Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"transform":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Ademọla Lookman d’ọmọ tí wọ́n nsọ pẹ̀lu b’óse gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jù lọ nílẹ Adulawọ f’ọdun 2024.

Agbabọọlu fun orileede wa Naijiria ati ilẹ Atalanta ni Italy, Ademola Lookman lo ti gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi agbabọọlu to dara julọ nilẹ adulawọ Africa f’ọdun 2024.

Lookman ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun lo fi ẹyin awọn alatako rẹ lati Cote d’Ivoire, Brighton, Hove Albion, Simon Adingra, Serhou Guirassy lati Guinea ati Borussia Dortmund, janlẹ̀.

Awọn mii tun ni ọmọ orile-ede Morocco to tun n gba bọọlu fun ilẹ Paris Saint-German, Achraf Hakimi, to fi mọ goli fun Mamelodi Sundowns, Ronwen Williams lati orileede South Africa.

Ilu Marrakech ni orile-ede Morocco, ni eto naa ti waye.

Gbigba ti Lookman gba ami ẹyẹ ti mu ko di igba keji ti agbabọọlu ilẹwa Naijiria gba a laarin ọdún meji.

Ta o ba gbagbe a o ranti pe Victor Osimhen lo gba a lọdun 2023 to kọja.

Ninu ọrọ rẹ, Lookman mọriri Ọlọrun, o dupẹ lọwọ gbogbo eniyan, papajulọ awọn ọmọ Ilẹwa Nàìjíríà fún ìfẹ ati aduroti wọn.

O ni, ọdun mẹrin sẹyìn, oun ba ijakulẹ pade, ṣugbọn nibayi Ọlọrun ti gbogo f’ọlẹ oun, Oun pada di ẹni tí gbogbo agbaye n ki ku oriire fún àṣeyọrí-aseyege lẹnu iṣẹ ere ìdárayá ere bọọlu alafẹsẹgba.

O gba awọn eeyan l’amọran papajulọ awọn ọdọ lati ma ṣe jẹ kí ijakulẹ ko se idiwọ fún igbega wọn, ki wọn sì má ṣe kaarẹ ọkan labẹ bi o ti hu ki o ri.

Ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 1997, ni wọn bi Ademola Olajide Alade Lookman, niluu Wandsworth ni England.

O ṣoju England ni ipele Under-19 ati Under-21, ko to o yàn lati maa ṣojú ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti ilẹwa Naijiria to jẹ ilẹ baba rẹ.

Ọdun 2022 lo kọkọ gba bọọlu fun Naijiria.

Ademola Lookman wa lara ikọ to ṣojú Naijiria ni Africa Cup of Nations lọdun 2023 ti Ivory Coast fi f’ẹyin wọn janlẹ ni ipele aṣekagba.

Igba mẹtadinlọgbọn lo ti ṣojú Naijiria, o si gba bọọlu sinu àwọ̀n ni igba mẹjọ, o si ti gba ami ẹyẹ M.O.N.

Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Atalanta jawe olubori ni 2023-2024 Europa League, nigba to gba ‘hat-trick’ wọ inu awọn Bayer Leverkusen ni aṣekagba, eyi to mu wọn bori, wọnyi ati awọn aseyọri mi ni lookman ti i ninu ere idaraya bọọlu alafẹsẹ gba.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fòntẹ̀ lù ìdájọ́ ikú oloye Ramon Adedoyin latari po lọwọ nínú ikú tó pa Akẹkọọ OAU Timothy Adegoke.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti o fi di kalẹ niluu Akurẹ ti buwọ́lù idajọ iku fun …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *