Kọmiṣọna feto idajọ nipinlẹ Eko, Lawal Pedro, SAN, ti ṣeleri rẹ pe igbẹjọ iku gbajugbaja olorin takasufe nni Ilerioluwa Alọba ti ọpọ mọ si ‘Mohbad’ yoo bẹrẹ laipẹ lati fi oju gbogbo awọn to lọwọ ninu iku rẹ lede.
Pedro lo sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aje Monday lori eredi ti igbẹjọ naa ṣe falẹ lati bi ọdun kan le sẹyin.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni igbẹjọ naa pe to bẹẹ latari oniruru iwadii ti awọn agbofinro n ṣe.
O ni “atupalẹ ‘forensic ati toxicology’ wa lara awọn iwadii naa, eyii ti yoo jẹ gbankọgbi ẹri niwaju ile ẹjọ.”
Agbẹjọro agba naa sọ siwaju si pe ilẹ Amẹrika ni wọn ti ṣe awọn iwadii ijinlẹ ọhun nitori awọn kọlọrọsi to dana sun ibi ti wọn ti le ṣe niluu Eko, iyẹn Lagos DNA and Forensic Centre, lasiko iwọde EndSARS ọdun 2020.
O ni eredi ree ti awọn fi lọ sẹ awọn ayẹwo naa nilẹ Amẹrika niyẹn.
Pedro wa fidi rẹ mulẹ pe esi awọn ayẹwo naa ti de siluu Eko bayii lati ilẹ Amẹrika fun igbẹjọ.
O wa sọ siwaju si pe awọn mọlẹbi oloogbe lo n da igbẹjọ naa duro bayo latari pe wọn ni awọn fẹ ṣe ayẹwo oku rẹ funra awọn.
Gẹgẹ bi o ti wo o ni awọn mọlẹbi Mohbad lo n da awọn duro bayii lẹyin ti wọn ni awọn naa fẹ se ayẹwo tiwọn.
Amọ sibẹ sibẹ, igbẹjọ naa yoo bẹrẹ laipẹ, idajọ ododo yoo si waye lẹyin igbẹjọ