Iroyin pajawiri

Monthly Archives: December 2024

Ẹ̀yin Abiamọ o, ẹ má jẹ ki wọ́n pa Naomi o, olúọmọ ló jẹ́ fún mi. – Ìyá t’obi Olorì Naomi lo rawọ́-ẹ̀bẹ̀ bẹ t’omijé-lójú.

Pasitọ Olufunmilayo Ogunseyi, iyẹn mama to bi Olori tẹlẹ fun Ọọni ifẹ, Naomi Silekunola, ti fi omije bẹbẹ nipa ọmọ rẹ, ti o wa lọgba ẹwọn o ni ki gbogbo abiamọ aye ma jẹ ki wọn pa Naomi oun lọmọ tori pe olu ọmọ oun lo jẹ. Ninu fọnran fidio …

Ka si »

Ọmọ tó ń tọ́jú mi ni wọ́n ti d’ẹmi rẹ l’egbodo yi o Ìyá ọkùnrin tó kú s’àgọ́ ọlọ́pàá nilu Ilorin lo kọminú bẹ.

Alhaja Morenike Olatunji, to jẹ iya fun oloogbe, Abdukadir Olatunji Jimoh, to ku satimọle ọlọpaa niluu Ilorin ti sọ pe, oloogbe naa ni o n tọju oun ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo. Alhaja Morenike sọ ọrọ yi lasiko to n ba awọn Akọroyin sọrọ nile rẹ to wa …

Ka si »

Òrìṣà bi Èṣù ni Jesu Kristi ati Ànọ́bì Muhammad, òjísẹ́ Elédùmárè kan naa ni wọn, Ifáyemí Elebuibon ló sàlàyé ọ̀rọ̀ bẹ.

Araba Awo ti ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibọn ti ṣalaye ohun ti Jesu, Mohammadu ati Esu jẹ. Ifayẹmi ninu ọrọ rẹ, o ni Eṣu jẹ oriṣa ati Ojisẹ Olodumare bi Jesu Kristi ati Annabi Muhammad ṣe jẹ oriṣa ati Ojisẹ fun Olodumare. Baba Ifeyemi tun tẹsiwaju pe, aṣiṣe ni alufaa Samueli …

Ka si »

Ògbómọ̀sọ́ Ajílété Cradle Carnival, àkọ́kọ́ irú ẹ̀ nílu Ògbómọ̀sọ́ fakọyọ.

Nse nita pe tero pe tẹsẹ o si gbero nibi Asekagba eto ayẹyẹ ọdun ibilẹ Ògbómọ̀ṣọ́ Cradle Carnival to waye l’ọjọ aje Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, osu Kejìlá ọdún 2024 yi ni papa igbabọọlu Sọun Township Stadium. Ṣaaju ki eto asekagba naa to bẹrẹ ni rabajigan ni awọn aṣaju ẹṣin mẹta, …

Ka si »

Ìjọba àpapọ̀ sèlérí fáwọn tó farapa níbi ìsẹ̀lẹ̀ ìtẹra ẹni pa tó wáyé ni’badan, l’Abuja ati Anambra.

Wọ̀nyí ni ìlèrí tí ìjọba ṣe fún ẹbí àwọn tí wọ́n tẹ̀ pa nibí tí wọ́n ti fẹ́ gba oúnjẹ ọ̀fẹ́ n’Ibadan, ilu Abuja àti nipinlẹ Anambra. Igbakeji aarẹ orilẹede wa Naijiria, Kashim Shettima ti fọkan awọn araalu t’ọrọ kan niti isẹlẹ atẹpa to wa kaakiri orileede yi balẹ pe …

Ka si »

Ipò t’Oriyomi Hamzat níleewòsàn lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó sokùnfa ikú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé nibi ayẹyẹ ìparí ọdún nilu Ìbàdàn

Alasẹ ati oludari Ileesẹ redio igbohunsafẹfẹ Agidigbo FM nilu Ibadan, Oriyomi Hamzat d’ero ileewosan lasiko tó dákú lẹyìn iṣẹlẹ aburu to se bẹ mú ọpọ àwọn ọmọdé lọ nigba ti awọn miiran sí tun farapa. Gẹgẹ bí ẹnìkan to ba awọn oniroyin sọrọ se wí, ipo ailera Hamzat ko sẹyìn …

Ka si »

Iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo kọ lo sàgbékalẹ̀ ètò ayẹyẹ ìparí ọdún fawọn ọmọdé, níbi tí ọ̀pọ̀ ọmọ ti sọ ẹ̀mí wọn nù.

Igbimọ alaṣẹ ileeṣẹ igbohun safẹfẹ redio Agidigbo FM niluu Ibadan ti sọ pe ileeṣẹ redio naa kọ lo ṣagbekalẹ tabi sagbatẹru eto apejẹ to waye lọgba ile-ẹkọ Islamic High School, to wa ni agbegbe Bashorun, nibi ti ọpọ awọn ọmọde ti pàdánù ẹmi wọn. Ọjọru Wednesday, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila …

Ka si »

Gómínà Adeleke sètò ìtúsílẹ̀ ọ̀dọ́mọ̀kùnrin tí wọ́n dájọ́ ikú fún torí pé ó jí adìyẹ gbe nipinlẹ Ọsun

Gomina ipinlẹ Osun, Sẹnitọ Ademola Adeleke ti kede pe ki wọn bẹrẹ igbesẹ lati ṣe iwadii kikun nipa ọdọmọdekunrin kan, Segun Olowookere ti wọn dajọ iku fun lọdun mẹwaa sẹyin. Adeleke ni oun yoo rii daju pe idajọ ododo waye lori ẹjọ naa, ati pe ẹsun ti wọn fi kan …

Ka si »

Ìkórajọpọ s’ẹ̀yẹ ọdún kérésì, ayẹyẹ ìparí ọdún fáwọn èwe yọrí s’íkú ọ̀pọ̀ ọmọdé n’Íbàdàn.

Iṣẹlẹ aburu ọhun lo waye nilu Ibadan, tiise Oluilu ipinlẹ Ọyọ l’ọjọru Wednesday, ọjọ kejidinlogun, osu kejila nibi eto ayẹyẹ opin ọdún awọn ọmọdé ìyẹn Children’s Carnival ti awọn ajọ kan sagbatẹru rẹ. Gẹgẹ bí iroyin naa tí a gbọ, isare girigiri, iwariri awọn ọgọrọ eeyan lo sokunfa iṣẹlẹ laabi …

Ka si »

Ademọla Lookman d’ọmọ tí wọ́n nsọ pẹ̀lu b’óse gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jù lọ nílẹ Adulawọ f’ọdun 2024.

Agbabọọlu fun orileede wa Naijiria ati ilẹ Atalanta ni Italy, Ademola Lookman lo ti gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi agbabọọlu to dara julọ nilẹ adulawọ Africa f’ọdun 2024. Lookman ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun lo fi ẹyin awọn alatako rẹ lati Cote d’Ivoire, Brighton, Hove Albion, Simon Adingra, Serhou Guirassy lati …

Ka si »