Iroyin pajawiri

Wọ́n fìyà ẹ̀sẹ̀ àìmọ̀dí jẹ ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan dójú àmì

Gẹgẹ bí iroyin ọhun ti a gbọ, awọn oṣiṣẹ at’awọn ẹsọ eleto-ààbò ṣọọṣi ọhun ti wọn ja lole ni wọn ti kọkọ lu ọmọdekunrin alaiṣẹ ọmọ ọdún mẹrinla ọhun lalubole-alubami ko to dipe Ojúlówó Ole gbewiri to se bẹ ji owo gbe ni sọọsi jẹwọ.

Ọmọdekunrin, ọmọ ọdún méjìlá ọhun lo jẹwọ iwa ọdaràn to wu lẹyìn ọsẹ diẹ ti wọn ti lù ọmọdekunrin alaiṣẹ ọmọ ọdún mẹrinla ti wọn tiran mọ lalubole-alubami.

Ọmọdekunrin alaiṣẹ ọhun, ọmọ ọdún mẹrinla, Aondoakaa Yarkwan, sọ ohun tójú rẹ rí lakoko ti wọn ka ẹsun owo jiji mọ lọrùn, o sọ ohun tó dojukọ- to farada nigba ti wọn n fiyajẹ lori ẹsẹ aimọdi ti ko mọwọ mọ ẹsẹ.

Ọmọdekunrin alaiṣẹ naa ni wọn kọkọ fẹsun kan pe o jale owo toto igba lọnà ẹgbẹrun naira N200,000 ninu owo ti wọn n dajọ nile-ijọsin St. Joseph Parish, Korinya, nipinlẹ Benue.

Gẹgẹ bí iroyin se gbe jade si wa leti, Ile-ijọsin naa ṣàgbékalẹ̀ eto isin-idupẹ lọjọ kẹjọ, osu kẹsan, ọdún 2024, nibi ti awọn eeyan ijọ naa si ti dawo toto igba lọnà ẹgbẹrun naira N200,000 naira fún ìdàgbàsókè ile-ijọsin.

Yarkwan ẹni tí wọn fi owo ti wọn dajọ naa sọ, ti owo naa wa ni ikawọ rẹ, ni wọn foju si lara dalẹbi nigba ti owo naa dawati ati bi wọn ṣe se pasiparọ owo naa si pepa.

Yarkwan ni, wọn mu oun lọ ọdọ Alufa ile-ijọsin naa, Ẹni-ọwọ Emmanuel Doki, nibi ti won ti f’ọrọ wa oun lẹnu wò, o ni, nigba t’oun salaye ohun to sẹlẹ, Alufa naa bù ifọju lù oun lẹmẹta, pe k’oun jẹwọ.

Gẹgẹ bí oṣiṣẹ ile-ijọsin naa se wí, Yarkwan gba pe òun mu ẹgbẹrun mẹta naira sugbon to ni oun ko mọ bi owo yòókù ṣe dawati.

Yarkwan ṣàpèjúwe bi Alaga Ile-ijọsin naa, Ọgbẹni Tartsegha, Catechist Kumbur, ati diakoni Agbero se fi koboko lù oun lalubole alubami ti wọn sì fa oun le ọwọ awọn ẹṣọ-alaabo ibilẹ.

O ni, wọn mu oun wọ inú igbó lọ ní korinya, nibi ti wọn n pe ni Golgotha, nibi ti wọn ti n saba ma dana sun awọn ole-gbewiri laaye.

O ni nse loun dakunlọ gbọnrangandan latari ijiya-ilukulu ti wọn lu oun nibẹ, o ni ìya oun lo súré gbe oun digba-digba lọ ọgba ileewosan nibẹ loun si yaju si.

Iya ọmọ naa, Benedicta Yarkwan kọminu, O ni, inu ìrora ni ọmọ oun wa, ko sì sí ẹnikan lati ile-ijọsin to wa tọrọ-aforijin tabi seranwọ lati ran àwọn lọwọ lori sisan owo ileewosan ti ọmọ oun ti n gba itọju.

Lẹyìn ọsẹ diẹ ti iṣẹlẹ naa waye ti lu Yarkwan nilukulu fiya ẹsẹ ti o mọ di jẹ ni Ọmọdekunrin ọmọ ọdún méjìlá to jẹwọ pe, oun loun ji owo naa.

Ẹgbẹrun mẹwa pere ni wọn sì rí gba pada lọwọ rẹ, botilejepe asiri ẹni tó jí owó tí tu sita, sibẹ ile-ijọsin tun kọ jalẹ pe ki Ẹbí Yarkwan ọmọdekunrin alaiṣẹ ọmọ ọdún mẹrinla yi o san ẹgbẹrun lọnà ọgọrin naira ti o ku latari pe oun ni wọn fi owo ile ijọsin naa sọ.

Latari iṣẹlẹ yi awọn eeyan ilu ti dide sọrọ náà, wọn sì ti pé fún ìdájọ ododo fún Yarkwan ati ẹbi rẹ.

Wọn ti pé fún Iwaadi-ifinmufinle nipa fifiyajẹ ọmọ kékeré ọhun lọnà tó lodi sofin.

Nigba ti awọn Akọroyin kan sí Agbẹnusọ fún Ileesẹ Ọlọpa nipinlẹ Benue, Anene Sewuese lati tan imọlẹ sọrọ naa, boya Ileesẹ Ọlọpa gbọ sí ọrọ ọhun tabi wọn ko gbọ sí, ati kinni igbesẹ ti wọn gbe lori rẹ, Alukoro fún Ileesẹ Ọlọpa ni awọn ko gbọ nkankan nipa iṣẹlẹ naa.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fòntẹ̀ lù ìdájọ́ ikú oloye Ramon Adedoyin latari po lọwọ nínú ikú tó pa Akẹkọọ OAU Timothy Adegoke.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti o fi di kalẹ niluu Akurẹ ti buwọ́lù idajọ iku fun …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *