Araba miran tun ti wo lawujọ awọn osere tiata Yoruba nilẹwa Naijiria Alhaji Ayọbami Mudasir Olabiyi ti gbogbo aye mọ si Bobo B ti jade laye.
Ti a ba n sọ nipa awujọ awọn gbajumọ osere tiata eekan ni Alhaji Mudasir Olabiyi Bobo B.
Iroyin iku gbajumọ osere naa lo di tọrọ n fọnkale lori itakun ayelujara loni ọjọru wednesday, nise ni wọn npin iroyin ati aworan gbajumọ osere naa.
Gbajumọ agba òṣèré náà jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ to ti n ba finra
Nígbà tó ń fìdí iroyin ikú agba osere náà múlẹ̀ fún awọn oniroyin Toyin Adegbola ṣàlàyé pé láti bíi oṣù méjì sẹ́yìn ni Bobo B ti ń ṣe àárẹ̀ tó sì wà ní ilé ìwòsàn.
O ni lati bi oṣù méjì sẹ́yìn ni Bobo B ti kọ́kọ́ wà ní ilé ìwòsàn University College Hospital, iyẹn ile iwosan UCH, Ibadan kí wọ́n tó gbé kúrò níbẹ̀ nígbà tí ara rẹ̀ kò balẹ̀ tó.
Ẹ̀ka àwọn tí àárẹ̀ wọn bá le púpọ̀, ICU ni Bobo B kọ́kọ́ wà kó tó di pé wọ́n gbe kúrò níbẹ̀.”
Ó sọ pé lẹ́yìn tí wọn kò rí ìyàtọ̀ lára rẹ̀ ni wọ́n gbe lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn tó wà ní agbègbè Amuloko ní ìlú Ibadan fun itọju bákan náà.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ ni òṣèré náà gbà lasiko ígbà tó fi wà nile iwosan UCH àti pé àgbà òṣèré náà ní wọn lo ni ìtọ̀ ṣúgà tí kò tètè mọ̀ afi igba tó ti wọ̀ ọ́ lára.
Ó ṣàlàyé pé wọ́n ti sin òkú rẹ̀ sí ilé rẹ̀ tó wà ní ìlú Ibadan ní ìlànà ẹ̀sìn Islam loni ọjọru Wednesday
Àtẹ̀jáde tí gómìnà ẹgbẹ́ àwọn òṣèré tíátà ní ìpínlẹ̀ Oyo, Bose Akinola fi léde náà fìdí ikú agba òṣèré náà múlẹ̀ pe o ti jade laye
Akinola wa gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ Bobo B sáfẹ́fẹ́ rere, kó sì rọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ lójú.
Ṣáájú ikú Bobo B, òun ni àkọwé apapọ fun ẹgbẹ́ osere TAMPAN ní ìpínlẹ̀ Oyo.