Ọpọ àwọn oloolufẹ lo ti wọn fẹ gbajumọ osere naa lo ti n ṣedaro Dokita Moses Korede Arẹ ẹni ti ọpọ èèyàn mọ si Baba Gbenro to doloogbe lana Ọjọbọ Thursday, ọjọ kẹrinla oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii.
Iyalẹnu nla ni iku gbajumọ osere kristiẹni ọhun Baba Gbenro jẹ fun ọpọ awọn eeyan, papajulọ awọn Oloolufẹ sinimọ alagbelewo ti awọn onigbagbọ, Kristian Movie nigba ti iroyin iku gbajumọ osere naa lù gbooro kan.
Ọpọ àwọn Oloolufẹ ere sinima Kristẹni naa ni wọn fẹràn eyikeyi ipa ti iransẹ ọlọrun naa ologbe Korede Are ba kopa ninu sinimọ, to fi mọ Baba Gbenro ti wọn n pe, ninu sinimọ Abattior awọn miiran gan a ma f’ọrọ baba Gbenro sawada laarin ara wọn pe (Daaddy, Mummy) ati bẹẹ lọ.
Amọ, ohun ti ọpọ awọn eeyan n beere ni pe ki lo ṣokunfa iku Baba Gbenro gan an pẹlu bi ọpọ ko ti gbọ nipa aisan to n ba finra saaju iku rẹ.
L’ọgba ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti LAUTECH niluu Ogbomoso iyẹn Lautech Teaching Hospital ni Baba Gbenro dakẹ si ni owurọ Ọjọbọ tọside.
Ajinhinrere Niyi Adebayo ti o jẹ Olùdásílẹ̀ ile-ijọsin True Worshippers Church niluu Ogbomoso wa lara awọn eeyan to wa nile iwosan pẹlu awọn iransẹ Ọlọrun miran ti o fi mọ awọn gbajumọ osere ni wọn jọ wa nile iwosan naa saaju iku Baba Gbenro.
Alufaa Adebayo ni awọn dokita lo fidi rẹ mulẹ pe arun inu ẹdọ ti oloyinbo n pe ni liver cirrhosis lo ṣokunfa iku oloogbe naa.
Iransẹ Ọlọrun naa ṣalaye wi pe awọn to n tọju rẹ nile iwosan naa sọ pe arun jẹjẹrẹ ti wọ inu ẹdọ rẹ.
‘’Ni nnkan bii ago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹdogun laarọ Ọjọ́bọ̀ ni agba oserekunrin Kristẹni naa korede Are jade laye.
Arun inu ẹdọ eyi ti wọn npe ni Jẹjẹrẹ lo n ba a finra fun igba pipẹ ti o si ti saaju lọ fun itọju nile iwosan kan niluu Eko.
Lẹyin naa ni wọn tun gbe Ọgbẹni Are to jẹ dokita nipa itọju ẹranko lọ si fasiti ẹkọṣẹ iṣegun UNILORIN ki wọn to gbe e wa si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun LAUTECH nibi ti o pada ku si,’’.
Ojiṣẹ Ọlọrun Adebayọ fikun ọrọ rẹ pe awọn n gbero lati gbe Baba Gbenro lọ si orileede India tabi Dubai fun itọju ṣugbọn awọn dokita sọ pe ko si nnkan ti wọn le ṣe si tori arun jẹjẹrẹ naa ti wọ inu ẹdọ rẹ.
O ni ọrọ ti oloogbe naa sọ gbẹyin ni pe ‘’Ọlọrun si maa jẹ Ọlọrun, ohunkohun to wu ko ṣẹlẹ.
Alufaa Adebayo sọ pe lẹyin naa lo ni ‘’buọda Niyi mo fẹ sinmi,’’ o ni ko ju iṣẹju marun un lọ sigba naa lo mi kanlẹ ti o si dagbere faye.