Iroyin pajawiri

Ọ̀YỌ́-SUBEB: Èyí ni àlàkalẹ̀ bi ohun gbogbo yoo se lọ fún àwọn olùsédánwò.

Ajọ SUBEB, State Universal Basic Education Board, ajọ to n ri si eto ẹkọ alakọbẹrẹ nipinlẹ Ọyọ ti se alakalẹ bi ifọwanilẹnuwo, ayẹwo fun awọn to peregede ninu eto idanwo eyi ti wọn se fun awọn to fe sisẹ olukọ laipẹ yi yoo se lọ.

Gẹgẹ bi wọn ti laa kalẹ lati Ọjọru, Wednesday, ọjọ kẹrinla, osu kẹjọ, si ọjọ Ẹti Friday, ọjọ kẹtalelogun osu kẹjọ yi kan naa ọdun 2024.

Se laipẹ yi ni ajọ naa gbe esi idanwo awọn ti wọn joko se’danwo pẹlu ẹrọ ayarabi asa Kọmputa CBT ti wọn se nilu ibadan jade.

Ninu ọrọ rẹ alaga ajọ SUBEB, Dokita Nureni Aderẹmi Adeniran l’Ọjọru Wednesday sọ ninu ifọwanilẹnuwo kan ti wọn se fun lolu ileesẹ ajọ naa ti o wa ni Agodi nilu Ibadan.

Ọmọwe Adeniran fi di ẹ mulẹ pe Ọ̀kẹ́-Méjì ó lé Ẹẹgbààta, ó dín Ọgọ́sán ó lé Meje, 45,827 ni awọn eeyan olusedanwo ti wọn joko se’danwo ọhun nigbati Ẹgbàrin ó lé Mẹ́tàdínlígba èèyàn si gba Maaki ti ijọba laakalẹ ti i se ida adọta soke, (50% cut-off Mark).

Ninu ọrọ rẹ Ọmọwe Adeniran sọ pe eto ayẹwo, ifọrọwanilẹnuwo fun awọn to yan yọ naa yoo jẹ didari nipasẹ oun ati awọn lọga lọga lati ẹka ọtọọtọ.

O wa se lalaye bi eto naa yoo se lọ, O ni Ọjọru Wednesday ọjọ kẹrinla 14 osu kẹjọ ni eto naa o bẹrẹ pẹlu awọn eeyan ijọba ibilẹ Ẹgbẹda, ijọba ibilẹ Atisbo ati agbegbe rẹ.

Ọjọ keji rẹ ti i se ỌjọbọThursday, ọjọ kẹẹdogun 15 ni yoo kan awọn eeyan ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ, Afijio ati Ibarapa Central.

Ọkọ kẹta rẹ ti i se Ọjọ Ẹti Friday, ọjọ kẹrindinlogun, 16 ni yoo sun kan awọn eeyan ilu Isẹyin, Itẹsiwaju, Kajọla, Ibarapa East, Ibarapa North, Lagelu ati Iwajọwa.

Ọjọ Aje Monday, Ọjọ kọkandinlogun 19 osu kẹjọ ọdun 2024 ni yoo kan awọn eeyan Ijọba ibilẹ Ido ati ijọba ibilẹ Ibadan South West.

Ọjọ Isẹgun Tuesday, Ogunjọ 20 ni awọn eeyan ijọba ibilẹ Saki West, Saki East, Irẹpọ, Oriire, Ọlọrunsogo, Orelope, Ogbomọsọ North ati awọn eeyan ijọba ibilẹ Ogbomọsọ South.

Ọjọ’ru Wednesday, ọjọ kọkanlelogun ni yoo sunkan awọn eeyan ijọba ̄ibilẹ Atiba, Ọyọ East, Ọyọ West, Surulere ati ijọba ibilẹ Ogo-Oluwa ati agbegbe rẹ.

Ọjọbọ Thursday, ọjọ kejilelogun, 22 ni awọn eeyan Ijọba Ibilẹ Ibadan South-East, Ibadan North-East ati awọn eeyan ijọba ibilẹ Ibadan North-West.

Ọjọ Eti Friday, ọjọ ketalelogun ni eto ayẹwo naa yoo dopin pẹlu awọn eeyan ijọba ibilẹ Oluyọle ati Ọna Ara pẹlu awọn ara agbegbe naa.

Ọmọwe Adeniran rọ awọn eeyan naa to n bọ fun ayẹwo lati wa pẹlu iwe pelebe ti wọn forukọ silẹ ati esi idanwo wọn ti wọn ti tẹ jade iyẹn Print Out.

O ni bakan naa ni wọn ni lati wa pẹlu iwe idanimọ ati iwe ẹri gbogbo ti wọn ba ni, bi iwe ẹri Ọjọ’bi, iwe ẹri ileewe, ojulowo iwe ẹri agunbanirọ NYSC fun awọn ti wọn ba lọ Fasiti, Iwe ẹri ipaarọ orukọ ati awọn iwe ẹri miiran ti o jẹ ojulowo.

O ni ago mẹsan owurọ ni ohun gbogbo yoo maa bẹrẹ ni gbogbo ọjọ ti awọn la kalẹ naa.

Ọmọwe Adeniran wa se ladura fun awọn arinrin ajo lati ijọba ibilẹ ti o jin pe wọn gunlẹ layọ ati alaafia.

O wa rọ awọn eeyan naa ki wọn o lọ wo ori itakun ayelujara oju opo ajọ naa lati le mọ ọjọ ti ayẹwo ati ifọrọwanilẹnuwo yoo kan wọn.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Wọ̀nyí ni bí nkan se lọ níbi ètò Ìsìnkú Sheik Muhideen n’Ibadan

Ero pitimu nibi eto isinku ilumọọka alfa to tun jẹ olukọ ẹsin Islam, oniwaasi Sheikh …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *