Irọ́ ikú ni wọn npa o, Lagbaja ò kú, ó lọ fún ìsinmi lẹ́nu ìṣẹ̀ ni-Iléeṣẹ ológun kede bẹ

Ileeṣẹ ologun nilẹwa Naijiria ti wọgile iroyin ẹlẹjẹ kan to ni Ọga agba ologun lorilẹede Naijiria, Taoreed Lagbaja ti jade laye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Onyema Nwachukwu fi ohun naa lede taki iroyin ẹlẹjẹ ti awọn kan ngbe kiri pe ọgagun naa ku, o ni Lagbaja lọ fun isinmi lẹyin iṣẹ, ti gbogbo eto si ti to lati jẹ ki Ọgagun Abdulsalami Ibrahim ma sisẹ lọ gẹgẹ bii adele Ọga ologun.

Nwachukwu ni aisi ni ile Lagbaja lọwọ ko da iṣẹ ologun duro rara, isẹ si n lọ bi o se tọ ati bi o se yẹ.

Saaju ni iroyin kan jade pe Ọga agba ileeṣẹ ologun naa, Lt. Gen Taoreed Lagbaja ti jade laye ni ile iwosan lẹyin to ni asian jẹjẹrẹ.

Ọpọ iroyin ẹlẹjẹ naa lo n lọ kaakiri pe ko si olori mọ ni ileeṣẹ ologun, ti o si n ya ọpọ lẹnu.

Iroyin mi ti o ti ẹnu alukoro ileesẹ ologun jade yi lo wa jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan to jọ bẹ, o ni irọ to jina si otitọ ni iroyin naa ti wọn ngbe kiri pe Lagbaja ku.

Ileeṣẹ ologun ni ilana ti awọn fi n sisẹ lasiko ti nnkan ba waye, ki Lagbaja o to gba isinmi, gbogbo eto naa lo wa fun Ọga ologun Abdulsalami Bugudu Ibrahim lati ma sisẹ le lori titi t Ọgagun Lagbaja yoo fi pada de lati isinmi ti o lọ

O ni ọpọ igba ni ọgagun ti ma n lọ sinmi, ti ọga ologun naa si ni lati lo oṣu mẹta, ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ yoo si maa sisẹ bi adele fun un titi yoo fi pada.

Agbẹnusọ ileesẹ ologun naa ni gbogbo awọn ẹka ileeṣẹ ologun ni wọn tẹsiwaju lẹnu iṣẹ wọn, ti ko si si idaduro kankan nibi kibi.

O wa rọ awọn araalu lati yago fun awọn iroyin ẹlẹjẹ bayii, to si tun jẹ ko di mimọ pe alaafia orilẹede Naijiria lo jẹ ileeṣẹ ologun logun pupọ.

 

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Olorì Damilọla dákú lóbá dèro ilé ìwòsàn látàri bí Portable tún se b’ọ́nà mi yọ si

Awuyewuye wahala mii tun ti suyọ lori itakun ayelujara laarin gbajumọ akọrin takansufe nni, Habeeb …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *