Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumogege lll, Soun t’ilẹ Ogbomoso lo seto yiyan Habib Ahmed Adekunle Ayilara gẹgẹ bi Imaamu asaaju eto gbogbo ti o nise lori ẹsin Islam ni aafin rẹ.
Ọba Olaoye nigba to n sọrọ nibi eto wiwe lawani naa ti o waye lọjọ Ẹti Friday laafin rẹ Kabiesi ṣalaye pe aafin nilo Imaamu ti yoo maa dari irun kiki.
O ni ọjọ tipẹ ti ọpọ awọn eeyan to jẹ ẹlẹsin musulumi laafi ti n kirun laini asaaju kan ti o jẹ yiyan pẹlu ontẹ Ọba ninu
Ọba Ghandi ni aafin Soun nilo Imaamu ti yoo maa ṣoju oun ninu gbogbo eto tawọn eeyan ẹlẹsin musulumi ba n ṣe yala niluu Ogbomoso tabi nibo miran.
Ọpọ awọn musulumi lọkunrin ati lobinrin lo peju si aafin Soun nibi ti wọn ti we lawani Imaamu fun Habib Ahmed Adekunle Ayilara naa.
Lara awọn eeyan ọhun ti wọn wa nikalẹ ni Parakoyi Ogbomoso, Alhaji Surajudeen Akeem, Sẹnẹtọ Fatai Buhari ẹni ti Alhaji Yekinni Wọleọla ṣoju fun atawọn Imaam imaam olori ẹsin musulumi mii l’Ogbomoso.
Sheikh Habib Ayilara ẹni ti wọn we lawaani Imaamu Afin Sọun fun yii ni ẹbi Ayilara ti saaju fọwọ si tẹlẹ pe ki o jẹ Imaamu Agba ilu Ogbomoso, saaju ki ọrọ o to dojuru.
Parakoyi ilu Ogbomoso ko ṣai satẹnumọ rẹ gẹgẹ bi Kabiesi se sọ pe aafin Soun ni Imaamu Sheikh Habib Ayilara wa fun, o ni Imaamu Agba ilu Ogbomoso, Sheikh Teliat Yunus Olusina Ayilara ṣi wa ni ipo rẹ gẹgẹ bi Imaamu agba ilẹ Ogbomọsọ.
O ni oun gbagbọ pe eyi owu ẹsin ti onikaluku ọmọ ilẹ Ogbomọsọ ba n se lo le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilu Ogbomoso laifi ti ẹlẹya mẹya tabi ikorira si.
O ni oun kosi ni kaarẹ ọkan nipa gbigbaruku ti iṣọkan ilu Ogbomoso fun anfani gbogbo araalu.
Iroyin wiwe lawani fun imaam tuntun laafin Sọun ọhun lo ti wa bẹrẹ sini da awuyewuye silẹ latari bi awọn kan ti n gbe kiri pe wọn ti yọ imaam agba ilẹ Ogbomọsọ Sheikh Teliat Yunus Olusina Ayilara nipo Imaamu agba.
Iroyin ti o ti Aafin Sọun tilẹ Ogbomọsọ tẹwa lọwọ ninu atẹjade kan ti wọn fi sita salaye ẹ pe ipa ọtọọtọ ni ipo Imaam Aafin Sọun ati Imaam agba ilẹ Ogbomọsọ ni lati ko, ki awọn eeyan o mọ da luru pọ mọ sapa ọrọ naa.
Imaam Agba ilẹ Ogbomọsọ Sheikh Teliat Yunus Olusina Ayilara ni Imaam asaaju irun fun gbogbo Musulumi Ogbomọsọ nigbati Imaam Sheikh Habib Ayilara si wa fun Afin Sọun nipa gbigba Ọba nimọran lori ọrọ ti o ni i se nipa ẹsin musulumi ati dida irun ati awọn akanse adua fun awọn musulumi ti o wa ninu afin.
Se ti ogiri o ba si lanu alangba o le raye wọle gẹgẹ bi a ti gbọ ohun ti o sokunfa eyi ko sẹyin igbesẹ ti Imaam agba ilẹ Ogbomọsọ gbe nipa pipe Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye lẹjọ, ati iwe ẹsun pe oun koni nkan se pẹlu afin Sọun.
Aisi ibasepọ ti o dan mọran eyi ti o mu ki Imaam o jinna si Aafin Sọun ti eyi si n se idiwọ fun awọn ipa kan ti o yẹ ki ẹni ti o ba jẹ Imaam o ma ko gẹgẹ bi oloye ọba to n siwaju awọn eeyan ẹlẹsin musulumi nilu.
Atẹjade naa wa ni ki awọn eeyan ti o n sọ ohun ti oju wọn o to o wa di ootọ ki wọn si se olootọ lori ọrọ to wa nilẹ