Ọkọ ati iyawo rẹ ọhun ni irọlẹ Ọjọbọ Thursday ni ori ko yọ lọwọ iku ojiji lasiko ti Container ile alasopọ mọ ọkọ nla trailer deede subu lu ọkọ wọn ti number idanimọ rẹ jẹ Nasarawa JZ 101 ZA loju ọna Ogbomọsọ High School.
Gẹgẹ bi iroyin naa ti a gbọ ijamba naa sẹlẹ lẹyin isẹju perete ti ọkọ ati iyawo rẹ ọhun sọkalẹ ninu ọkọ lati ya ra awọn nkan loju ọna naa.
Nse ni ọpọ awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn nba arakunrin ati arabinrin ti wọn jẹ tọkọ’taya naa yin Ọlọrun logo.