Bàbawándé ló talẹ̀ Òòsà dáràn nínú Sinimọ́ t’Olúwa nilẹ̀, Òṣìṣẹ́ ìjọba kan naa re o, ó rẹ́wọ̀n he lẹ́yìn tó t’alẹ̀ ìjọba nipinlẹ Ọ̀yọ̀.
Osisẹ Ijọba ìbílẹ̀ kan tó ń ta ilẹ̀ ìjọba lọ́nà àìtọ́ rí ẹ̀wọ̀n he lẹyin ti o se bẹ ta ilẹ ti o jẹ ti ijọba ibilẹ rẹ lọna aitọ.
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, iwa ibajẹ n’ipinlẹ Ọyọ, iyẹn Oyo State Anti-Corruption Agency, ti apepọ rẹ n jẹ (OYACA)’, ti kede ẹbi ẹsun ti òṣiṣẹ ijọba ibilẹ kan jẹ lẹ́yìn ti àṣírí rẹ tú pe o ń ta ilẹ̀ ijọba ipinlẹ Ọyọ lọ́nà aitọ.
Se ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan soso si ni tolohun, Afurasi oṣiṣẹ Kansu náà, Adesina Olanrewaju Oyegoke, ẹni ti o jẹ igbákeji ọ̀gá agba lẹka ile alakọpọ, nijọba ìbílẹ̀ Lagelu, nilu Ibadan, ni wọn ti se dajọ rẹ pe ko lọ re maa gbatẹgun lọgba ẹwọn naa tori pe o jẹbi ẹsun naa ti wọn fi kan.
Ẹwọn oṣù mẹta gbako ni wọn ni ki ọkunrin naa o lọ lo lori ẹsun mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti wọn fi kan an latari pe o jẹbi ẹsun titalẹ ijọba.
Awọn ẹ̀sùn naa gẹgẹ bi ajọ ọhun se wi ni wọn lo ni i ṣe pẹlu ìwà ajẹbanu labẹ ofin ajọ OYACA ti ọdun 2019.
Ninu ìdájọ́ ti Adajọ O. A Akande gbe kalẹ̀ lọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ ọdún yii ni ilé ẹjọ to n bẹ ni Iyaganku nilu Ibadan wọn ni ki Ọgbẹni Adesina o lọ re maa gbatẹgun lẹwọn fun oṣu mẹta.
Bakan náà, ninu atẹjade ti ajọ OYACA ọhun fi ṣọwọ si awọn oniroyin l’Ọjọbọ Thursday, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣù kẹjọ ọdun 2024 yii, ninu èyí ti akọwe ajọ naa, Amofin I. O Tijani buwọ́lù lorukọ alaga, Adajọ Eni Esan.
Ajọ naa wa se kilọ fun gbogbo oṣiṣẹ ijọba láti dẹkun iwa ibajẹ, ki wọn o fọwọ sibi tọwọ n gbe kiwọfa wọn o ma sebi ọba ki wọn o mọ ba arawọn nibi ti wọn ko fẹ.
Wọn fi kún un pe ko si ibi ti amookunṣika le sa si, ti ọwọ ofin kò ni i to o lọjọ kan.