Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"addons":1,"transform":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Ìgbòho lóní kí a bọ̀’gún a sì ti bọ́ o, o ni gbogbo àwọn tí wọ́n ba fẹ́ gbógunti iran Yorùba kí ògún se wọn síba sìbo.

Nilu Ogbomọsọ ati agbegbe rẹ, agbarijọpọ ẹgbẹ ọdẹ ibilẹ ati awọn eeyan ọmọ ọkọ Yoruba ti wọn fọnrere Ominira Yoruba Nation korajọpọ nidi ogun.

Ohun ti wọn n pariwo sọ ni pe ogun lakaye Ọsimọlẹ, kolomi nle fẹjẹ wẹ, ko fẹjẹ wọn wẹ o, gbogbo awọn ti wọn fẹ gbogun, ti wọn n gbogun tabi ti wọn n gbabọde fun iran Yoruba gbogbo wọn ni ki ogun o kọju ija si.

Wọn ni gbogbo awọn ti wọn n fẹ’re fun iran Yoruba ki ogun o ma kọju ija si wọn, ki wọn o ma lọ ọ re bọ ọ’re ki ohun gbogbo ti wọn ba n se ki o ma se deede ki ogun o ma fisọ rẹ sọ wọn ni o, amọ gbogbo ọta iran Yoruba ki ogun o se wọn siba sibo.

Ninu ọrọ rẹ Comrade Abiọdun Iyiọla ti ọpọ eeyan mọ si imọlẹ ẹni ti o soju fun oloye Sunday Igboho, o sọ wipe Oloye Sunday Igboho lo fi’pe sita pe ki awọn o bọ ogun ilu Ogbomọsọ ki ogun o mu gbogbo ọdalẹ, awọn asikupani ti wọn n gbogun ti iran Yoruba.

Gẹgẹ bi o se wi o ni gbogbo ohun to n lọ nilu lorileede Naijiria yi ni ko dun mọ awọn ninu paapaa julọ oloye Sunday Igboho ati awọn ọmọ ọkọ Yoruba bi ti ẹ, idi ẹ si niyẹn ti o jẹ ki wọn o ma fọnrere Ominira Yoruba Nation, ki awa iran Yoruba o ni orileede ti wa ti a si ma sejọba arawa nibẹ.

O ni awọn o ba Aarẹ Bọla Tinubu tabi awọn alasẹ ipo oselu kankan ja, amọ awọn o le laju silẹ ki talubọ o kọ wọ, awọn o le maa woran ki awọn ẹya kan o maa foju iran Yoruba gbolẹ, o ni ogun ti awọn fulani ngbe ti iran Yoruba ti n pọ lapọju ki wọn o mọ pa awọn eeyan, ji awọn eeyan gbe ki wọn o ma fẹran jẹko, fẹran ba nkan oko jẹ.

O ni idi ẹ rẹ ti Oloye Sunday Igboho fi n jijagbara lati gba iran Yoruba silẹ lọwọ awọn kọlọrọsi fulani ti wọn fẹ fogun jaran Yoruba.

Lẹyin gbogbo etutu irubọ lori ogun, awọn eeyan naa korajọpọ kọwọrin lọ si Aafin Sọun tilẹ Ogbomọsọ lati fi erongba ati igbiyanju wọn to Ọba leti ati lati beere fun atilẹyin ori ade naa.

Igbimọ Sọun ati awọn oloye laafin ti agba Oye Sọbalaje Ọtọlorin ẹni ti i se Aarẹ-ago lewaju wọn lo ki awọn eeyan naa kaabọ lorukọ Kabiesi Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye Sọun tilẹ Ogbomọsọ.

Aarẹ Ago nigba ti o n fesi si erongba awọn eeyan naa o ki wọn lorukọ Sọun tilẹ Ogbomọsọ, o si se wọn pẹlẹ, o jẹ ki o di mimọ fun wọn pe gbogbo igbiyanju wọn latori ẹni ti i se asaaju wọn Sunday Igboho ni awọn n ri ti awọn si n gboriyin fun, amọ ki wọn o mọ wi pe Ọmọ Ọba ki i jagun bi Ẹru.

O ni ki wọn o fi ọgbọn ati imọ Olodumare se ohun gbogbo ti wọn fẹ se, o ni iru eyi ti wọn lọ se nidi ogun ara rẹ ni pe ki ogun o kọju ija s’awọn ọta iran Yoruba, o ni bẹẹni ki wọn o mọ ba’wọn onilẹ sọrọ ki wọn o le maa dari wọn tọ wọn sọna.

O rọ wọn ki wọn o mase tẹ ofin loju mọlẹ ki wọn o se ohun gbogbo pẹlu ọgbọn Olodumare, o wa ki wọn lẹẹkan si lorukọ Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye Sọun tilẹ Ogbomọsọ pe wọn ku afọmọ niyan se, ti o si tun gba ladura fun wọn pe wọn o ni sise, wọn o si ni silẹ tẹ.

Comrade Abiọdun Iyiọla Imọlẹ, oun pẹlu dupẹ lorukọ ọga wọn Oloye Sunday Adeyẹmọ Igboho, o ni gbogbo ohun ti Ọba wi ni awọn ti gbọ ni pataki julọ pe Ọmọ Ọba lawọn, Ọmọ Ọba o si gbọdọ maa jagun bi ẹru.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ọ̀rọ̀ akọ àti abo tí Trump sọ nípa rẹ̀ kò kàn èmi o torí obìnrin ni mí, mo sì ní ẹ̀rì tó dájú – Bobrisky

Ọ̀rọ̀ akọ àti abo tí Trump sọ nípa rẹ̀ kò kàn èmi o torí obìnrin …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *