Iroyin pajawiri

Saheed Òsùpá fún obinrin kan Àsàkẹ́ Alálùbọ́sà ní ẹ̀bùn owó tó jọjú nilu Ibadan

Obinrin oni elo ti Asakẹ Alalubọsa saaju ninu ifọrọwerọ kan to se eyi to gba ori itakun ayelujara kan, lo ti ṣalaye pe o wu oun ki oun na owo fun ilumọka olorin Fuji nni, Saheed Osupa sugbọn oun ko ti ni iru owo bẹ lọwọ .

Asake Alalubosa lo n kọrin Saheed Osupa ninu ifọrọwerọ naa to ṣe pẹlu Ayo Adam, gbajumọ akọroyin kan niluu Ibadan.

Ko pe ọṣẹ kan ti ifọrọwerọ naa jade sori itakun ayelujara ni iroyin naa de etigbọ Saheed Osupa, to si pinnu lati se abẹwọ si arabinrin ọhun ninu ọja Oje niluu Ibadan.

Ninu fọnran fidio kan to wa loju opo itakun ayelujara ni Saheed Osupa, ti lọ se abẹwo si obinrin naa Asake Alalubosa lati fi ẹmi more han si i bi o ṣe nifẹ si orin rẹ.

Osupa ni bi obinrin naa Asake Alalubosa ṣe fi ifẹ han si orin oun ati oun funra oun, gan an dun mọ oun ninu pupọ, lai si ani ani, o ni, awọn eeyan ti ma ri pe ololufẹ Osupa ni obinrin n se.

O ni “Awọn ọrọ to sọ ninu ifọrọwerọ naa pa oun lẹrin pupọ, paapa eyi to ni, ‘oun jẹ Saheed Osupa lowo, oun kini buruku yii ma na owo fun Saheed Osupa ti oun ba ni owo.

Saheed Osupa ni oun lọ si sọọbu rẹ ninu ọja Oje niluu Ibadan, oun ya lẹnu, nipa fifi ẹbun owo ta arabinrin naa lọrẹ

Obinrin naa Asake lo jẹ ọkan ninu awọn ọpọ eeyan to jẹ ololufẹ Olorin Fuji paapaa julọ orin Saheed Osupa ti o si loun ṣetan lati na gbogbo owo oun lati gbe oriyin fun orin gbajugbaja Olorin fuji naa bi oun ba foju ganni rẹ amọ fun iyalẹnu ni Osupa yọ gẹlẹ si nibi to ti n ta Alubọsa ti Osupa si fi ẹbun owo fun

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ìmáàmù Agba Ogbomoso tu ba o, o rawọ-ẹbẹ sí Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi, pe ko má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ t’oun bá ṣẹ̀

Lẹyin ọpọ awuyewuye, gbonmisi-omi-o-t o ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *