Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"transform":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Àlàyé ikú ti ó pa Sunday Babatunde, elégún Danafojura, l’Ogbomọṣọ.

Awọn ẹbi oloogbe naa fidi iku ẹni wọn mulẹ pe l’ọgba ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Bowen, BUTH, niluu Ogbomoso, nipinlẹ Ọyọ ni Sunday Babatunde dakẹ si.

Awọn ẹbi Babatunde sọ fawọn oniroyin pe lọjọ Abamẹta Satiide to kọja yi ni oloogbe naa deedee yọ ṣubu lasiko to n wẹ lọwọ ni baluwẹ.

Lati ibẹ ni wọn si ti gbe e digba digba lọ sọgba ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Bowen niluu Ogbomoso nibi ti wọn ti bẹrẹ si ni tọju rẹ.

Amọ, gẹgẹ bi ẹbi rẹ se ṣalaye, ọjọ Aje Mọnde ni Babatunde dagbere faye nile iwosan naa.

L’ọjọ Aje Monday, ọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla ọdun yii ni Oloye Sunday Babatunde ẹni to n gbe gbajugbaja eegun Danafojura ti ọpọ eeyan mọ si eegun onina niluu Ogbomoso.

Gẹgẹ bi iroyin naa ti a gbọ, Babatunde dagbere faye lẹni ọdun mẹrindinlaadọta 46.

Ọpọ awọn eeyan lo n ṣedaro oloogbe naa lati igba ti iroyin iku rẹ lù jade sigboro.

Diẹ lara ohun ti awọn eeyan sọ nipa ologbe naa ni pe o di ẹni to n ru ẹku eegun Danafojura ni nnkan bi ọdun meloo sẹyin lẹyin ti Ifa mu un pe oun ni yoo maa gbe eegun naa jade lọdọọdun.

Adari ijọ ni ologbe Sunday Babatunde ni ṣọọṣi kan ti o jẹ oludasilẹ rẹ ki o to di ẹni to n gbe egungun Danafojura.

Bakan naa ologbe Babatunde lo ni ile ọti kan ti orukọ rẹ n jẹ Oburẹkẹ niluu Ogbomoso nigba aye rẹ.

Ṣaaju, ninu ọdun 2024 yii ni a gbọ wi pe oloogbe naa ṣe oku iya rẹ ni agboole Alakasu ti i se agboole wọn niluu Ogbomoso.

Egungun Danafojura ti ologbe naa n gbe jẹ Eegun nla to ma n fi ina wẹ ara rẹ.

Oniruuru eegun lo wa nilẹ Yoruba, ọtọ leegun ọlọrẹ, bakan naa ni a ni eegun alare amọ eegun danafojura yi eegun onina ni ti awọn eeyan mọ si.

Eegun to ṣeni ni kayeefi ni eegun Danafojura yi jẹ, pataki lara nnkan kayeefi to n bẹ lara rẹ ni pe inu ina lo ti n ma fẹla, to ti ma n jo.

Eegun yii fẹran ina pupọ, eyi lo si fun lorukọ ti awọn eeyan npe ni Danafojura.

Agboole Alakasu niluu Ogbomoso ti i se agboole ologbe yi ni eegun Danafojura fi se ibuba.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ìmáàmù Agba Ogbomoso tu ba o, o rawọ-ẹbẹ sí Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi, pe ko má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ t’oun bá ṣẹ̀

Lẹyin ọpọ awuyewuye, gbonmisi-omi-o-t o ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *