Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Saidi Balogun, ti ṣapejuwe ọmọbinrin rẹ, Zeenat Balogun to ku laipẹ yii gẹgẹ bii akọni eeyan.
Balogun sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku Sunday.
Ni owurọ ọjọ Ẹti Friday, ọjọ karun un, oṣu Kẹwaa yii ni ilumọọka oṣere naa kede iku ọmọbinrin rẹ ninu atẹjade to fi lede loju opo Instagram rẹ.
Ninu atẹjade ti o fi lede loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku Sunday lorukọ idile Balogun ni o ti ki gbogbo awọn ọrẹ, awọn akẹgbẹ rẹ ati gbogbo eeyan to ba kẹdun pẹlu idile rẹ lasiko ti ọmọbinrin rẹ naa jade laye.
Saheed Balogun wa ṣapejuwe ọmọbinrin rẹ ọhun gẹgẹ bi obinrin ogun to gbe igbe aye rẹ daadaa ti o si maa n kun fun ayọ nigbogbo igba.
O ni Zeenat jẹ ẹnikan ti kii gbagbọ wi pe oun le ni ijakulẹ ninu ohun kohun to ba n ṣe.
O ni o jẹ ọmọ kan to maa n kun fun ireti nigba gbogbo, o ni ọmọ naa gbọn afi bi obinrin to ti wa nile ọkọ ni.
Gbogbo eeyan ti Zeenat ba ni ibaṣepọ pẹlu ni o fi ifẹ han si nigba aye rẹ.
Awọn nkan wọnyii si ni awọn o fi ma ṣe iranti rẹ lẹyin ti o ti fi aye silẹ lọ bayi.
Saheed Balogun ninu ọrọ rẹ sọ wipe Ọjọ meji to ṣe pataki julọ laye ni ọjọ ti a bi ni saye ati ọjọ ti a ba ku.
Ṣugbọn ohun ti o ṣe pataki ni pe ki a gbe ile aye ṣe rere, wọn ni Zeenat maa n gbiyanju lati ṣe ohun to dara ni gbogbo igba fun ẹbi atawọn eeyan rẹ, eyi ni ọrọ ti ẹbi Balogun lo sọ ninu atẹjade ti Saidi fi lede loju opo Instgram.
Saidi sọ ninu atẹjade naa pe ọmọbinrin oun to doloogbe yi maa n sọ foun lọpọ igba wi pe ‘’ko dẹ wa ri bẹẹ oo, baba mi, mo maa yipada, o ni ko si nnkan toun le yipada ninu iwa ọmọ oun to doloogbe naa afi ti o ba fun rarẹ yipada.
O ni orukọ ọmọ naa maa n ro o ni gbogbo igba, tori o jẹ onirẹlẹ, olododo, o si tun ni omi aanu loju.
Ilumọọka oṣere naa sọ wi pe, Eledumare lo n fun ni lọmọ, oun naa si lo n gba a, nitori naa oun gba fun Eledumare
O wa gba ladura pe ki Ọlọrun tẹ ọmọ naa si afẹfẹ rere.