Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹri, Sẹnetọ Rashidi Adewọlu Ladoja ti sọ̣ pe oun ti ṣetan lati de ade idẹ, yatọ si ade paali to ba jẹ pe ọna kan ṣoṣo niyẹn lati di Olubadan ilẹ Ibadan.
Oloye Ladoja, eni to tun ti figba kan ri jẹ Sẹnetọ lorilẹede Naijiria sọ pe ko si gbogbo idiwọ ati idena ti wọn gbe ka iwaju oun, to le se dènà fún oun lati di Olubadan.
Ladoja sọrọ naa lori eto kan ti wọn pe ni Agbami Oṣelu ni ìkànnì ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Fresh FM to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.
Nibẹ lo ti sọ pe to ba jẹ ọna kan ṣoṣo to le di oun lọwọ lati de ipo toun ti n foju sọna fun lati ọdun to ti pẹ sẹyin niyẹn, ko si nnkan to da oun duro lati de ade eyi keyi ti wọn ba gbe wa saaju ojulowo ade Olubadan.
Ipo Olubadan lo jẹ pe awọn oloye agba nilẹ Ibadan ni wọn n jẹ ẹ, iyẹn awọn to wa ni ipo bii Balogun ati Ọtun.
Ladoja ninu ọrọ rẹ sọ pe “Oun maa de ade naa to ba jẹ pe ohun ni yoo di oun lọwọ lati di Olubadan tilẹ Ibadan.”
Ladoja tẹsiwaju pe Ọlọrun ti ṣaanu oun de ibi to ni apẹẹrẹ, to si loun ti ṣe gbogbo ohun to yẹ lati di Olubadan.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ọpọ lo n foju sọna lati di Olubadan, ṣugbọn ti ko si anfaani fun wọn.
O ni ọpọ lo ti de ipo Balogun tabi Ọtun Olubadan, ṣugbọn ti wọn ko de ipo Olubadan nitori pe kii ṣe ayanmọ wọn lati debẹ, to si loun yoo de ori itẹ naa nitori pe ayanmọ oun ni.
O ni nipa oore ọfẹ Ọlọrun, oun ni igbagbọ pe oun maa di Olubadan.
Gbogbo ifunpa oun to ga soke ti lọ silẹ bayii, oun si ti wa ni ilera pipe, ẹnikẹni ti Ọlọrun ba ti kadara wi pe yoo di Olubadan, dandan ni ko de ipo Olubadan.
Ko si oniruuru idena ti wọn le gbe soju ọna, bi Ọlọrun ba ti sọ pe yoo di Olubadan, o maa di Olubadan naa pẹlu irọrun.
O ni “Asiko aburo oun, Abiola Ajimobi ni wọn bẹrẹ gbogbo eto yii, oun si bori.
O ni, ohun ti oun mọ ni pe Olubadan lo yẹ ko ṣe awọn ayipada, kii ṣe gomina amọ nitoripe gomina lo ni agbara ati asẹ lọwọ lori ipo Ọba yowu nipinlẹ Ọyọ.
O ni oun ti wa setan bayi Ohun ti awọn ara Ibadan ba fẹ ki oun ṣe ni oun ma ṣe.
Ọlọrun si ni eleto ti o ni eto ohun gbogbo lọwọ.
Ladoja pari ọrọ rẹ pe ọpọ ni awọn to ti de ipo Ọtun Olubadan ṣugbọn ti wọn ko di Olubadan amọ nitoun agba Oye Atọbatẹlẹ, Adewọlu Ọladọja oun yoo dori apere Olubadan tilẹ Ibadan lasẹ Edumare atawọn t’oni ilẹ Ibadan.