Iroyin pajawiri

Monthly Archives: August 2024

Àjọ NCC tun ti kéde gbèdéke tuntun fún àwọn eeyan tí kò tíì so nọ́mbà fóònú wọn pọ̀ mọ́ nọmba ìdánimọ̀ NIN

Ajọ NCC, ajọ to n ṣakoso awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilẹwa Naijiria ti tun kede gbedeke ọjọ ti wọn yoo fofin de awọn ti wọn ko i ti so Sim wọn pọ mọ NIN wọn. Ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an to n bọ yi ni ajọ naa kede gẹgẹ bi gbedeke …

Ka si »

Nipinlẹ Ondo Ọwọ́ ìkọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn tẹ àwọn ọmọ iya meji ti wọn ji ọkada àtàwọn akẹgbẹ́ wọn méji

Ọjọ gbogbo ni t’ole ọjọ kan ni t’olohun bẹẹ gẹẹ lọrọ ri awọn ikọ onisẹbi adigunjale kan tọwọ awọn ikọ eleto abo Amọtẹkun tẹ l’Ondo. Awọn ọdaran ọhun James Amos ẹni ọgbọn ọdun ati Moses Punsak, ẹni ọdun mọkanlelogun lọwọ tẹ lasiko ti wọn sisẹ laabi wọn wa digunjale lagbegbe …

Ka si »

Àwọn Adigunjalè sèkọlù síléesẹ́ Radio BCOS Ajílété, Gembari Ògbómọ̀sọ́, wọn sa bàbá ẹni àádọ́rin ọdún lada.

Lasalẹ ana ọjọ Ẹti Friday, ọjọ kẹtalelogun osu kẹjọ ni awọn adigunjale agbebọn kan se akọlu sileesẹ agbohun safẹfẹ Radio Ajilete, ẹka ileesẹ igbohunsafẹfẹ BCOS ipinlẹ Ọyọ ti o wa ni Gambari nilu Ogbomọsọ. Gẹgẹ bi iroyin naa ti a gbọ awọn adigunjale ọhun se Jamba si Baba ẹni aadọrin …

Ka si »

Oró nla lẹẹdá o, ẹ̀yin t’ẹpa Mojisola Awesu akẹ́kọ̀ọ́ jáde nílé ẹ̀kọ́ ìsègùn Kwara State College of Health Technology tó wà nilu Offa, nipinlẹ Kwara.

Ileesẹ Ọlọpa ti fi gbooro ofin gbe awọn Afurasi meji, Woli Adebayo ti ọpọ mọ si Ogunsẹ ati ọmọ rẹ, Happiness lori ikú Mojisọla Awesu to jáde láyé lẹ́yìn to bá Happiness ọmọ woli lọ ilé ìtura nilu Ilorin Latari bi iku akẹkọbinrin to ṣẹṣẹ pari eto-ẹkọ rẹ nile ẹkọ …

Ka si »

Ayẹyẹ ọdún Ìsẹ̀se wáyé káàkiri àwọn ìlú nílẹ̀ Yorùbá.

Ayẹyẹ ọdun iṣẹṣẹ wa kaakiri ilẹ Yoruba, Paapajulọ lawọn ipinlẹ bii Ọyọ, Eko, Ọṣun, Ogun to fi mọ ipinlẹ Kwara. Gbogbo ogunjọ oṣu kẹjọ ọdọọdun ni ayajọ ọdun iṣẹṣẹ ni ilẹ Yoruba. Kaakiri awọn ilu isẹmbaye, nilẹ Yoruba ni awọn ipinlẹ ti o wa lẹkun gusu orileede Naijiria ni ajọdun …

Ka si »

Nípìnlẹ Ọ̀yọ́ òsìsẹ́ Ìjọba Ìbílẹ̀ kan talẹ̀ Ìjọba r’ẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta he.

Bàbawándé ló talẹ̀ Òòsà dáràn nínú Sinimọ́ t’Olúwa nilẹ̀, Òṣìṣẹ́ ìjọba kan naa re o, ó rẹ́wọ̀n he lẹ́yìn tó t’alẹ̀ ìjọba nipinlẹ Ọ̀yọ̀. Osisẹ Ijọba ìbílẹ̀ kan tó ń ta ilẹ̀ ìjọba lọ́nà àìtọ́ rí ẹ̀wọ̀n he lẹyin ti o se bẹ ta ilẹ ti o jẹ ti ijọba …

Ka si »