Laipẹ yii ni ẹnu bẹrẹ si kun ilumọnka Alfa ẹsin Islam kan, Al Sheik Hamad Labeeb L’Agbaji, ti ọpọ mọ si Sheik Lagbaji.
Eyi ko ṣẹyin fọnran fidio kan to jade sori itakun ayelujara, to ṣafihan bi olori ẹlẹsin Islam naa ṣe wa lori itage kan naa pẹlu gbajugbaja alufa ijọ Genesis, Wooli Oladele Ogundipe ti ọpọ mọ si Genesis.
Ninu fónrán fidio naa lati ri Sheik Lagbaji ati Wooli Gensis ti wọn jọ n jo loju agbo tẹrin-tọyaya- tayọ tidunnu.
Bakan naa la ri to da bi ẹni pe Wooli Genesis fi nnkankan si apo Alfa naa.
Ọpọ awọn to n sọrọ nipa fọnran fidio naa lori ayelujara lo gbagbọ pe ko lẹtọọ fun Sheik naa lati wa ni ipejọpọ kan naa pẹlu ẹlẹsin mii.
Amọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu awọn Akọroyin lori awuyewuye naa Sheik L’agbaji sọ pe ọkan ṣoṣo ni Ọlọrun ọba, nitori naa ẹnikẹni o le reti pe ki oun ati Genesis pade ara, ki awọn si maa ya aṣọ mọ ara wọn lara.
O ni lara ibi ti agbọye ẹsin ti bẹrẹ ni ki eeyan fi ikorira si fun gbogbo ẹda ti Ọlọrun ba da.
O ni ẹni ti ko ba ni oye iru nnkan bẹẹ, yoo maa ṣe bii aja digbolugi pe oun ko fẹ ri ẹlẹsin kankan yatọ si ẹlẹsin rẹ
Nipa ti fọnran fidio naa to fa awuyewuye ọhun, Sheik Lagbaji ṣalaye pe kii ṣe ṣọọṣi Oluṣọagutan Genesis ni oun lọ.
O ni ode ariya kan to waye lasiko awẹ ni awọn ti pade.
Nigba ti awọn de ibẹ, Genesis lo n sọrọ lọwọ ti o si fi apọnle fun oun nigba to si kan oun naa oun naa pọnle pada.
O ni sẹ ẹni to pọn oun le, o wa a da ki oun kan an l’abuku bi
Sheik L’agbaji sọ pe wọn o kọ oun lẹkọọ lati ma a ta ọfa gbolohun si ẹni to pọn oun le lagbo.
Tako nnkan ti awọn eeyan n sọ pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun mejeeji jọ waasu papọ, tabi pe Alfa naa jọsin pẹlu awọn ẹlẹsin Kristiẹni, Sheik Lagbaji ṣalaye pe ọrọ ko ri bẹẹ o.
O ni ohun kan ti oun sọ ni pe “awọn ẹni Ọlọrun lo ma n ṣe bi Wooli Oladele Genesis ṣe ṣe.
O ni awọn ọrọ toun ba ti Genesis nsọ lo n mu awọn ranti ipilẹ, paapaa nipa asiko to gbe ninu igbe aye oṣi ati aini.
O ni lara awọn nnkan ti awọn eeyan tun ṣi oun gbọ le lori ni pe oun sọ pe Ọlọrun da awọn Kristiẹni mọ ninu Kuraani.
“Nnkan ti oun fẹ sọ ni pe Ọlọrun darukọ awọn Krsitiẹni ninu Kuraani.
‘Eyi to tumọ si pe awọn le jọ ṣe oriṣiriṣi nnkan papọ, yatọ si didarapọ mọ ẹsin wọn tabi jọ jọsin papọ.
O ni oun le lọ si ṣọọṣi lati waasu, nitori naa ẹnikẹni ko le sọ pe ki oun doju ija kọ Genesis.
Aigbọra ẹni ye nipa ọrọ ẹsin ko jẹ tuntun ni orilẹ-ede Naijiria leyi ti o si ti fa rogbodiyan, edeayede-gbọnmisiomioto ni aimọye igba, to si ṣaba maa n mu ẹmi ati biba dukia lọ.