Iṣẹlẹ aburu ọhun lo waye nilu Ibadan, tiise Oluilu ipinlẹ Ọyọ l’ọjọru Wednesday, ọjọ kejidinlogun, osu kejila nibi eto ayẹyẹ opin ọdún awọn ọmọdé ìyẹn Children’s Carnival ti awọn ajọ kan sagbatẹru rẹ.
Gẹgẹ bí iroyin naa tí a gbọ, isare girigiri, iwariri awọn ọgọrọ eeyan lo sokunfa iṣẹlẹ laabi naa.
Lakoko ti didagirigiri naa waye ni ọpọ àwọn ọmọ kékeré ti wọn ko lọjọ lori tí padanu ẹmi wọn.
Bi o tile jepe a ko ti le fidi ẹ mulẹ iye àwọn ọmọde náà naa ti wọn padanu ẹmi wọn a ko le sọ ni pato.
Iṣẹlẹ ọhun lo jẹ ohun tó banilọkanjẹ púpọ, a fi K’Eledua tu ọkan awọn mọlebi ti awọn ọmọ wọn bá iṣẹlẹ naa lọ.
Gẹgẹ bí iroyin ti ileesẹ iroyin The PUNCH gbe jade, wọn ni o to ọgbọn niye awọn ọmọde to pàdánù ẹmi wọn, nigba ti awọn miiran si f’arapa lakoko iṣẹlẹ ijamba naa.
Ninu atejade kan to jẹ gbigbe jade sita l’ọjọru Wednesday, Kọmisọna f’eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọyọ Ọmọ-Ọba Dotun Oyelade, fìdí iṣẹlẹ naa múlẹ.
Gẹgẹ bi o ti wi o ni eto ayẹyẹ opin ọdún fawọn ọmọ kékeré ti o waye níleewe Basorun Islamic High School, nilu Ibadan jẹ ohun ti o ba ni ninu jẹ.
Oyelade jẹ kó di mímọ̀ pé, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gbe ìgbésẹ akin ni kanmọkobo lẹyìn tí iroyin iṣẹlẹ laburu na lù igboro kan.
Kọmisọna naa ni awọn Olufarakasa ti jẹ gbigbe lọ s’awọn ọgbà ileewosan lagbegbe ilu Ibadan fún itọju.
Nigba to n mọriri o dupẹ lọwọ Kọmisọna f’eto ilera (iyẹn Commissioner for Health) nipinlẹ Ọyọ, Oluwaserimi Ajetunmobi, fún igbesẹ akin ti wọn gbe pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto-ilera lati seranwọ nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Oyelade ni, ijọba ipinlẹ Ọyọ yóò sa gbogbo ipa ati agbara rẹ lati satilẹyin-seranwọ fawọn to forilugbadi iṣẹlẹ laburu naa niru akoko ìṣòro yi.
O ni, Ijọba ko lọwọ ninu eto naa, bẹẹ ni Ileesẹ eto-ilera ko rán enikankan lati pèsè àwọn ohun-idẹrun fun eto ayẹyẹ opin ọdún fawọn ọmọde.
Oyelade, bakanna ko sai tẹnumọ isepataki sise agbekalẹ eto lọnà tó dara lọnà tí kò ní mu ewu dani, papajulọ awọn eto to rọ mọ, awọn ọmọde ati awọn agbalagba.
Kọmisọna ni, awọn sì n duro dè esi Iwaadi-ifinmufinle iroyin lat’ọdọ Kọmisọna Ọlọpa lati mọ pato iye àwọn ọmọ kékeré to ba iṣẹlẹ laburu naa lọ.
O wa rọ gbogbo àwọn Òbí ati alagbatọ ti wọn kò bá rí ọmọ wọn, ki wọn se bẹ lọ yẹ awọn ọgbà ileewosan wo nilu Ibadan, nibi ti wọn gbe awon ọmọ kékeré to farakasa naa lọ fún itọju to péye, pẹlu ami idanimọ ni awọn ileewosan bi Patnas Hospital, Basorun; Western Hospital, Basorun; Ringroad State Hospital; Molly Specialist Hospital; ati ọgbà ileewosan College ileewe gíga fasiti Ibadan.
Ni orúkọ Ijọba ipinlẹ Ọyọ, o ba awọn mọlebi ti awọn ọmọ wọn farakasa ninu iṣẹlẹ laburu naa kẹdun, to sì rọ àwọn aráàlú lati se suuru gẹgẹ bí iroyin gbogbo nipa iṣẹlẹ naa ti n jẹ gbigba jade, ti ijọba sì ti n ṣètò atilẹyin fawọn Olufarakasa ti wọn farakasa ninu isẹlẹ naa.