{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"transform":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Oró nla lẹẹdá o, ẹ̀yin t’ẹpa Mojisola Awesu akẹ́kọ̀ọ́ jáde nílé ẹ̀kọ́ ìsègùn Kwara State College of Health Technology tó wà nilu Offa, nipinlẹ Kwara.

Ileesẹ Ọlọpa ti fi gbooro ofin gbe awọn Afurasi meji, Woli Adebayo ti ọpọ mọ si Ogunsẹ ati ọmọ rẹ, Happiness lori ikú Mojisọla Awesu to jáde láyé lẹ́yìn to bá Happiness ọmọ woli lọ ilé ìtura nilu Ilorin

Latari bi iku akẹkọbinrin to ṣẹṣẹ pari eto-ẹkọ rẹ nile ẹkọ isegun Kwara State College of Health Technology to wa nilu Offa se lu ori-itakun ayelujara kan lọsẹ to kọja.

Bi o ti tilẹ jẹ pé orísirísi ahesọ, awuyewuye ni awọn eeyan ngbọ nípa ọrọ iku Akẹkọbinrin naa ti wọn sekupa.

Amọ akọroyin wa ti ri aridaju ohun tó ṣẹlẹ gan pato lẹyìn tí Ileesẹ Ọlọpa bẹrẹ Iwaadi-ifinmufinle wọn lori iku Akẹkọbinrin ọhun

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lo ti saaju bẹrẹ iwadii-ifimufinle lori iku akẹkọbinrin naa ẹni ọdun mọkanlelogun Mojisola Awesu, ti wọn ba oku rẹ lori akitan, nilu Ilorin.

Akẹkọọ ile ẹkọ iṣẹgun Kwara State College of Health Technology, to wa nilu Offa, ni Mojisola, o sì ṣẹṣẹ pari eto-idanwo asekagba nile-ẹkọ naa ni, ko to salaba-pade iku gbóná latọwọ awọn asekupani ẹda

Gẹgẹ bí Iroyin ti a gbọ, Mojisola di awati lẹyin ti ọrẹ rẹ kan bẹẹ lọwẹ pe ko tẹle ọrẹ oun to jẹ ọkunrin lọ ode ariya, ko si ṣe bii ọrẹbinrin ọkunrin naa ko le gba owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlogun N15,000 naira.

Agbẹnusọ ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Kwara, DSP Toun Ejire-Adeyemi, fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade kan to jẹ gbigbe jade lati ofisi rẹ

Ileesẹ Ọlọpaa sọ ninu atẹjade naa pe ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii ni wọn ta ileeṣẹ Ọlọpa lolobo pe oloogbe ọhun di ẹni ti wọn n wa.

O ni “lọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yi ni nnkan bii aago mẹrin abọ irọlẹ, ni omidan kan, torukọ rẹ n jẹ Blessing, to n gbe lagbegbe Gbomi, niluu Offa, nipinlẹ Kwara sọ fun ileese ọlọpa pe alabagbe oun ninu yara kan naa iyẹn room mate oun ni Omidan Mojisola Awesu, ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun to jẹ akẹkọọbinrin ileewe isegun Kwara State College of Health Technology, ti di awati lati ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹjọ.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Mojisola gba ipe lati ọdọ Omidan kan ti orukọ rẹ n jẹ Timileyin, to ni ko yọju sibi ode ariya kan ti yóò waye ni ileewe gíga fasiti Summit ati Al-Hikmah, niluu Ilorin.

“Omidan Timileyin lo fa Mojisola le Ọgbẹni kan to n jẹ Adebayo Happiness lọwọ, to jẹ akẹkọọ fasiti Summit, ti Adebayo si ni ko ba oun lọ ode ariya nibi ti yoo ti dibọn gẹgẹ bii ọrẹbinrin oun ti oun yo si fun ni ẹgbẹrun marundinlogun naira N15,000.”

Ileesẹ Ọlọpaa ṣalaye pe nigba ti oloogbe ọhun yoo de ibẹ, o pe alabagbe rẹ pe ile itura ti Adebayo Happiness fi oun si ko tẹ oun lọrun ati pe ko si ayẹyẹ kankan to n waye nibẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti Ileesẹ ọlọpaa sọ, lẹyin to fi ọrọ naa ranṣe si alabagbe rẹ tan ni foonu ibaraẹnisọrọ rẹ ku ti ko si si aaye lati kan si mọ.

Agbẹnusọ Ileesẹ ọlọpaa ṣalaye siwaju si pe awọn ti tari ọrọ naa lọ si ẹka CID fun iwadii-ifimufinle ni kikun.

Kọmiṣọna ọlọpaa, CP Victor Olaiya si ti ṣeleri lati tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Ileesẹ Ọlọpa ti wa fi gbooro ofin gbe awọn Afurasi meji kan.

Nigba ti ọwọ tẹ Adebayo Happiness ẹni ti ọrẹ awesu fa le lọwọ lati jọ lọ sibi ayẹyẹ, o ni ki wọn soun jẹjẹ pe baba oun lo ran oun nisẹ asekupani ti oun jẹ.

Nibayi ileesẹ ọlọpaa ti wa fi gbooro ofin gbe Baba rẹ naa torukọ rẹ n jẹ Woli Adebayo Adeniyi ti ọpọ mọ sí (OGUNSẸ) ti wọn lọwọ nínú iku to pa Mojisola.

Awọn Afurasi mejeeji ọun ni wọn si ti wa lagọ Ọlọpa, ti wọn ti n f’ọrọ wawọn lenuwo.

Ileesẹ Ọlọpa ni Iwaadi-ifinmufinle sì n tẹsiwaju.

Wayi o awọn Akẹkọ Akinẹgbẹ Akẹkọbinrin ti wọn sekupa naa ti wa jade sọfọ rẹ nipa Candle light l’ọjọ isegun Tuesday, ti i se ogunjọ, osu kẹjọ, ọdún.

Nse lawọn Akẹkọ ileewe naa tofi mọ awọn oloolufẹ Oloogbe naa gbogbo wọn ni wọn se bẹ jade se Iwọde Candle Light naa ti wọn si n pe fun idajọ ododo fún Akinẹgbẹ Mojisola Awesu ti wọn sekupa.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ipò t’Oriyomi Hamzat níleewòsàn lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó sokùnfa ikú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé nibi ayẹyẹ ìparí ọdún nilu Ìbàdàn

Alasẹ ati oludari Ileesẹ redio igbohunsafẹfẹ Agidigbo FM nilu Ibadan, Oriyomi Hamzat d’ero ileewosan lasiko …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *