Iroyin pajawiri

Tòhun tomijé ójú ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn péjọ sẹ̀yẹ ìkẹyìn níbi ètò ìsìnkú Àdùkẹ́ Gold

Niiṣe ni awọn ẹbi, ara ọrẹ ati awọn ololufẹ ologbe Aduke Ajayi, ti ọpọ eeyan mọ si Aduke Gold fomije s’ogbere oju pade iyoku ara oloogbe Adukẹ nigba ti wọn gbe de ibi eti isinkẹ rẹ.

Aduke Gold, ẹni to jade laye ni ọsẹ to kọja l’ọgba ile iwosan UCH niluu Ibadan.

Ni wọn seto isinku rẹ loni ọjọ Ẹti Friday nibi ti wọn ti fi eru fun eeru fi erupẹ fun erupẹ fi iyoku ara ologbe naa fun ilẹpa.

Ọpọ awọn eeyan ti wọn soju sẹyin nibi eto isinku naa ni wọn n sọ ohun ti wọn mọ nipa ologbe Adukẹ Gold.

Nigba to n sọrọ, ọkan lara awọn ọmọ lẹyin Aduke Gold, Michael Akande salaye pe gbogbo awọn mọ riri ipa nla ti Aunty Aduke ko ninu igbesẹ aye awọn.

O ni”Gbogbo awọn ni Aunty Aduke fẹ kawọn o se orire, o fẹ k’awọn ka iwe, o fẹ k’awọn gbe igbe aye to dara to sumọ Ọlọrun.”

Ẹnikan tí oun jẹ alajọgbe Adukẹ nigba aye rẹ, o ni ọpọ awọn ti awọn jọ n gbe ile ni awọn ko mọ pe ilumọka ni nitori o jẹ eeyan to rẹ ara rẹ silẹ.

O ni “Awọn ko mọ pe ilumọka ni nitori ko ri ara rẹ gẹgẹ bii eeyan nla, O ni iwa tutu bi adaba ti gbogbo awọn si nifẹ rẹ ladugbo ni.

Pasitọ Henry Sinmidele fi ọrọ Ọlọrun bọ awọn to pejọ sibi ẹyẹ ikẹyin Aduke Gold pe gbogbo ohun to waye lo jẹ akọsilẹ ti ko si ẹnikẹni to le se nnkan nipa rẹ.

Oniwasu naa ni Ọlọrun nikan lọ mọ ju, O ni, ko dun mọ wa ninu sugbọn Ọlọrun Ọba lo ni gbogbo nnkan lọwọ

O ni lara ohun ti eeyan ni lati se ti yoo sọ nipa pe eeyan lo aye rẹ daadaa ni Adukẹ fi aye rẹ se, Aduke gbe igbe aye to dara, o lo ẹbun rẹ lati fi yín Ọlọrun to da saye, O ko ipa nla ninu awọn eeyan to sun mọ lasiko aye rẹ.”

Lẹyin gbogbo ọrọ iyanju eti iboji ni wọn gbe iyoku ara ologbe lọ si itẹ nibi ti wọn ti f’eru fun eru fi erupẹ fun erupẹ.

Adukẹ Ajayi ti gbogbo awọn eeyan mọ si Adukẹ Gold o di bẹni ba n jọni odi beeyan ba n jọyan, o dowurọla o tun doju ala kato rira wa ni gbolohun ọrọ idagbere ti awọn eeyan ololufẹ rẹ fi pẹyinda kuro leti iboji

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ọ̀rọ̀ akọ àti abo tí Trump sọ nípa rẹ̀ kò kàn èmi o torí obìnrin ni mí, mo sì ní ẹ̀rì tó dájú – Bobrisky

Ọ̀rọ̀ akọ àti abo tí Trump sọ nípa rẹ̀ kò kàn èmi o torí obìnrin …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *