O ma se o, Fọnran fídíò kan to jade loju opo itakun ayelujara Instagram lo ti ṣafihan bi gbajumọ oṣerebinrin onitiata nní, Ramota Adetu, ti ọpọ èèyàn mọ si Aunty Ramota ṣe n pe fun iranlọwọ àwọn eeyan ọmọ Naijiria pe oun ko ni ile lori mọ.
Ninu fọnran fídíò ọhun to jade loju opo Agiye Amira lori itakun ayelujara Instagram ni Aunty Ramota ti sọrọ sita, fẹsun kan ẹni ti o n ṣe alamojuto rẹ pe o lu oun ni jibiti owo.
Bakan naa ni Aunty Ramota ni awọn to n ṣe akoso oun ti bẹgidina ikanni Tiktok oun.
O ni “Bi oun ṣe wa yii, oun ko ni ile lori mọ Obinrin ti oun gbe pẹlu rẹ, ṣe igbeyawo loṣu to kọja, to si ni ki oun kuro ni ile oun nitori ọkọ rẹ̀ ko fẹ ki awọn o gbe pọ.
O ni, pẹlu gbogbo igbiyanju oun ti oun ṣisẹ karakara wọn pada ji oun lowo nitori oun ko mọ iye owo ti oun n pa wọle.
Wayi ọgbẹni Ganiyu Kehinde, ẹni ti ọpọ mọ si Ijọba Lande ti wa jẹ ko di mimọ pe kosi nnkan to jọ mọ pe Aunty Ramota ko ni ile lori mọ, o ni lootọ ni pe awọn to n ṣe alamojuto rẹ kọ lati fun ni owo.
Bakan naa lo sọ pe lootọ ni pe ibi ti Aunty Ramota wa tẹlẹ, ẹni naa tisegbeyawo ti o si ni ki wọn wa mu Aunty Ramota kuro ni ọdọ rẹ, to si jẹ pe ọdọ awọn mọlẹbi rẹ lo wa bayi.
Ijọba Lande sọ pe bi oun se gbọ ọrọ naa, inu oun ko dun si, o ni oun mọ bi Ramota ṣe n sisẹ to, oun si mọ iye owo to n pa wọle.
O wa ni pẹlu bi o ṣe n sisẹ to yi o yẹ ki wọn le gba ile oni yara meji fun un, o ni ko i ti buru pupọ ko ba ti pari ile rẹ amọ o burukuju pe o n wọ awọsun kiri.
O ni ti oun ba bi Ramota pe ṣe o fẹ kuro lọdọ awọn mọlẹbi rẹ, o maa ni rara, ṣugbọn awọn ti n ṣisẹ lori ile rẹ.
Sussie Ratty, ẹni to ni a le pe oun ni mọlẹbi Aunty Ramota ni Ramota ko bere owo lọwọ ẹnikẹni ṣugbọn otitọ ni pe wọn lu ni jibiti owo.
O ni alaafia ni Aunty Ramota wa, to n si n gbe pẹlu ayọ pẹlu mọlẹbi rẹ
Ṣugbọn o ṣe ni laanu pe wọn ṣe owo rẹ baṣubaṣu bi ko ti ye̱, ti wọn si fẹ sọ si kolobo.