Gbajugbaja were olorin takasufe nni, Habib Okikiola, ti ọpọ eeyan mọ si Portable ni ori ti ko yọ lọwọ awọn eeyan kan ti wọn furasi pe wọn fẹ gba ẹmi lẹnu rẹ.
Ninu fọnran fidio kan to lu sita lori ayelujara laipẹ yi ni ọkunrin kan ti ọwọ tẹ pẹlu sisaapa lati se ijamba fun Portable ni agbegbe Ota nipinlẹ Ogun.
Nse ni ibẹruboju han loju Portable, ninu fọnran fidio kan to ti n pariwo pe awọn eeyan kan fẹ gba ẹmi oun laisẹ, lairo.
Ọpọ awọn eeyan lo pe le ọkunrin naa ti ọwọ tẹ toun tibọn lọwọ ti wọn lo fẹ se Portable ni ijamba ni agbegbe Ọta
Gẹgẹ bii iroyin naa ti a gbọ awọn eeyan kan ni wọn sekọlu si Portable lasiko to n lọ si ọfisi rẹ, ti o si jọla awọn eeyan ti wọn wa ni adugbo rẹ, ti wọn yọ ninu ewu naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ni oṣu kẹjọ ọdun yii ni Portable fi ẹsun kan awọn kan to pe ni ẹgbọn adugbo pe wọn n dunkooko mọ oun.
Ninu fọnran fidio ti gbajumọ were olorin naa ti wọn n pe ni Idaamu Adugbo naa gbe jade lori itakun ayelujara o sọ pe ibi toun ti lọ kọrin lagbegbe Iju-Ishaga nipinlẹ Eko ni awọn eeyan naa ti wa da ibẹ ru ti wọn si sekọlu s’oun
O ni ọrẹ oun kan to n ta mọto loun lọ ba ṣe ayẹyẹ, toun si tun kọrin nibẹ pẹlu, ko to di pe awọn to pe lẹgbọn adugbo naa sekọlu wa dagboru ti wọn si sekọlu si.
Portable ni niṣe lọrọ di ẹni ori yọ, o di ile, toun si sa asala fun ẹmi ara oun, ṣugbọn to loun ko tii ri awọn ọmọ ẹyin oun yooku gẹgẹ bi o ti sọ nigba naa.
Bakan naa lo sọ pe kii ṣe pe awọn ‘Ẹgbọn Adugbo’ naa lu awọn nikan, bi ko ṣe pe wọn tun ja ẹgba ọrun ati awọn dukia miran to jẹ olowo iyebiye gba lọwọ oun.
Akọlu ti gbayẹn ati eyi ti wọn tun se yi lo dabi ẹni pe o tun lọwọ awọn eeyan ọhun ti Portable pariwo wọn pe wọn ni ẹgbọn adugbo ninu.
Kin ni ohun ti Portable se f’awọn ẹgbọn adugbo naa ti wọn fi n wa ẹmi rẹ ni ibeere ti ọpọ eeyan nbeere ti Portable fun ra rẹ naa si n pariwo rẹ pe kinni mo se fun.