Awọn eeyan ọmọ ile ọba niluu Osogbo ti pariwo síta pe ki araalu o gba wọn lọwọ Ọba Jimoh Olanipekun Ataoja ilu Osogbo, lori ẹsun pe o n fi awọn ti kii ṣe ọmọ ilu naa jẹ oye.
Eyi jẹyọ nibi eto ìwọ́de ifehonuhan kan ti awọn eniyan naa ṣe lọjọ kọkandinlogun, osu Kọkanla, ọdun 2024 yi, niluu Osogbo, Olúìlú ipinlẹ Ọsun.
Wọn ni ki Ọba Olanipekun da wọ iwa ibajẹ ati iwa aijọniloju naa duro.
Awọn eniyan ọhun to wa lati awọn idile to ma n jẹ ọba niluu Osogbo fẹsun kan kabiyesi pe oun wuwa ko si ẹni to le mu mi, lati ma fi awọn ti kii ṣe ọmọ ilu ati awọn ti kii se ọmọ oye jẹ ọba ati oye miran lai fi to awọn leti rara.
Ẹnikan lara awọn eeyan naa, Ọmọọba Agboola Adejobi to jẹ arole oluawo, sọ fun awọn akọroyin pe awọn ko ni laju awọn silẹ ki Ọba Jimoh Olanipekun, ba ilu Osogbo jẹ patapata pẹlu iwa ibajẹ ti o n wu kaakiri lati ma fi alejo jọba lori onile.
Ọgbẹni Adejọbi tun tẹsiwaju wi pe, gbogbo owo n to wọ aafin Ataoja lati ọwọ ijọba ati lati oke okun fun atunṣe ilu ati aafin, ni kabiyesi da si apo ara rẹ ti ko sí lo bo se tọ àti bó ṣe yẹ.
Ọmọ ọba Abdullatifu Akinyemi ni oun ti awọn fẹ ni ki ọba Jimoh Olanipekun fi ipo Ọba silẹ fun ẹni ti yoo tun iluu Osogbo ṣe, tabi ko dawọ iwa ibajẹ naa
duro.
Akinyemi tun fi kun ọrọ wi pe, ọba naa ko tọ si ipo ọba saaju koun pẹlu naa o to jọba.
O ni Ọba Jimoh Olanipekun dojuti gbogbo ọmọ bibi ilu Osogbo nipa iwa buruku to n wu lawujọ lati maa fi ori ade sagbe kaakiri.
Ọgbẹni Bello Wasiu to jẹ akọwe fun Ọba Jimoh Olanipekun sọ pe, awọn ọlọtẹ, ti ko fẹ isejọba kabiyesi, lo wa nidii iwọde naa.
O ni lootọ ni awọn gbọ ẹsun naa, ṣugbọn awọn ti ọrọ kan ti jawe olubori nile ẹjọ.
Ọgbẹni Bello sọ pe irọ patapata ni, pe kabiesi n fi awọn ti kii ṣe ọmọ ilu Osogbo joye tabi fi wọn jọba awọn ilu keekeeke to wa labẹ Osogbo, lẹyin to ba ti gba owo lọwọ wọn.
Aafin Ọba ni, irọ to jinna sootọ ni ẹsun naa ti awọn araalu fi kan ọba.