Wọ̀nyí ni ìlèrí tí ìjọba ṣe fún ẹbí àwọn tí wọ́n tẹ̀ pa nibí tí wọ́n ti fẹ́ gba oúnjẹ ọ̀fẹ́ n’Ibadan, ilu Abuja àti nipinlẹ Anambra.
Igbakeji aarẹ orilẹede wa Naijiria, Kashim Shettima ti fọkan awọn araalu t’ọrọ kan niti isẹlẹ atẹpa to wa kaakiri orileede yi balẹ pe gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn nibi eto pinpin ounjẹ to waye lọsẹ to kọja ọhun lawọn yoo ṣe iranwọ fun mọlẹbi wọn, lati fi pa ironu wọn rẹ.
Shettima lo sọrọ yii ninu atẹjade ibanikẹdun kan to fi sita lanaa lọjọ Aiku, Sunday ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 yi niluu Abuja.
Igbakeji aarẹ kọminu gidi lori iṣẹlẹ ajalu naa, to si lo ba oun pẹlu ọpọ eeyan, paapaa ijọba Naijiria lọkan jẹ.
Nibẹ lo ti gbadura fun gbogbo mọlẹbi ti wọn padanu awọn eeyan wọn, wi pe ki Ọlọrun tu wọn ninu.
Shettima, nigba to n ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi ajalu apapọ lorileede yi o jẹ ko di mimọ pe ijọba apapọ ti paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba tọrọ kan lati dide iranlọwọ fun awọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn.
Ninu ọrọ rẹ to kọ sinu atẹjade ibanikẹdun naa, Shettima sọ pe Iṣẹlẹ to mu ẹmi awọn alaisẹ lọ yii “ba oun lọkan jẹ gidi”
O ni adura oun ati ero ọkan oun lọ si gbogbo awọn mọlẹbi ti ọkan wọn gbọgbẹ, to fi mọ awọn to farapa, ti wọn si n gba itọju lọwọ.”
Shettimma tẹsiwaju pe iṣẹlẹ ọhun ko iporuru ọkan ba oun lati rii pe ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa awọn ọmọde ti sọnu sibi iṣẹlẹ titẹ ara ẹni pa naa eyi to yẹ ki wọn ti dena rẹ, ka ni eto ati ilana daadaa wa nilẹ fun.
O ni pipadanu awọn ẹmi kii ṣe fun awọn ipinlẹ to ti isẹlẹ nikan bi ko ṣe fun gbogbo orileede Naijiria.
O wa jẹjẹ atilẹyin rẹ naa, o ni ijọba orileede yi ti duro digbi lati dide iranwọ fun gbogbo mọlẹbi lasiko iṣoro yii, a ti pe ko si igbiyanju ti awọn maa gbe sẹgbẹ kan lati fi pese iranwọ ti wọn ba n ilo fun wọn.
Fun awọn ti wọn ṣi n gba itọju lọwọ lawọn ile iwosan kaakiri, ipadabọsipo wọn jẹ ijọba logun, ti awọn si maa duro ti wọn lasiko ipenija yii, igbakeji Aarẹ Kashim Shettima lo sọ bẹẹ.