe Satani, o da oun loju pe, orile-ede Naijiria yoo gba alaafia pada.

Ifashola ni idi oriṣa Eṣu ni wọn bi oun si, oriṣa Eṣu naa ni oun n sin lati igba ewe oun titi di asiko yii.

Oni oun ti rinirin ajo lọ si orile-ede aláwọ̀ funfun kaakiri ti oun ko si kabamọ wi pe oun n sin oriṣa Eṣu rara.

Gbogbo ọrọ wọnyii lo waye lasiko ti awọn ọdọ onisẹse ti ipinlẹ Osun n ṣe ayajọ ọdun Eṣu, lati jẹ ki awọn eeyan mọ ìyàtọ̀ to wa laarin Eṣu ati Satani.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Lẹyìn ọdún mẹta ti Alaafin àná ti wàjà Owoade Gomins Makinde buwọ́lù ìyànsípò Owoade gẹ́gẹ́ bí Alaafin Ọ̀yọ́.

Gómìna ipinlẹ Ọyọ onimọ-ẹrọ Seyi Makinde, ti buwọ́lù iyansipo Ọmọọba Abimbola Ọwọade gẹgẹ bí Alaafin …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *