Olugbọn ti orile-igbọn Asaaju awọn awọn ori ade ọrun ilẹkẹ nijọba ibilẹ Suurulere nilu Ògbómọ̀ṣọ́, ipinlẹ Oyo, Ọba Francis Alao ti sọ gbángba-gbangba pe Awọn Ori-Ade ọrun-ilẹkẹ ko lagbara lori awọn Adari ẹṣin kankan nilẹ Yoruba ati bi gbogbo.
Ọba Alao sọ eyi di mímọ nínú atẹjade kan to gba jade fún àwọn oniroyin lọjọ Isẹgun Tuesday, atẹjade naa lo gba ori itakun ayelujara kan eyi ti awọn eeyan siti bẹrẹ si i sọ iha ti wọn kọsi ọrọ naa ti ori ade ọhun sọ.
Gẹgẹ bí o ti jẹyọ ninu atẹjade naa ti Kabiesi Ọba Olugbọn ti orileede igbọn gbe jade sita lẹyìn ọjọ diẹ ti Sọun tilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afọlábí Olaoye Orumogege lll yan Habib Ayilara gẹgẹ bí Imamu Aafin Sọun Ogbomoso.
Ti iyansipo ọhun sì da Awuyewuye silẹ káàkiri.
tonikaluku nsọ iha ti o kọ sí iyansipo Imaam aafin naa.
Iyansipo Imamu Aafin Ogbomoso yi ni awọn eeyan kan sọ pe o nise pẹlu aawọ to wa laarin Ọba Ghandi Afọlabi Sọun tilẹ Ogbomọsọ ati imamu agba ilẹ Ogbomoso, Sheik Teliat Yunus Ayilara.
Amọ ti atẹjade kan ti afin sọun jade yannana rẹ pe ojuse ọtọọtọ ni Imaam Aafin ati Imaam agba ilẹ Ogbomọsọ ni, Imaam aafin niise gẹgẹ bi olubadamọran, olugbọba nimọran lori ọrọ ti o jẹ mọ ẹsin musulumi ati dida irun fun awọn ẹlẹsin musulumi to n bẹ laafin niwọn igba ti Imaam agba ilẹ Ogbomọsọ ti fa sẹyin pe oun koni ajọsepọ kankan pẹlu aafin Sọun tilẹ Ogbọmọsọ.
Ọba Francis Alao Olugbọn ti orile igbọn ti wa pakiyesi Kabiyesi lati mase dasi ọrọ ẹlẹsin dé nilu Ogbomoso nipataki julọ ọrọ Imaam ati awọn ẹbi Ayilara, Ori Ade naa ko sai tenumọ pe, Awọn Ori-Ade ọrun-ilẹkẹ ko lẹtọ bẹẹni wọn ko lagbara lori awọn Adari ẹṣin nilẹ Yoruba ati nibi gbogbo.
Ọba Aládé naa tiise igbakeji Alaga igbimọ awọn l’ọba-lọba ati awọn ijoye nipinlẹ Oyo, sọ wipe Sheik Yunus Ayilara sì ni Imamu Agba ilẹ Ogbomoso eyi ti awọn mọ ti gbogbo ilu naa si mọ pẹlu.
O ni, wọn ti pe àkíyèsí oun, at’awọn àgbagba majeobaje-ilu Ogbomoso si ariwisi eyi ti ẹgbẹ musulumi iyẹn Muslim Rights Concern (MURIC) se lori iyansipo Habib Ayilara gẹgẹ bí Imamu agba Aafin Ogbomoso, ẹni tí Sọun tilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afọlábí Olaoye yan sipo naa L’ọjọ ẹtì Friday ti o kọja yi.
O ni, gẹgẹ bí Agbaojẹ eekan nilu Ògbómọ̀ṣọ́, ati gẹgẹ bí Igbakeji alaga fún igbimọ awọn l’ọba-lọba ati awọn ijoye nipinlẹ Óyo, oun mu da ẹgbẹ MURIC l’oju pe awọn o ṣiṣe takuntakun lati ri daju pe awọn ko fayegba ki àwùjọ àwọn mùsùlùmí pin yẹlẹyẹlẹ nilu Ogbomọsọ ati agbegbe rẹ.
O wa tun mu da ẹgbẹ naa MURIC ati awọn ọmọ Nàìjíráà loju lori iṣẹlẹ naa, pe awọn ko ni laju awọn kalẹ lati fayegba ipinya laarin àwùjọ àwọn mùsùlùmí nilu Ogbomoso.
Olugbọn ni, igbẹjọ lori ọrọ naa sí wá nileẹjọ, leyi to fihan pe Sheik Ayilara sì ni Imamu Agba ayafi ti Ile-ẹjọ ba pohun da loku.
O pe gbogbo awon to n pe fún ìpínyà ki wọn jáwọ, bibẹẹkọ wọn o kandin ninu iyọ.
O ni gẹgẹ bí Ori-Ade ọrun-ilẹkẹ nilẹ Yoruba oun mọ wipe Ọba Alade kan ko lagbara lori Imamu Agba ati awọn adari ẹṣin gbogbo nilu wọn.
O ni, ijọba nikan lo lẹtọ labẹ ofin lati yọ adari ẹṣin ti wọn ba gbe sori ipo gẹgẹ bí adari ẹṣin, nigba ti ìpinnu náà sì gbọdọ tẹle Ilana ofin.
Olugbọn ni, oun o Olugbọn ti orile-igbọn, Oba Francis Olushola Alao, sì dúró digbi wa lẹyìn Imamu Agba Taliat Yunus Olushina Ayilara Ki o ma tẹsiwaju ojúṣe rẹ gẹgẹ bí Imamu Agba ilu Ogbomoso nitoripe oun ni ẹni tí àwùjọ Musulumi yan saaju iku Sọun ti o waja sini.
O ni, ki ọkàn ẹgbẹ MURIC ati awọn Agbaojẹ majeobaje fawọn Musulumi ma se poruru ọkan nitoripe igbẹjọ sí wá nileẹjọ lori ọrọ naa, awọn Agbaojẹ majeobaje-ilu Ogbomoso n bẹ lẹyìn Imamu Agba Taliat Yunus Olushina Ayilara onyẹ kan kosi ni yẹ kuro nipo Imaam.