Ayẹyẹ ọdun iṣẹṣẹ wa kaakiri ilẹ Yoruba, Paapajulọ lawọn ipinlẹ bii Ọyọ, Eko, Ọṣun, Ogun to fi mọ ipinlẹ Kwara.
Gbogbo ogunjọ oṣu kẹjọ ọdọọdun ni ayajọ ọdun iṣẹṣẹ ni ilẹ Yoruba.
Kaakiri awọn ilu isẹmbaye, nilẹ Yoruba ni awọn ipinlẹ ti o wa lẹkun gusu orileede Naijiria ni ajọdun Isẹmbaye naa ti ma n waye.
Ṣaaju ni awọn ipinlẹ kan nilẹ Yoruba ti kọkọ kede Ogunjọ oṣu Kẹjọ yi gẹgẹ bi ojọ isinmi lẹnu isẹ lati fi se ọdun isẹse gẹgẹ bii ayajọ ọdun awọn ẹlẹsin Isẹse, ẹsin abalaye.
Isinmi naa ni wọn kede rẹ fun awọn eeyan ki awọn ti o ba jẹ ẹlẹsin abalaye le ṣe ọdun wọn.
Ti a ko ba gbagbe, saaju ki ikede naa o to waye ni awọn ẹlẹsin abalaye ti n bere pe o yẹ ki ijọba o yẹ awọn naa si, ko fun awọn ni ọjọ isinmi.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ ninu ibere wọn ṣaaju, wọn ni awọn naa lẹtọ si ayẹsi ati ọjọ isinmi gẹgẹ bo ṣe wa fun awọn ẹlẹsin Kristẹni atawọn ẹlẹsin Musulumi.
Wọn sọ pe ti ijọba ba le maa ṣeyẹsi awọn ẹlẹsin to ku, to si n kede isinmi fun wọn lẹnu iṣẹ lati ṣe ọdun wọn, awọn pẹlu naa tọ si irufẹ ayẹsi ati isinmi bẹẹ lẹnu isẹ.
Ko pẹ lẹyin gbogbo atotonu, ibeere wọnyi ni ijọba kede ọjọ ogunjọ osu kẹjọ fun wọn lati mafi sinmi lẹnu isẹ fun a ti se ọdun wọn ti i se ayajọ ọdun isẹse.
Awọn ipinlẹ naa to kede ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yi gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni
Ipinlẹ Eko, Ipinlẹ Ogun, Ipinlẹ Oyo, Ipinlẹ Osun.
Ipinlẹ Ondo ati ipinlẹ Ekiti ni wọn o ti kede irufẹ ikede naa nipinlẹ wọn
Botilẹ jẹ pe kii ṣe gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lo kede isinmi naa amọ sibẹ pupọ awọn ilu ti o wa ni ipinlẹ kọọkan nilẹ Yoruba ni wọn ti korajọpọ se ayẹyẹ ọdun isẹse ti i se ọdun awọn ẹlẹsin abalaye.
Ni ipinlẹ Ogun, agbegbe oke Abola, Oke Aregba Abeokuta ni ayẹyẹ naa ti waye.
Ni kutukutu owurọ lawọn ẹlẹsin abalaye ti bẹrẹ si i korajọpọ si ibudo naa.
Bakan naa lọmọ ri lawọn ipinlẹ yoku bi ipinlẹ Eko, Ọyọ, Ọsun ati ipinlẹ Kwara.
Àjọ̀dún àyájọ́ ọdún ìṣẹ̀ṣe naa waye ní ìlú Shao ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Nilu Osogbo nipinlẹ Ọsun, Papa isere Adamasingba nilu Ibadan lawọn ẹlẹsin Isẹse, ẹsin abalaye yinka ipinlẹ Ọyọ korajọpọ si.
Se onirunru ọbẹ laari lọjọ’ku eerin bẹẹ lọrọ ri ni papa isere Adamasingba ọhun nibi ti awọn eekan Babalawo, Ọmọ awo, ori ade ọrun ilẹkẹ korajọpọ si, Bi eegun ti n jo, ni igunnu njo ti agere naa o si ye maa dara, oniruru iran lokun bi ọdun isẹse ọhun ti o waye nilu olu ilu ipinlẹ Ọyọ.