Iroyin pajawiri

Àjọ NCC tun ti kéde gbèdéke tuntun fún àwọn eeyan tí kò tíì so nọ́mbà fóònú wọn pọ̀ mọ́ nọmba ìdánimọ̀ NIN

Ajọ NCC, ajọ to n ṣakoso awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilẹwa Naijiria ti tun kede gbedeke ọjọ ti wọn yoo fofin de awọn ti wọn ko i ti so Sim wọn pọ mọ NIN wọn.

Ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an to n bọ yi ni ajọ naa kede gẹgẹ bi gbedeke ọjọ tawọn eeyan ni lati so nọmba foonu wọn pọ mọ kaadi idanimọ NIN wọn.

Ajọ naa kede rẹ loju opo X wọn lalẹ Ọjọru Wednesday wi pe oun ti sọ fun gbogbo ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ nilẹ Naijiria lati pari eto siso nọmba foonu wọn pọ mọ kaadi NIN titi ọjọ kẹrinla oṣu Kẹsan an.

Ninu atẹjade ti ọga agba ajọ naa to ni ṣe pẹlu ibaraẹnisọrọ pẹlu araalu ajọ NCC, Ọgbẹni Reuben Muoka, sọ igbesẹ naa lati jẹ ki gbogbo eeyan so nọmba foonu wọn pọ mọ kaadi NIN wọn gẹgẹ bi alakalẹ ijọba.

Ọgbẹni Muoka sọ ninu atẹjade naa pe ọpọ Naijiria lo ti so nọmba wọn pọ mọ kaadi idanimọ NIN wọn.

Amọ, ajọ naa tun rọ awọn ọmọ Naijiria ti ko tii so nọmba wọn pọ mọ kaadi NIN wọn pe ki wọn o se bẹ ki o too di ọjọ kẹrinla oṣu Kẹsan an ọdun yi.

Ọgbẹni Muoka ṣalaye ninu atẹjade naa pe siso nọmba foonu pọ mọ kaadi NIN yoo ṣeranwọn fun eto ọrọ aje ati eto abo.

Bakan naa o ni siso nọmba foonu pọ mọ kaadi yoo jẹ ko rọrun lati maa gba owo ati sanwo lori ẹrọ kọmoputa tabi lori foonu ni irọrun.

Eyi yoo tun mu adinku ba iwa jibiti ori ayelujara tawọn kan n lo fun awọn ọmọ Naijiria.

A o ni awọn fẹ ri wi pe lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹsan an to n bọ yi, ko ni si nọmba foonu kankan ti ko ni tii di siso pọ pẹlu kaadi idanimọ NIN.

O ni nitori naa ni awọn ṣe n rọ gbogbo eeyan ti wọn ba n koju iṣoro kan tabi omiran lori ati sọ nọmba foonu wọn pọ mọ kaadi NIN wi pe kiwọn tete lọ si ọfiisi ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ wọn ki o di ọjọ kẹrinla oṣu Kẹsan an.

Bakan naa, ni wọn tun fẹ ki araalu mọ pe rira tabi tita nọmba foonu eyi ti wọn ti forukọ silẹ lodi sofin, wọn ni ẹni ti ijọba ba gbamu pe o ṣe bẹẹ yoo lọ gbatẹgun lẹwọn, Ọgbẹni Muoka lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ajọ NCC.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ìmáàmù Agba Ogbomoso tu ba o, o rawọ-ẹbẹ sí Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi, pe ko má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ t’oun bá ṣẹ̀

Lẹyin ọpọ awuyewuye, gbonmisi-omi-o-t o ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *