Iroyin pajawiri

Ó má ń wù mí kí n kọ́lé sí Lekki àmọ́ àlá àti ìgbà kékeré kò jẹ́ – Ibrahim Chatta.

Gbajumọ Oṣere tiata nní, Ibrahim Chatta, gbajumọ osere ti ọpọ mọ pe o ma n gbe asa ati iṣe yoruba larugẹ, ti jẹ ko di mímọ pé, Láti kékeré oun ní òun tí sọ fún ará oun pé oun náà yóò ní ibí kan tí wọ́n o ti maa ṣe eré, ya sinima.

O ni, Ó má ń wù oun kí oun kọ́lé sí Lekki bíi àwọn ẹgbẹ́ oun se kọ, àmọ́ àlá àti ìgbà kékeré kò jẹ́.

Gbajugbaja oṣere tiata naa Ibrahim Chatta ṣo pe gbogbo igba lo ma n wu oun lati ṣe awọn nkan meremere bi ile kikọ, gẹgẹ bi awọn akẹgbẹ rẹ yooku se n se, ti wọn n da l’ara.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti o se pẹlu awọn oniroyin ni gbajumọ oṣerekunrin naa ti sọ pe akanṣe iṣẹ kikọ abule nla kan eyi ti awọn eeyan yoo ti le maa lo ya ere sinima, ni ko fi aaye gba oun.

Ọgbẹni Chatta ṣalaye pe lati igba kekere ni oun ti ni ala lati kọ iru abule bẹẹ ti awọn oṣere akẹgbẹ rẹ yoo ti ma ni anfaani lati se ere sinima wọn ni ilana aye atijọ.

O ni, nigba t’oun dawọ le kikọ Africhatta, ibudo iya ere sinimọ, ọpọ ibeere lo ni oun bi ara oun pe ṣe nnkan yii lo kan ninu ọrọ oun.

Abule, ibudo iya ere sinimọ Africhatta, to wa niluu Oyo, ọhun lo jẹ ọkan lara aye to wa fun awọn oṣere lati lo se ere sinima wọn, to si pese awọn ohun eelo ti yoo mu ko da bi aye atijọ sibẹ.

Awọn ile alamọ, ẹṣin, ọja adayeba ati awọn ohun aaye atijọ miran lo wa ni abule ibudo Africhatta naa.

Bakan naa ni o tun kọ ile itura fun awọn to ba wa ya ere sinima lati ni aye to dara fun oorun lẹyin ti wọn ba pari iṣẹ wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ pe iṣẹ irinajo ni iṣẹ sinima, Ibrahim Chatta ni oun lọ ṣiṣẹ ni ilu kan fun ọpọlọpọ ọjọ, ti oun si fi owo nla gba ile itura lati sun.

O ni, “ori ilẹ ti oun fi kọ abule ibudo iya sinimọ naa, nigba ti oun fẹ raa, o jẹ akoko ti oun fẹ se akans iṣẹ kan ti oun o si lo bii ọjọ mejilelogoji, o ni lẹyin iṣẹ ọhun oun yoo si tun bẹrẹ iṣẹ mii ti ohun maa to bii oṣu mejidinlogun.

O ni eyi ni o mu oun ro pe laarin ọjọ ati osu ti oun fẹ lo naa owo ti yoo bọ lara oun fun yara t’oun nikan, oun maa n rera nipa ibi sisun lalẹ, ibi ti oun yoo ki ori bọ.

O ni, bakan naa ni oun ro pe, ti oun ba san owo ile itura fun ọjọ mejilelogoji lẹyin oṣu kan, oun ma tun san owo oṣu mi.

Niise l’oun siro owo naa papọ ti o si jẹ owo ti o to owo

O ni bayi ni oun pe awọn onilẹ adugbo naa wa pe, ki wọn fun oun ni aye kan ti oun fẹ ra, ti oun ba n ṣiṣẹ ninu ọdọ wọn, ti oun le ma maa sun si, ti wọn yoo sí din oun ni owo.

O ni oya loun tun ro pe se ti oun ba pari iṣẹ tan, ṣe oun o kan fi ilẹ naa silẹ ni, o ni bayi ni oun kọ ile kan, eyi ti oun ma le gbe ti oun yoo si maa mojuto nnkan oṣin pẹlu ero pe ki ilẹ naa ko sa maa ṣofo.

Eeka ilẹ meji ni Ibrahim Chatta kọkọ ra, gẹgẹ bi o ti wi ti o si bẹrẹ si ni sin ẹṣin ati awọn ẹranko miran nibẹ.

O ni lẹyin naa loun bẹrẹ si ni kọ oriṣiriṣi ile atijọ, ati igbalode fun iṣẹ eré sinima yiya.

Lara awọn ere sinima to ti jẹ anfaani abule naa ni Jagunjagun ati Bashorun Gaa.

Yatọ si sinima ṣiṣe, abule ibudo Africhatta tun jẹ ibudo ti ẹbi le lo fun isinmi ati irinajo igbafẹ.

Ibrahim Chatta ni o maa n dun oun pupọ pe oun ko tete gbe igbesẹ naa lori nini aye ere sinima to jẹ ti oun sugbọn oun gbagbọ pe oorun to wa nita si to aṣọ ọ gbẹ.

O ni, igba ti oun kọkọ bẹrẹ akanse isẹ lorilẹ naa, igba mii wa t’oun o da joko wi pe ki loun ṣe yii, se oun si n se nkan ti o lọpọlọ bayi, Gbogbo ẹgbẹ oun n kọ ile si Lekki oun wa nkọle sinu igbo.

O ni, sugbọn ninu ohun gbogbo ti awọn eeyan ba n sọ, lo maa n mu oun tẹsiwaju.

O fikun ọrọ rẹ pé, oun ṣe awari pe lati tan iṣoro awọn eeyan kan le pa owo fun eniyan, eyi wa lara oun ti o tẹ oun siwaju.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ìmáàmù Agba Ogbomoso tu ba o, o rawọ-ẹbẹ sí Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi, pe ko má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ t’oun bá ṣẹ̀

Lẹyin ọpọ awuyewuye, gbonmisi-omi-o-t o ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *