Alasẹ ati oludari Ileesẹ redio igbohunsafẹfẹ Agidigbo FM nilu Ibadan, Oriyomi Hamzat d’ero ileewosan lasiko tó dákú lẹyìn iṣẹlẹ aburu to se bẹ mú ọpọ àwọn ọmọdé lọ nigba ti awọn miiran sí tun farapa.
Gẹgẹ bí ẹnìkan to ba awọn oniroyin sọrọ se wí, ipo ailera Hamzat ko sẹyìn iṣẹlẹ buruku airotẹlẹ to ba lojiji nibi eto ayẹyẹ àpèjẹ eyi ti Olori Ọọni tẹlẹri Naomi Silekunola ṣàgbékalẹ̀ rẹ.
Alaga Ileesẹ redio Agidigbo FM nilu Ibadan yi ni wọn lo daku gbọnrangandan ti wọn si sare gbe digbadigba lọ ile iwosan, nibi to ti n gba itọju lọwọ nileewosan kan ti wọn fi orúkọ bo lasiri.
Iṣẹlẹ ọun lo jẹ ohun tó bá ní lojiji to si dà jinnijinni, ọgbẹ ọkàn silẹ leyi to sokunfa didaku Alaga Ileesẹ redio Agidigbo naa.
Ẹsẹ girigiri nibi ti ẹgbẹrun marun awọn ọmọde pejọ si nibi ti wọn ti ṣèlérí láti pin ounjẹ ọfẹ ati owo fun nibi eto ayẹyẹ ipari ọdun.
Wàhálà ọhun lo bẹrẹ nígbà tí àwọn èèyàn bẹrẹ sí ni ti-ara wọn- sáré girigiri l’ojuna lati ráyè wọnú gbọ̀ngàn ibi ti eto naa ti waye lẹyìn tí àwọn Àjọ to sagbatẹru eto àpèjẹ ifunni-lounjẹ ọfẹ ati owo gunlẹ sí gbọngan ọun.
Aarẹ ilẹwa Nàìjíríà, Aarẹ Bola Tinubu ti wa pàṣẹ ki wọn bẹrẹ Iwaadi-ifinmufinle to loorin lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ buruku naa.
Ninu atejade kan nipasẹ Agbẹnusọ rẹ, Bayo Onanuga, Aarẹ fi aidunnu ọkan rẹ, latari awọn Olufarakasa to pàdánù ẹmi wọn, ti o sí bá àwọn ẹbi ti wọn pàdánù awọn ọmọ wọn kẹdun ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ.
Aarẹ Tinubu ko sai tẹnumọ isepataki fún Iwaadi-ifinmufinle naa lati mọ boya aikasi- aifiyesi-aika-nkan kun tabi igbesẹ ti wọn kan mọọmọ se ni lo ṣokunfa iṣẹlẹ buruku naa.
O wa fi dá àwọn aráàlú loju pé, akoyawọ ati otitọ yóò ṣe atọna fún igbesẹ Iwaadi-ifinmufinle naa.