Gbajugbaja akọrin ẹmi nni Adeyinka Alaṣeyori, lo ti pariwo sita bayi o, o ke gbajare pẹlu omije loju wi pe awọn eeyan kan n dunkoko iku mọ oun, wọn fẹ gbẹmi lẹnu oun.
Alaseyori sọrọ naa ninu fọnran fidio kan to fi lede loju opo ayelujara rẹ lopin ọsẹ to kọja yi.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọsẹ to lọ yi ni ilumọọka akọrin ẹmi, Aduke Ajayi Morounkọla ti ọpọ mọ si Aduke Gold jade laye lẹyin to ṣe aisan fun ọpọ ọdun.
Se ẹni n lọ ni waju to jin sọfin o kọ ẹni ti nbọ lọgbọn ni, ki soobia o si to d’egbo olukanbi laakesi ki ọrọ o si ma bẹyin yọ lo mu ki gbajumọ akọrin ẹmi naa Yinka Alaseyọri o oa pariwo sita.
Alaseyori sọ ninu fọnran fidio naa pe ‘’o to ki oun bẹru eeyan, idi ni pe iku ko ni pa oun laipe ọjọ, O di eewọ!
Gẹgẹ bi o ti wi o ni Ọpọ lo n fi oriṣiiriṣii atẹjiṣẹ buruku ranṣẹ si oun lori itakun ayelujara.
Ọpọ lo n fi ẹnu wọn pe ipekupe si oun, ẹnu aye si lẹbọ.
Se ọrọ ti o ba ju ẹkun lọ ẹrin leeyan fi i rin, o ni nṣe loun n maa n rẹrin in ti oun ba ti ri irufẹ atẹjiṣẹ bẹẹ, tori ẹnikẹni to ba ro iku ro oun, pe ki oun o ku ni kekere irufẹ ẹni bẹ fẹẹ ku niyẹn.
Alaseyori ni ẹnikẹni to ba ko awọn eeyan jọ lati maa gbadura odi le oun lori, iku a maa le wọn kiri ni, ti wọn ba duro iku, ti wọn ba jokoo iku, koda pẹlu loju orun ati loju aye wọn iku ni.
O ni a fi ti awọn eeyan naa ba ye wa si oju opo ikanni ayelujara oun lati DM oun maa sọrọ odi si oun, sọ ọrọ ibi nipa oun.
Gbajugbaja akọrin ẹmi naa sọ pe wa fi ote le pe ‘’o di eewọ fun ẹnikẹni lati wa ma DM oun ro iku ro oun.
O ni wọn le maa ṣe e fawọn ẹlomiran ki wọn o maa mujẹ, amọ, o di eewọ lori oun Adeyinka Alaseyori.
O ni Angẹli apanirun ni yoo maa le gbogbo eeyan to n pe iku le oun lori.
Koda, to ba jẹ wooli lo n ro iku ro mi, angẹli apanirun a doju ija kọ̣
O wa rọ gbogbo eeyan ololufẹ rẹ lati maa gbadura fun.
Akọrin ẹmi naa Alaseyori ni awọn eeyan ni lati gbadura gidi foun tori aye le ju bi ọpọ wọn ti ro lọ.
Alaseyori ni oun o sọkun tori ọrọ naa ba oun ninu jẹ pupọ ju.
O ni Ọpọ eeyan ni ko mọ ohun to n lọ labẹlẹ, oriṣiiriṣii nnkan lo n ṣẹlẹ ti ọpọ eeyan ko mọ.
O ni ki awọn eeyan o ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni tan wọn jẹ onikaluku wọn nilo adura, asiko si niyi lati gbadura gigi tori wọn o ro ire ro wọn.
Ọpọ nnkan lo ti n ṣẹlẹ lati bi oṣu mẹfa sẹyin bayii, ti o ni oun o wulẹ sọ sita rara, amọ ọrọ iku o se mu mọra rara b’otiwulẹ ki o mọ.
O ni ohun ti oun mọ ni pe Ọlọrun lo ni ẹmi onikaluku lọwọ, tori naa, ki onikaluku o maa fi Ọlọrun silẹ nigba kankan.
O ni oun fẹ ki awọn eeyan o gbadura fun oun ti wọn ba ti n gba adura fun arawọn naa.